ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 3/1 ojú ìwé 3-4
  • Ǹjẹ́ A Lè Yọ Ṣọ́ọ̀ṣì Nínú Ìṣòro?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ A Lè Yọ Ṣọ́ọ̀ṣì Nínú Ìṣòro?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ló Ń Yọ Ẹnì Kejì Rẹ̀ Nínú Ìṣòro?
  • Ẹ̀rí Túbọ̀ Ń Fi Hàn Pé Wàhálà Ń Bọ̀
  • Ìkórè ti Kristẹndọm ní Africa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ṣọọṣi Latin-America Ninu Idaamu—Eeṣe ti Araadọta-Ọkẹ Fi Ń Kuro?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Kí Ló Dé Táwọn Èèyàn Ń Fi Àwọn Ẹ̀sìn Tó Ti Wà Látayébáyé Sílẹ̀?
    Jí!—2002
  • Èé Ṣe Tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kò Fi Nípa Lórí Àwọn Ènìyàn Mọ́?
    Jí!—1996
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 3/1 ojú ìwé 3-4

Ǹjẹ́ A Lè Yọ Ṣọ́ọ̀ṣì Nínú Ìṣòro?

ÀLÙFÁÀ ọmọ ilẹ̀ Uganda kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Stephen Tirwomwe, sọ pé: “Àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣì gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ wọn ò fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn fún Kristi.” Nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn ni àlùfáà yìí yè bọ́ nínú ogun gbígbóná janjan tí wọ́n gbé dìde sí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ ní Uganda. Ní báyìí, ó ti wá dẹni tó ń wàásù láwọn ilé tí àwọn ọkùnrin ti ń gbafẹ́ nílùú Leeds, ní ilẹ̀ England, ó máa ń fi ìṣẹ́jú mẹ́wàá wàásù káwọn tó wà níbẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí ta tẹ́tẹ́ bingo.

Tá a bá tún sọdá sí òdìkejì òkun Àtìláńtíìkì, ìyẹn ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a ó ri pé ìṣòro tẹ̀mí kan náà yìí ló dojú kọ Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà tí wọ́n dá sílẹ̀ níbẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ibi tí Ibùdó náà ń kó ìsọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sọ pé: “Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni ibi tí àwọn tí kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tí wọn ò sì ka ohun tẹ̀mí sí ti pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì lágbàáyé. Orílẹ̀-èdè wa ti ń di ibi tí wọ́n máa kó àwọn míṣọ́nnárì wá báyìí.” Nígbà tí gbogbo ipa tí wọ́n sà láti yí bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà padà já sí pàbó, ibùdó tuntun náà wá jáwọ́ nínú títẹ̀lé àwọn àṣà ìbílẹ̀, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn aṣáájú tó wà ní Éṣíà àti Áfíríkà láti bẹ̀rẹ̀ sí “kó àwọn míṣọ́nnárì wá sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.”

Àmọ́, kí nìdí táwọn míṣọ́nnárì láti Áfíríkà, Éṣíà, àti Látìn Amẹ́ríkà fi wá ‘ń wàásù fáwọn èèyàn’ láwọn ilẹ̀ Yúróòpù àtàwọn orílẹ̀-èdè Àríwá Amẹ́ríkà táwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni pọ̀ sí tẹ́lẹ̀?

Ta Ló Ń Yọ Ẹnì Kejì Rẹ̀ Nínú Ìṣòro?

Ó lé ní irínwó ọdún tí àwọn míṣọ́nnárì olùfọkànsìn láti ilẹ̀ Yúróòpù fi ń ya lọ sáwọn ilẹ̀ táwọn ará Yúróòpù ń gbókèèrè ṣàkóso bí Áfíríkà, Éṣíà, Pàsífíìkì, àtàwọn orílẹ̀-èdè Gúúsù Amẹ́ríkà. Ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ káwọn tí wọ́n pè ní abọgibọ̀pẹ̀ láwọn ilẹ̀ wọ̀nyẹn tẹ́wọ́ gba ìsìn tiwọn. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn àgbègbè táwọn ará Amẹ́ríkà tẹ̀ dó, tí wọ́n sọ pé àwọn fìdí wọn múlẹ̀ lórí àwọn ìlànà Kristẹni, dára pọ̀ mọ́ wọn. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn àgbègbè táwọn ará Amẹ́ríkà tẹ̀dó yìí wá ṣe ju àwọn ará Yúróòpù tí wọ́n fẹ́ fara wé lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ ìjíhìn tiwọn jákèjádò ayé. Nǹkan tí wá yí padà báyìí ṣá o.

