Ìsìn Kristẹni Tòótọ́ Ń Gbèrú
IṢẸ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi ní ipa tó lágbára lórí ayé ní ọ̀rúndún kìíní. Ìwàásù rẹ̀ ń fúnni lókun, ó ń tànmọ́lẹ̀ sáyé ẹni, ó sì ń gbéni ró láwọn ọ̀nà kan tó yani lẹ́nu. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó fetí sí i ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀ lọ́kàn ṣinṣin.—Mátíù 7:28, 29.
Jésù kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò ní báwọn kópa nínú oyè ṣọ́ọ̀ṣì àti ipò òṣèlú tí wọ́n fi ń pọ́n àwọn èèyàn lójú nígbà ayé rẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ káwọn gbáàtúù èèyàn sún mọ́ òun. (Mátíù 11:25-30) Ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ ipa tó lágbára táwọn ẹ̀mí búburú ń ní lórí ayé, ó sì fi agbára tí Ọlọ́run fún un lórí wọn hàn kedere. (Mátíù 4:2-11, 24; Jòhánù 14:30) Jésù fọgbọ́n tan ìmọ́lẹ̀ sórí ìsopọ̀ pàtàkì tó wà láàárín ìjìyà àti ẹ̀ṣẹ̀, ó sì fìfẹ́ tọ́ka sí Ìjọba Ọlọ́run pé òun ni yóò fúnni ní ìtura pípẹ́ títí. (Máàkù 2:1-12; Lúùkù 11:2, 17-23) Ó mú òkùnkùn tó ti bo irú ẹni tí Baba rẹ̀ jẹ́ mọ́lẹ̀ kúrò pátápátá, ó sì jẹ́ kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ fún gbogbo àwọn tó fẹ́ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Rẹ̀.—Jòhánù 17:6, 26.
Abájọ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi yára sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì náà fáwọn èèyàn níbi gbogbo láìfi inúnibíni táwọn onísìn àtàwọn olóṣèlú ń ṣe sí wọn pè. Ní àárín nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún péré, àwọn ìjọ Kristẹni tó ń gbèrú ti wà ní Áfíríkà, Éṣíà, àti Yúróòpù. (Kólósè 1:23) Òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ni tànmọ́lẹ̀ sí ọkàn àwọn onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n jẹ́ olódodo èèyàn jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù.—Éfésù 1:17, 18.
Àmọ́, báwo ni gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun wọ̀nyí tí wọ́n wá láti àwọn ibi tí ọrọ̀ ajé, àṣà ìbílẹ̀, èdè, àti ìsìn tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ ti yàtọ̀ síra yóò ṣe wá kóra jọ pọ̀ sínú “ìgbàgbọ́ kan” tó wà níṣọ̀kan gidi, gẹ́gẹ́ bí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè é? (Éfésù 4:5) Kí ni yóò jẹ́ kí wọ́n “máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan” kí wọ́n máà bàa pínyà? (1 Kọ́ríńtì 1:10) Nítorí ìyapa tó wà láàárín àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni lóde òní, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù fúnra rẹ̀ fi kọ́ni.
Ohun Tó Mú Káwọn Kristẹni Wà Níṣọ̀kan
Nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ Jésù níwájú Pọ́ńtíù Pílátù, ó sọ ohun tó mú káwọn Kristẹni wà níṣọ̀kan. Ó ní: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá wà ní ìhà ọ̀dọ̀ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.” (Jòhánù 18:37) Nítorí náà, títẹ́wọ́gba àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti àwọn apá yòókù nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí, ni ipa tó lágbára tó ń so àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ fún Kristi pọ̀.—1 Kọ́ríńtì 4:6; 2 Tímótì 3:16, 17.
