Àwọn Eré Ìdárayá Ayé Àtijọ́ àti Ìjẹ́pàtàkì Gbígbégbá Orókè
“OLÚKÚLÙKÙ ènìyàn tí ń kó ipa nínú ìdíje a máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo.” “Bí ẹnì kan bá díje nínú àwọn eré . . . a kì í dé e ládé láìjẹ́ pé ó díje ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àfilélẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 9:25; 2 Tímótì 2:5.
Àwọn ìdíje tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ apá pàtàkì nínú àṣà ìbílẹ̀ ilẹ̀ Gíríìkì ìgbàanì. Kí ni ìtàn jẹ́ ká mọ̀ nípa irú àwọn ìdíje bẹ́ẹ̀ àti irú ẹ̀mí tí wọ́n ń gbé lárugẹ?
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n ṣe ìpàtẹ kan ní Gbọ̀ngàn Ìwòran ìlú Róòmù, àkọlé rẹ̀ ni Nike—Il gioco e la vittoria, (“Nike—Ìdíje àti Ìṣẹ́gun”). Wọ́n ṣètò ìpàtẹ yìí káwọn èèyàn lè mọ̀ nípa àwọn ìdíje ilẹ̀ Gíríìkì.a Ìpàtẹ náà pèsè ìdáhùn díẹ̀ sáwọn ìbéèrè òkè yìí, ó sì tún jẹ́ ká mọ ojú tó yẹ káwọn Kristẹni fi máa wo eré ìdárayá.
Àṣà Àtayébáyé
Ilẹ̀ Gíríìkì kọ́ ni orílẹ̀-èdè ọ̀làjú tó kọ́kọ́ ṣètò eré ìdárayá. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Tiwa, akéwì ará ilẹ̀ Gíríìkì náà, Homer ṣàpèjúwe àwọn èèyàn kan tí ẹ̀mí ìdíje àti jíjẹ́ akọni gbà lọ́kàn, tí wọ́n sì ka jíjẹ́ ọ̀jáfáfá nínú ogun jíjà àti eré ìdárayá sí ohun pàtàkì. Ìpàtẹ náà jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àkọ́kọ́ nínú àjọyọ̀ ilẹ̀ Gíríìkì jẹ́ àjọ̀dún ìsìn tí wọ́n fi júbà àwọn ọlọ́run níbi ìsìnkú àwọn akọni. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ilẹ̀ Gíríìkì tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ, ìyẹn ewì Homer tó pe àkọlé rẹ̀ ní Iliad, ṣàpèjúwe bí àwọn jagunjagun olókìkí, tí wọ́n jẹ́ akọni bíi ti Achilles, ṣe kó àwọn ohun ìjà wọn sílẹ̀ níbi ààtò ìsìnkú tí wọ́n ṣe fún Patroclus, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn díje láti fakọ yọ nínú ẹ̀ṣẹ́ kíkàn, ìjàkadì, jíju ohun pẹlẹbẹ kan tó rí ribiti, jíju ọ̀kọ̀ àti fífi kẹ̀kẹ́ ẹṣin sáré.
Irú àwọn àjọ̀dún bẹ́ẹ̀ wá di ohun tí wọ́n ń ṣe káàkiri ilẹ̀ Gíríìkì. Ìwé tó ń ṣàlàyé nípa ìpàtẹ náà sọ pé: “Àwọn àjọ̀dún yìí jẹ́ àǹfààní pàtàkì kan tí àwọn Gíríìkì ní láti dáwọ́ ẹ̀mí asọ̀ àti ìwà ipá wọn dúró fúngbà díẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run wọn, kí wọ́n wá lo okun àti agbára wọn láti máa díje, ìyẹn láti fi ẹ̀mí àlàáfíà àti òótọ́ inú bá ara wọn díje.”
Láwọn ìpínlẹ̀ tó wà nílẹ̀ Gíríìkì, àwọn aráàlú máa ń pé jọ déédéé láwọn ibi ìjọsìn tó wà fún gbogbo èèyàn láti bọlá fún àwọn ọlọ́run àjúbàfún wọn, nípa bíbá ara wọn díje. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, mẹ́rin lára irú àwọn àjọ̀dún bẹ́ẹ̀ wá di ohun táwọn èèyàn kà sí pàtàkì débi pé wọ́n di àjọ̀dún gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ Gíríìkì lápapọ̀. Gbogbo àwọn olùdíje ilẹ̀ Gíríìkì ló sì máa ń kópa nínú rẹ̀. Àwọn àjọ̀dún mẹ́rin náà ni Ìdíje Òlíńpíìkì àti Nemea, tí wọ́n ń fi méjèèjì júbà Zeus, Ìdíje Pythia tí wọ́n fi ń júbà Apollo, àti Ìdíje Isthmus tí wọ́n fi ń júbà Poseidon. Nígbà táwọn Gíríìkì bá ń ṣe àjọ̀dún, wọ́n máa ń rúbọ, wọ́n máa ń gbàdúrà, wọ́n tún máa ń ṣe eré ìdárayá tó kàmàmà tàbí iṣẹ́ ọnà aláràbarà láti fi júbà àwọn ọlọ́run wọn.
