Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ètò Kan Lórí Tẹlifíṣọ̀n Mú Kí Obìnrin Kan Yin Ọlọ́run Lógo
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù sọ pé “àwọn kan ń wàásù Kristi ní tìtorí ìlara àti ìbánidíje, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn pẹ̀lú ní tìtorí ìfẹ́ rere.” (Fílípì 1:15) Nígbà míì, àwọn tí wọ́n fẹ́ láti ba àwọn èèyàn Jèhófà lórúkọ jẹ́ máa ń ṣe àwọn nǹkan tó ń mú káwọn olóòótọ́ ọkàn nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́.
Ní oṣù November 1998, wọ́n ṣe ètò kan lórí tẹlifíṣọ̀n orílẹ̀-èdè Faransé, ètò náà fi àwòrán Bẹ́tẹ́lì hàn, ìyẹn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Louviers, ní orílẹ̀-èdè Faransé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn sọ nípa ètò náà, ó so èso rere láwọn ọ̀nà kan tá ò tiẹ̀ rò tẹ́lẹ̀.
Lára àwọn tó wo ètò náà ni Anna-Paula tó ń gbé ní ọgọ́ta kìlómítà sí Bẹ́tẹ́lì. Anna-Paula àti ọkọ rẹ̀ ti kọ ara wọn sílẹ̀. Ó ní ọmọ méjì, ó sì ń wáṣẹ́. Nítorí náà, láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ó tẹ Bẹ́tẹ́lì láago láti béèrè bóyá wọ́n lè gba òun ṣíṣẹ́ níbẹ̀. Ó ní: “Ohun tí mo rí lórí ètò tí wọ́n ṣe nínú tẹlifíṣọ̀n jẹ́ kí n gbà pé ibì kan tó dáa ni àti pé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ ń ṣèèyàn láǹfààní.” Ẹnu yà á gan-an nígbà tó gbọ́ pé ńṣe ni gbogbo àwọn òjíṣẹ́ tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì yọ̀ǹda àkókò wọn lọ́fẹ̀ẹ́! Lẹ́yìn tí wọ́n bá a jíròrò ráńpẹ́ nípa ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó gbà pé kí Ẹlẹ́rìí kan wá sọ́dọ̀ òun.
Nígbà tí Léna, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan láti ìjọ àdúgbò ibẹ̀ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n jọ sọ̀rọ̀ gan-an, Anna-Paula sì tẹ́wọ́ gba ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.a Kó tó di ìgbà tí Léna máa lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, Anna-Paula ti ka ìwé náà látòkèdélẹ̀, ó sì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó fẹ́ béèrè. Kíá ló gbà pé kí wọ́n wá máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Anna-Paula sọ pé: “Àǹfààní lèyí jẹ́ fún mi láti mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mi ò tíì gbé Bíbélì dání rí láyé mi.”
Anna-Paula ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì ní oṣù January, ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó lọ sí ìpàdé Kristẹni fúngbà àkọ́kọ́. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń wàásù fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní: “Mi ò lè pa ohun tí mò ń kọ́ mọ́ra láìsọ fáwọn èèyàn. Mo fẹ́ máa sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn kí n sì máa tù wọ́n nínú.” Lẹ́yìn tí Anna-Paula ti sapá gidigidi láti yanjú àwọn ìṣòro kan tó ní, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé déédéé. Ó tẹ̀ síwájú kíákíá, ó sì ṣe ìrìbọmi ní May 5, 2002.
Kì í ṣe ìyẹn nìkan o, nítorí tí Anna-Paula jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó sì ń fi ìtara wàásù, ìyá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tó fi ṣèrìbọmi. Anna-Paula sọ pé: “Ayọ̀ mi pọ̀ jọjọ. Ojoojúmọ́ ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún jíjẹ́ tó jẹ́ kí n mọ òun kí n sì máa jọ́sìn òun, mo sì tún ń dúpẹ́ fún àwọn ìbùkún ti mo rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Òkè: Anna-Paula rèé
Ìsàlẹ̀: Ẹnu àbáwọlé ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní orílẹ̀-èdè Faransé