Ọ̀gbẹ́ni Andrew Walls, tó dá Ibùdó Àyẹ̀wò Ìsìn Kristẹni sílẹ̀ Láwọn Ilẹ̀ Tí Ko sí ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé sọ pé: “Ibùdó [àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni] ti yí padà.” Ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni lọ́dún 1900 ló jẹ́ ará

Yúróòpù tàbí ará àwọn orílẹ̀-èdè Àríwá Amẹ́ríkà. Àmọ́ ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni lónìí ló ń gbé ní Áfíríkà, Éṣíà, àti Látìn Amẹ́ríkà. Ìròyìn kan tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé: “Àwọn àlùfáà tó ń wá láti Philippines àti Íńdíà ni àwọn ìjọ Kátólíìkì tó wà ní Yúróòpù gbára lé,” àti pé “ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àlùfáà mẹ́fà mẹ́fà tó ń sìn láwọn ilé ìjọsìn Kátólíìkì tó wà nílẹ̀ Amẹ́ríkà ló jẹ́ àwọn tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè.” Àwọn ajíhìnrere ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tó wà ní Netherlands, tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ ọmọ Gánà, rí ara wọn gẹ́gẹ́ bí “ṣọ́ọ̀ṣì míṣọ́nnárì kan ní ilẹ̀ táwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ ìsìn.” Àwọn ajíhìnrere láti Brazil sì ti wá ń ṣe ìsìn ní apá ibi púpọ̀ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì báyìí. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Ọ̀ràn àwọn míṣọ́nnárì ìsìn Kristẹni kò rí bíi ti àtijọ́ mọ́.”

Ẹ̀rí Túbọ̀ Ń Fi Hàn Pé Wàhálà Ń Bọ̀

Ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n nílò àwọn míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ Yúróòpù àtàwọn orílẹ̀-èdè Àríwá Amẹ́ríkà tí wọ́n jẹ́ aláìnífẹ̀ẹ́ ìsìn. Ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Àwọn tó máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé nínú àwọn Kristẹni tó wà ní Scotland kò tó ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún.” Kódà àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní ilẹ̀ Faransé àti Jámánì kò pọ̀ tó yẹn. Ìròyìn mìíràn sọ pé nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá àwọn èèyàn lẹ́nu wò, “nǹkan bí ìpín ogójì lára àwọn ará Amẹ́ríkà àtàwọn bí ìpín ogún lára àwọn ará Kánádà ló sọ pé àwọn máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé.” Ọ̀ràn náà yàtọ̀ pátápátá ni ilẹ̀ Philippines, iye àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé níbẹ̀ ń lọ sí nǹkan bí ìpín àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún, bó sì ṣe rí láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà nìyẹn.

Ohun tó túbọ̀ gbàfiyèsí ni pé àwọn tó máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní Gúúsù Agbedeméjì ayé kọ́wọ́ ti ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì sọ ju àwọn tó wà ní Àríwá Agbedeméjì ayé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá àwọn Kátólíìkì tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Yúróòpù lẹ́nu wò, léraléra ni wọ́n ń sọ bí wọ́n ò ṣe lè fọkàn tán àwọn àlùfáà tó wà nípò àṣẹ, wọ́n sì sọ pé àwọn fẹ́ káwọn tí kì í ṣe àlùfáà túbọ̀ máa kópa nínú ọ̀ràn ṣọ́ọ̀ṣì kí ṣọ́ọ̀ṣì sì dẹ́kun fífojú kéré àwọn obìnrin. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ńṣe ni àwọn Kátólíìkì tó wà ní Gúúsù Agbedeméjì ayé fi tayọ̀tayọ̀ fara mọ́ ọwọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì fi mú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyẹn látìbẹ̀rẹ̀. Bí àwọn tó ń kọ́wọ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́yìn ṣe ń dín kù ní Àríwá Agbedeméjì ayé tí wọ́n sì ń pọ̀ si ní Gúúsù Agbedeméjì ayé fi hàn pé wàhálà kan máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀gbẹ́ni Philip Jenkins, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn àti ìsìn sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nígbà tá a bá fi máa rí ọdún bíi mẹ́wàá tàbí ogún ọdún sí àkókò tá a wà yìí, bóyá ni àwọn Kristẹni tó wà ní apá ibi kan lágbàáyé fi máa fara mọ́ ohun táwọn Kristẹni tó wà ní apá ibòmíràn ń ṣe.”

Nítorí bí nǹkan ṣe ń lọ yìí, Walls sọ pé ohun tó yẹ ká bójú tó ní kíákíá ni, “bí àwọn Kristẹni ará Áfíríkà, Éṣíà, Látìn Amẹ́ríkà, àwọn orílẹ̀-èdè Àríwá Amẹ́ríkà àti Yúróòpù á ṣe jọ wà pa pọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì kan náà, tí wọ́n á sì jọ gba ohun kan náà gbọ́.” Kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ a lè yọ ṣọ́ọ̀ṣì nínú ìṣòro nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí? Kí ni ohun tó mú kí ìsìn Kristẹni tòótọ́ wà níṣọ̀kan? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò fúnni ní ìdáhùn tó bá Ìwé Mímọ́ mu, pẹ̀lú ẹ̀rí tó ṣe kedere pé àwùjọ àwọn Kristẹni kan tó wà níṣọ̀kan ti ń gbèrú jákèjádò ayé báyìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ṣọ́ọ̀ṣì ni ilé yìí tẹ́lẹ̀, ó ti wá di ibi táwọn òṣèré ti ń kọrin báyìí

[Credit Line]

AP Photo/Nancy Palmieri

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́