Àjọ̀dún tó tíì pẹ́ jù lọ tó sì tún lókìkí jù lọ nínú àwọn àjọ̀dún náà ni wọ́n máa ń ṣe ní ọdún mẹ́rin-mẹ́rin ní ìrántí Zeus ní àgbègbè Olympia, láti ọdún 776 ṣáájú Sànmánì Tiwa ni ìtàn sì sọ pé wọ́n ti ń ṣe é. Èyí tó tún gbayì tẹ̀ lé e ni àjọ̀dún Pythian. Wọ́n máa ń ṣe é ní tòsí ojúbọ tó gbajúmọ̀ jù lọ láyé ọjọ́un, nílùú Delphi, wọ́n sì máa ń ṣe eré ìdárayá nígbà àjọ̀dún yìí náà. Ṣùgbọ́n nítorí kí wọ́n lè bọlá fún Apollo, tó jẹ́ baba ìsàlẹ̀ àwọn akéwì àtàwọn olórin, orin àti ijó ló máa ń pọ̀ jù nígbà àjọ̀dún náà.
Àwọn Eré Ìdárayá Tí Wọ́n Máa Ń Ṣe
Bá a bá fi wé àwọn ìdíje òde òní, iye àwọn eré ìdárayá tí wọ́n ń ṣe nígbà yẹn kéré, àwọn ọkùnrin nìkan ló sì máa ń kópa nínú wọn. Iye eré ìdárayá tí wọ́n máa ń ṣe níbi Ìdíje Òlíńpíìkì ayé àtijọ́ kì í sábà ju mẹ́wàá lọ. Àwọn ère gbígbẹ́, àwòrán aláràbarà àtàwọn àwòrán tí wọ́n yà sára àwọn orù tí wọ́n fi hàn ní Gbọ̀ngàn Ìwòran náà jẹ́ káwọn èèyàn mọ díẹ̀ lára irú àwọn eré ìdárayá náà.
Eré àfẹsẹ̀sá oríṣi mẹ́ta ló wà. Àkọ́kọ́ jẹ́ nǹkan bí igba mítà; èkejì jẹ́ ìlọ́po méjì ti àkọ́kọ́, tá a lè fi wé eré onírinwó mítà òde òní; ẹ̀kẹta sì ni eré ìje gígùn, tó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún [4,500] mítà. Ìhòòhò goloto làwọn sárésáré náà máa ń wà nígbà tí wọ́n bá ń sáré àti nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìdánrawò. Àwọn kan máa ń kópa nínú eré ìdárayá kan tó jẹ́ alápá márùn-ún, ìyẹn eré sísá, fífò, jíju ohun pẹlẹbẹ kan tó rí ribiti, jíju ọ̀kọ̀ àti jíja ìjàkadì. Àwọn ìdíje mìíràn ni ẹ̀ṣẹ́ kíkàn àti eré ìdárayá ẹhànnà kan tí wọ́n ṣàpèjúwe pé ó jẹ́ “ìdíje oníwà ìkà tó ní ìjàkadì àti ẹ̀ṣẹ́ kíkàn nínú.” Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin sáré lọ síbi tó jìn tó ẹgbẹ̀jọ [1,600] mítà. Ẹṣin méjì tàbí mẹ́rin ni wọ́n máa ń fi fa kẹ̀kẹ́ onítáyà kékeré tí kò nílé lórí, àwọn ẹṣin náà sì lè jẹ́ ńlá tàbí kékeré.
Ẹ̀ṣẹ́ kíkàn jẹ́ eré ìdárayá tó kún fún ìwà ipá gan-an, ó sì máa ń la ikú lọ nígbà mìíràn. Àwọn akànṣẹ́ máa ń wé awọ tẹ́ẹ́rẹ́ tó nípọn mọ́ ọwọ́, irin ṣó-ṣò-ṣó tó lè ṣeni léṣe sì máa ń wà lára rẹ̀. Èyí lè jẹ́ kó o mọ ìdí tí olùdíje kan tó ń jẹ́ Stratofonte kò fi lè dá ara rẹ̀ mọ̀ mọ́ nínú dígí lẹ́yìn wákàtí mẹ́rin tó ti ń kànṣẹ́. Àwọn ère àti àwòrán aláràbarà ayé àtijọ́ jẹ́rìí sí i pé ìrísí àwọn akànṣẹ́ kì í dára rárá.