Ká sòótọ́, àríyànjiyàn tàbí gbọ́nmisi-omi-ò-to á máa wáyé láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kí ni yóò ràn wọ́n lọ́wọ́? Jésù ṣàlàyé pé: “Nígbà tí èyíinì bá dé, ẹ̀mí òtítọ́ náà, yóò ṣamọ̀nà yín sínú òtítọ́ gbogbo, nítorí pé kì yóò sọ̀rọ̀ láti inú agbára ìsúnniṣe ti ara rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ohun tí ó ń gbọ́ ni yóò sọ, yóò sì polongo àwọn ohun tí ń bọ̀ fún yín.” (Jòhánù 16:12, 13) Nítorí náà, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló máa mú kí àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù lóye òtítọ́ náà bí Ọlọ́run ṣe ń fi hàn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Ẹ̀mí kan náà ni yóò mú àwọn èso bí ìfẹ́, ìdùnnú, àti àlàáfíà jáde, èyí tí yóò jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wọn.—Ìṣe 15:28; Gálátíà 5:22, 23.
Jésù ò fàyè gba ìyapa láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò fún wọn láṣẹ láti máa tún òtítọ́ Bíbélì ṣàlàyé kó lè fara mọ́ àwọn àṣà ìbílẹ̀ àti ti ìsìn àwọn tí wọ́n máa bá pàdé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ìtara gbàdúrà ní alẹ́ tó lò kẹ́yìn lọ́dọ̀ wọn pé: “Èmi kò ṣe ìbéèrè nípa àwọn wọ̀nyí nìkan, ṣùgbọ́n nípa àwọn tí yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn; kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi jáde.” (Jòhánù 17:20, 21) Nítorí náà, wíwà ní ìṣọ̀kan ní ẹ̀mí àti òtítọ́ ni àmì tá a fi ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tòótọ́ mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni títí di àkókò tiwa yìí. (Jòhánù 4:23, 24) Síbẹ̀síbẹ̀, dípò káwọn ṣọ́ọ̀ṣì òde òní wà níṣọ̀kan, ńṣe ni wọ́n pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
Ìdí Tí Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Fi Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
Àìtẹ̀lé ẹ̀kọ́ Jésù ni olórí ohun tó fà á tí onírúurú ìgbàgbọ́ àti àṣà fi wà láàárín àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni lóde òní. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Bíi ti ìgbà àtijọ́ ni àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń di Kristẹni lóde òní ṣe máa ń mú gbogbo ohun tí wọ́n bá mọ̀ pé ó máa bá ohun tí wọ́n fẹ́ mu nínú Bíbélì, tí wọ́n á sì pa gbogbo ohun tí wọ́n bá mọ̀ pé kò sí níbàámu pẹ̀lú àṣà ìsìn ìbílẹ̀ wọn tì.” Ohun tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn.
Bí àpẹẹrẹ, abẹ́ ìmísí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé sí Tímótì tó jẹ́ alábòójútó bíi tirẹ̀, tó sọ pé: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí; wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé a óò mú wọn yà sínú ìtàn èké.” Ṣé gbogbo Kristẹni la máa ṣì lọ́nà ni? Rárá o. Pọ́ọ̀lù tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa pa agbára ìmòye rẹ mọ́ nínú ohun gbogbo, jìyà ibi, ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.” (2 Tímótì 4:3-5; Lúùkù 21:8; Ìṣe 20:29, 30; 2 Pétérù 2:1-3) Tímótì àtàwọn Kristẹni tòótọ́ mìíràn fi ìmọ̀ràn onímísí yẹn sílò.
Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Ṣì Wà Níṣọ̀kan
Bíi ti Tímótì, ńṣe làwọn Kristẹni òde òní máa ń pa agbára ìmòye wọn mọ́ nítorí wọn kò tẹ́wọ́ gba èrò ènìyàn, tí wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gba kìkì ọlá àṣẹ Ìwé Mímọ́ nínú ẹ̀kọ́ ìsìn wọn. (Kólósè 2:8; 1 Jòhánù 4:1) Ní àfarawé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣepé ní ohun tó lé ní igba ó lé ọgbọ̀n [230] ilẹ̀, wọ́n ń mú ohun tí Jésù sọ níbẹ̀rẹ̀, ìyẹn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn níbi gbogbo. Ṣàyẹ̀wò ọ̀nà mẹ́ta pàtàkì tí wọ́n gbà ń fara wé Jésù tí wọ́n sì jẹ́ Kristẹni tòótọ́ níbikíbi tí wọ́n bá ń gbé.
Orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn kà. (Jòhánù 17:17) Àlùfáà ìjọ kan ní Belgium kọ̀wé nípa wọn pé: “Ohun kan tá a lè rí kọ́ lára wọn [ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ni bí wọ́n ṣe máa ń fẹ́ láti fetí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti bí wọ́n ṣe ní ìgboyà láti jẹ́rìí nípa rẹ̀.”
Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n ń retí pé ó máa báni yanjú àwọn ìṣòro ayé. (Lúùkù 8:1) Ẹlẹ́rìí kan bá Antonio, tó jẹ́ alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú kan sọ̀rọ̀ ní Barranquilla, Kòlóńbíà. Ẹlẹ́rìí náà kò ti ẹgbẹ́ tí ọkùnrin yìí wà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe alágbàwí èròǹgbà ètò òṣèlú mìíràn. Dípò ìyẹn, ó sọ pé òun á kọ́ Antonio àti àbúrò rẹ̀ obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Kó pẹ́ tí Antonio fi rí i pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ìrètí tó wà fún àwọn òtòṣì tó wà ní Kòlóńbíà àti ní àwọn apá ibi yòókù ní ayé.
Wọ́n bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run. (Mátíù 6:9) Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ bá Maria, ìyẹn Kátólíìkì olùfọkànsìn kan tó ń gbé ní Ọsirélíà pàdé, ó jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí náà fi orúkọ Ọlọ́run han òun nínú Bíbélì. Kí ló wá ṣe? Ó ní: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì, mo sunkún. Bí mo ṣe rí i pé mo lè mọ orúkọ Ọlọ́run kí n sì máa lò ó mórí mi wú gan-an ni.” Maria ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ, ní ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ó wá mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, ó sì ṣeé ṣe fún un láti ní àjọṣe tí yóò wà pẹ́ títí pẹ̀lú rẹ̀.
Ìfẹ́ ló so wọ́n pọ̀. (Jòhánù 13:34, 35) Ọ̀rọ̀ olótùú kan nínú ìwé ìròyìn The Ladysmith-Chemainus Chronicle, ti Kánádà sọ pé: “Ìsìn yòówù tó o bá ń ṣe tàbí tí o kò bá tiẹ̀ ṣe ìsìn kankan, ó yẹ kó o gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye wọ́n jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlélógún [4,500], tí wọ́n ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru ní ọ̀sẹ̀ kan ààbọ̀ sẹ́yìn láti kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ mítà ẹgbàá ó lé ọ̀ọ́dúnrún [2,300] níbùú lóròó ní Cassidy . . . Bí wọ́n ṣe lè ṣe èyí láìsí pé wọ́n ń bára wọn jiyàn, tí kò sí ìyapa láàárín wọn tàbí kí ẹnì kan máa wá ògo ti ara rẹ̀ jẹ́ àmì jíjẹ́ Kristẹni tòótọ́.”
Tóò, ẹ jẹ́ ká wá gbé ẹ̀rí náà yẹ̀ wò. Níbi táwọn tó ń kọ́ni ní ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn míṣọ́nnárì, àtàwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ti ń ronú nípa wàhálà tí àríyànjiyàn tó ń lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn máa dá sílẹ̀, ńṣe ni ìsìn Kristẹni tòótọ́ ń gbèrú jákèjádò ayé. Àní sẹ́, ńṣe làwọn Kristẹni tòótọ́ ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ti wíwàásù àti kíkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ ní pẹrẹu. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Tó o bá wà lára àwọn tí wọ́n “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora” lórí àwọn ohun ìṣe họ́ọ̀ sí tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí, tí ọ̀nà tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì gbà ń yapa síra wọn sì ń dààmú rẹ, a rọ ẹ́ pé kó o dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ìjọsìn Kristẹni tó wà níṣọ̀kan tó jẹ́ ti Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.—Ìsíkíẹ́lì 9:4; Aísáyà 2:2-4.