ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 8/1 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Òtòṣì Túbọ̀ Ń Tòṣì Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Òtòṣì Túbọ̀ Ń Tòṣì Sí I
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ipò Òṣì Ò Ní Dópin Ni?
  • Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn
    Jí!—1998
  • Báwo Ni Àwọn Òtòṣì Yóò Ti Níláti Dúró Pẹ́ Tó?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsapá Àwọn Èèyàn Láti Fòpin sí Ipò Òṣì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Láìpẹ́, Ẹnikẹ́ni Kì Yóò Tòṣì Mọ́!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 8/1 ojú ìwé 3-4

Àwọn Òtòṣì Túbọ̀ Ń Tòṣì Sí I

“Ó dájú pé kò sí àwùjọ kan tó lè máa gbèrú kó sì máa láyọ̀ bí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn ibẹ̀ bá jẹ́ òtòṣì àti akúùṣẹ́.”

ONÍMỌ̀ ètò ọrọ̀ ajé, Adam Smith, ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní ọ̀rúndún kejìdínlógún. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àkókò tá a wà yìí gan-an ló wá hàn kedere pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tó sọ yẹn. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọlọ́rọ̀ àti tálákà ti wá pọ̀ gan-an. Ní orílẹ̀-èdè Philippines, ìdá mẹ́ta àwọn olùgbé ibẹ̀ ni owó tí wọ́n ń ná lójúmọ́ ò pé dọ́là kan, nígbà tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ lèèyàn á ṣe táá fi rí iye yẹn láwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù. Ìwé Human Development Report 2002 ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé “iye tó ń wọlé fún ìdá márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó lọ́rọ̀ jù lọ láyé pọ̀ ju iye tó ń wọlé fún ìdá márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òtòṣì paraku, àní ó jù ú lọ lọ́nà mẹ́rìnléláàádọ́fà pàápàá.”

Nígbà táwọn kan ń gbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì, ọ̀kẹ́ àìmọye ló ń gbé gẹ́gẹ́ bí àtìpó, tó jẹ́ pé kò jọ ahéré kò jọ abà ni wọ́n ń kọ́ síbikíbi tí wọ́n bá ráyè sí, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé. Tàwọn míì tiẹ̀ tún burú jùyẹn lọ; ojú pópó làwọn yẹn ń gbé ní tiwọn, páálí tàbí ọ̀rá lásán ni wọ́n ń tẹ́ sùn. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń ta gbogbo ọgbọ́n láti gbọ́ bùkátà ara wọn nípa ṣíṣe iṣẹ́kíṣẹ́ tí wọ́n bá rí—wọ́n máa ń wá inú ààtàn, wọ́n máa ń gba àárù, tàbí kí wọ́n máa fi ọmọlanke kó àwọn nǹkan táwọn èèyàn kó dà nù àmọ́ tó ṣeé tún tà lówó pọ́ọ́kú.

Kì í ṣe kìkì àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà nìkan ni àìdọ́gba ti wà láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn òtòṣì àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Báńkì Àgbáyé sọ, “gbogbo orílẹ̀-èdè ló ni ‘àwọn àdádó táwọn òtòṣì gbilẹ̀ sí.’” Bó ti wù káwọn kan lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ tó láti ilẹ̀ Bangladesh títí dé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, síbẹ̀ àwọn kan wà tó jẹ́ pé ekukáká ni wọ́n fi ń rí oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ àti ilé tí wọ́n máa gbé. Ọ̀rọ̀ tí ìwé ìròyìn The New York Times fà yọ látinú ìròyìn Ẹ̀ka Ìjọba fún Ètò Ìkànìyàn ti ọdún 2001 ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ńṣe ni àlàfo tó wà láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn òtòṣì ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà túbọ̀ ń gbòòrò sí i. Ó ní: “Ìdá kan nínú márùn-ún àwọn tó lọ́rọ̀ jù lọ lórílẹ̀-èdè náà ló gba ìdajì àpapọ̀ gbogbo owó tó wọlé lọ́dún tó kọjá . . . Ìdá kan nínú márùn-ún àwọn tó tálákà jù lọ sì gba ìpín mẹ́ta àtààbọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún lára owó tó wọlé náà.” Bákan náà ni ipò nǹkan ṣe rí ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn, ti àwọn mìíràn tiẹ̀ burú jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Ìròyìn kan láti Báńkì Àgbáyé fi hàn pé nǹkan bí ìpín mẹ́tàdínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tó wà láyé ni iye tí wọ́n ń rí ná lóòjọ́ kò tó dọ́là méjì péré.

Ohun tó jẹ́ kí ọ̀ràn náà tún burú sí i ni pé, lọ́dún 2002, àwọn èèyàn gbọ́ ìròyìn kan tó ba ọ̀pọ̀ èèyàn nínú jẹ́ nípa àwọn lọ́gàálọ́gàá tí wọ́n di ọlọ́rọ̀ lọ́nà tó kọni lóminú. Bí wọn ò tiẹ̀ dìídì ṣe ohun kan tí kò bófin mu, síbẹ̀ ohun tí ìwé ìròyìn Fortune sọ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àwọn lọ́gàálọ́gàá wọ̀nyí “ń di ọlọ́rọ̀ lọ́nà tó kàmàmà, tó tayọ lọ́lá, tó sì ń kóni nírìíra jù lọ.” Ríronú lórí ohun tó ń lọ láyé yìí ti mú káwọn kan máa ṣe kàyéfì nípa bí irú owó rẹpẹtẹ tó kani láyà bẹ́ẹ̀, èyí tá a ṣírò sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù dọ́là, ṣe lè wà lọ́wọ́ àwọn kan nígbà tí omilẹgbẹ èèyàn ń tàràkà kí wọ́n tó rówó jẹun.

Ṣé Ipò Òṣì Ò Ní Dópin Ni?

Èyí ò wá túmọ̀ sí pé kò sẹ́ni tó ń gbìyànjú àtiyanjú ìṣòro àwọn tálákà o. Àwọn tó jẹ́ elérò rere lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn àjọ tó ń ṣèrànwọ́ ti gbé àwọn àbá kan dìde láti mú ìyípadà wá. Síbẹ̀síbẹ̀ òótọ́ ìdí ọ̀rọ̀ náà kò múnú ẹni dùn rárá. Ìwé Human Development Report 2002 sọ pé “ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló wá tòṣì gan-an báyìí ju bí nǹkan ṣe rí fún wọn ní ọdún mẹ́wàá, ogún ọdún, kódà ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn pàápàá láwọn ibì kan,” láìfi gbogbo ìsapá wíwúnilórí táwọn kan ń ṣe pè.

Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé kò sí ìrètí kankan fáwọn òtòṣì mọ́? A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka àpilẹ̀kọ tó kàn kó o lè ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ kan tó lè ṣèrànwọ́ nísinsìnyí àti àwọn ojútùú tó o lè má tíì ronú kàn rárá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́