Nínú eré ìjàkadì, ohun tí òfin sọ ni pé òkè ara nìkan ni àwọn tó ń kópa ti lè di ẹni tí wọ́n ń bá jà mú, ẹni tó bá sì kọ́kọ́ dá ẹnì kejì rẹ̀ mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta ló borí. Àmọ́ ṣá o, ìdíje tó ní ẹ̀ṣẹ́ kíkàn àti ìjàkadì nínú yàtọ̀ nítorí èèyàn lè di ẹni tó ń bá jà mú níbikíbi. Àwọn olùdíje lè ta ara wọn nípàá, kí wọ́n kan ara wọn lẹ́ṣẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì yẹ oríkèé ara wọn. Kìkì ohun tí wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe ni pé kí wọ́n ti ìka bọ ẹnì kejì wọn lójú, kí wọ́n ya á ní èékánná, tàbí kí wọ́n gé e jẹ. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe eré ìdárayá yìí ni láti sọ ẹnì kejì di ẹni tí kò lè gbéra ńlẹ̀, kí wọ́n sì fipá mú un láti juwọ́ sílẹ̀. Àwọn kan kà á sí “eré ìdárayá tí àwọn èèyàn fẹ́ràn jù lọ nínú gbogbo ìdíje tí wọ́n ń ṣe ní Òlíńpíìkì.”
Ìtàn sọ pé èyí tó lókìkí jù lọ nínú eré ìdárayá ẹhànnà yìí láyé àtijọ́ ṣẹlẹ̀ níbi àṣekágbá Ìdíje Òlíńpíìkì lọ́dún 564 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó ń bá Arrhachion jà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fún un lọ́rùn pa, Arrhachion ṣì lágbára láti rọ́ ìka ẹsẹ̀ ẹni náà. Ìrora tó pàpọ̀jù ló mú kí onítọ̀hún juwọ́ sílẹ̀ kété kí Arrhachion tó kú. Àwọn adájọ́ sọ pé òkú Arrhachion ló borí!
Fífi kẹ̀kẹ́ ẹṣin sáré ni ìdíje tó gbayì jù lọ, òun sì làwọn ọ̀tọ̀kùlú fẹ́ràn jù lọ, nítorí pé kì í ṣe ẹni tó gùn ún ló borí bí kò ṣe ẹni tó ni kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin. Ìgbà tí ara àwọn èèyàn máa ń wà lọ́nà jù lọ nínú ìdíje náà ni ìbẹ̀rẹ̀ eré náà, nígbà táwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbọ́dọ̀ wà ní ibi tí wọ́n á ti bẹ̀rẹ̀ ìdíje náà, àti ní pàtàkì jù lọ, ní gbogbo ibi tí wọ́n bá ti fẹ́ ṣẹ́ kọ́nà ní ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin òpópó tí wọ́n ti ń sáré. Nígbà táwọn olùdíje bá ṣe àṣìṣe tàbí òjóró, èyí lè fa jàǹbá tó máa ń mú kí eré tó gbajúmọ̀ yìí túbọ̀ dùn ún wò.
Irú Ẹ̀bùn Wo Ni Wọ́n Ń Gbà?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo àwọn sárésáré nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà.” (1 Kọ́ríńtì 9:24) Bíborí lọ́nàkọnà lohun tó jẹ wọ́n lógún jù lọ. Wọn kì í fúnni ní wúrà tàbí fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni kì í sí ipò kejì tàbí ipò kẹta. Ìpàtẹ náà jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé: “Ìṣẹ́gun, tí wọ́n ń pè ní Nike lédè Gíríìkì, ni lájorí ohun táwọn tó ń ṣeré ìdárayá náà ń lépa. Èyí nìkan ti tó wọn, nítorí ìṣẹ́gun nìkan ṣoṣo ló ń fi irú ẹni tí onítọ̀hún jẹ́ gan-an hàn, ìyẹn ni bó ṣe lágbára sí àti ẹ̀mí ìfaradà rẹ̀, àti bó ṣe jẹ́ ẹni àmúyangàn ní ìlú rẹ̀.” Gbólóhùn kan nínú ewì Homer ló ṣàkópọ̀ irú ẹ̀mí tí àwọn eléré ìdárayá fi ń díje, ó sọ́ pé: “Mo ti kọ́ bí màá ṣe máa gbégbá orókè lọ́jọ́ gbogbo.”
