ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w01 10/15 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Àpótí Májẹ̀mú?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Èèyàn Mẹ́jọ La Ìparun Já
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
w01 10/15 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ibo làwọn ọ̀pá tá a fi ń gbé àpótí májẹ̀mú wà, tí 1 Àwọn Ọba 8:8 fi sọ pé a lè rí wọn láti Ibi Mímọ́?

Nígbà tí Jèhófà fún Mósè ní àwòrán àgọ́ ìjọsìn ní aginjù, ọ̀kan lára ohun pàtàkì jù lọ nínú rẹ̀ ni àpótí májẹ̀mú. Inú àpótí onígun mẹ́rin, tá a fi wúrà bò yìí la kó wàláà Òfin àtàwọn nǹkan mìíràn sí. Yàrá inú lọ́hùn-ún, tá a ń pè ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ ló wà. Àwòrán kérúbù méjì tá a fi wúrà ṣe, tí wọ́n na ìyẹ́ wọn, wà lórí ìdérí Àpótí náà. Ihò kéékèèké méjì wà níhà kọ̀ọ̀kan Àpótí yìí, kí ó lè ṣeé ṣe láti fi ọ̀pá méjì gbé Àpótí yìí. Igi bọn-ọ̀n-ní tá a fi wúrà bò la fi ṣe ọ̀pá méjèèjì yìí. Ó bọ́gbọ́n mu láti parí èrò sí pé ńṣe la ti àwọn ọ̀pá náà bọ ihò wọ̀nyí, tí ọ̀pá wọ̀nyí á sì wá yọ lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Àpótí náà. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí Àpótí náà bá wà láyè rẹ̀ ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn, tó dojú kọ ìlà oòrùn, àríwá àti gúúsù làwọn ọ̀pá náà máa dojú kọ ní tiwọn. Báyìí ni Àpótí náà tún ṣe wà níkẹyìn, nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́.—Ẹ́kísódù 25:10-22; 37:4-9; 40:17-21.a

Aṣọ ìkélé kan wà láàárín Ibi Mímọ́ Jù Lọ àti Ibi Mímọ́ (ìyẹn, yàrá ìta). Àwọn àlùfáà tí ń bẹ ní Ibi Mímọ́ kò gbọ́dọ̀ lọ yọjú wo Àpótí náà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, níbi tí Ọlọ́run sọ pé òun wà. (Hébérù 9:1-7) Fún ìdí yìí, ohun tó wà nínú 1 Àwọn Ọba 8:8 lè fẹ́ rúni lójú. Ó kà pé: “Àwọn ọ̀pá náà gùn, tí ó fi jẹ́ pé orí àwọn ọ̀pá náà ni a lè rí ní Ibi Mímọ́ ní iwájú yàrá inú pátápátá, ṣùgbọ́n a kò lè rí wọn lóde.” Ìwé 2 Kíróníkà 5:9 sọ ohun kan náà. Báwo lẹni tó wà ní Ibi Mímọ́ tẹ́ńpìlì ṣe lè rí àwọn ọ̀pá náà?

Àwọn kan sọ pé ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni àwọn ọ̀pá náà kan aṣọ ìkélé, táwọn èèyàn wá ń rí bó ṣe ti aṣọ náà síta. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn kò lè rí bẹ́ẹ̀ bó bá ṣe pé àríwá àti gúúsù làwọn ọ̀pá náà dojú kọ, tó wá jẹ́ pé ìbú làwọn ọ̀pá náà wà sí aṣọ ìkélé. (Númérì 3:38) Àlàyé mìíràn tó bọ́gbọ́n mu jùyẹn lọ wà. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa rí àwọn ọ̀pá náà, bó bá ṣe pé àlàfo kékeré kan wà láàárín aṣọ ìkélé àti ògiri tẹ́ńpìlì tàbí nígbà tí àlùfáà àgbà bá fẹ́ wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Aṣọ ìkélé kò lè jẹ́ kéèyàn rí Àpótí náà rárá, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kéèyàn gba ibi àlàfo náà rí orí àwọn ọ̀pá náà tó yọ níhà méjèèjì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlàyé yìí bọ́gbọ́n mu, kò yẹ ká sọ pé èyí labẹ gé.

Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ la ò tíì mọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe àlàyé díẹ̀ nípa àgọ́ yìí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Hébérù. Lẹ́yìn náà ló wá sọ pé: “Ìsinsìnyí kọ́ ni àkókò láti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí.” (Hébérù 9:5) Àjíǹde àwọn olóòótọ́ tí ń bọ̀ yóò fún wa láǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn èèyàn bíi Mósè, Áárónì, Bẹ́sálẹ́lì, àtàwọn míì tí kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn náà kò ṣẹ̀yìn wọn, tí wọ́n sì mọ gbogbo ohun tí wọ́n ń lò ó fún.—Ẹ́kísódù 36:1.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wọn kì í yọ àwọn ọ̀pá náà nínú ihò wọn, kódà nígbà tí Àpótí náà wà lójú kan nínú àgọ́ ìjọsìn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé wọn kì í lo ọ̀pá náà fún nǹkan mìíràn. Bákan náà, ẹnikẹ́ni ò ní fọwọ́ kan Àpótí ọ̀hún; ká ní wọ́n ń yọ àwọn ọ̀pá náà kúrò nínú ihò wọn ni, gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé e ni wọ́n á máa fọwọ́ kan Àpótí náà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ti àwọn ọ̀pá náà bọnú ihò wọn. Nígbà tí Númérì 4:6 sọ pé ‘kí wọ́n ti ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́,’ bóyá ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n tún àwọn ọ̀pá náà ṣe, bí wọ́n ti ń múra àtigbé àpótí wíwúwo yìí lọ sí ibùdó tuntun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́