Ẹ̀bùn tí wọ́n máa ń fún ẹni tó bá borí nínú ìdíje àwọn ará Gíríìkì jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn adé tí wọ́n fi ewé ṣe. Pọ́ọ̀lù pè é ní “adé tí ó lè díbàjẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 9:25) Síbẹ̀, ẹ̀bùn náà ṣe pàtàkì gan-an lójú wọn. Ó dúró fún agbára tí ó tinú ìṣẹ̀dá wá tó fún olùborí náà lókun láti jáwé olúborí. Ìṣẹ́gun tí àwọn eléré ìdárayá máa ń lépa láìsí ìpínyà ọkàn yìí ni wọ́n kà sí ẹ̀rí pé àwọn ọlọ́run ti yọ́nú sí wọn. Níbi ìpàtẹ náà, àkọsílẹ̀ wà pé àwọn tí ń gbẹ́ ère àtàwọn ayàwòrán ayé àtijọ́ ya àwòrán bí Nike, tí í ṣe abo ọlọ́run ìṣẹ́gun ilẹ̀ Gíríìkì abìyẹ́lápá, ṣe ń gbé adé fún ẹni tó borí. Jíjẹ́ olùborí nínú Ìdíje Òlíńpíìkì lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo akitiyan eléré ìdárayá kan.
Ewé igi ólífì ni wọ́n fi ń ṣe adé nínú Ìdíje Òlíńpíìkì, wọ́n máa ń lo ewé igi ahóyaya fún ti Ìdíje Isthmus, wọ́n ń lo ewé igi lọ̀rẹ́ẹ̀lì fún ti Ìdíje Pythia, nígbà tí wọ́n ń lo ewé celery fún ti Ìdíje Nemea. Àwọn tó ń ṣètò ìdíje níbòmíràn máa ń pèsè ẹ̀bùn owó tàbí ẹ̀bùn mìíràn láti fi fa àwọn olùdíje tó jẹ́ ọ̀jáfáfá jù lọ mọ́ra. Ọ̀pọ̀ orù tí wọ́n kó wá síbi ìpàtẹ náà ló jẹ́ ẹ̀bùn tí wọ́n ń fún àwọn eléré ìdárayá níbi Ìdíje Panathenaic, èyí tí wọ́n ń ṣe nílùú Áténì láti fi bọlá fún abo ọlọ́run tó ń jẹ́ Áténà. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, òróró tí wọ́n ń ṣe lágbègbè Attica ni wọ́n máa ń rọ sínú àwọn orù oníga méjì wọ̀nyí. Lára ọ̀kan nínú àwọn orù náà, wọ́n ya àwòrán abo ọlọ́run Áténà sí ẹ̀gbẹ́ kan rẹ̀, wọ́n sì kọ ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀bùn fún ìdíje Áténà” sí i lára. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì, wọ́n ya àwòrán eré ìdárayá kan sí i lára, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ eré ìdárayá tí olùborí náà ṣe.
Àwọn ìlú Gíríìkì fẹ́ràn kí wọ́n máa pòkìkí àwọn eléré ìdárayá wọn, ìṣẹ́gun wọn sì máa ń sọ wọ́n di akọni ní ìlú ìbílẹ̀ wọn. Orin àti ijó ni wọ́n fi máa ń kí àwọn olùborí káàbọ̀. Wọ́n máa ń gbẹ́ ère wọn láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́run, ohun tó jẹ́ pé àwọn tó ti kú ni wọ́n máa ń fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dá lọ́lá; bẹ́ẹ̀ làwọn akéwì sì máa ń kọrin nípa ìwà akin wọn. Lẹ́yìn èyí, wọ́n máa ń fi àwọn olùborí sí ipò pàtàkì níbi ayẹyẹ, ìjọba sì máa ń fún wọn ní owó ìfẹ̀yìntì.
Gbọ̀ngàn Eré Ìmárale Àtàwọn Eléré Ìdárayá Tó Ń Lò Ó
Wọ́n ka eré ìdárayá sí ohun tó pọn dandan fún àwọn aráàlú tó bá máa di jagunjagun. Gbogbo àwọn ìlú Gíríìkì ló ní gbọ̀ngàn eré ìmárale, níbi tí wọ́n ti máa ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin lẹ́kọ̀ọ́ eré ìmárale. Wọ́n tún máa ń kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ nípa ọgbọ́n orí àti ẹ̀kọ́ ìsìn. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn ilé eré ìmárale yí ká gbàgede tí wọ́n ti ń ṣeré ìdárayá, wọ́n sì tún máa ń kọ́ àwọn ìloro àtàwọn ibi ìkówèésí àti iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ yí ká àwọn ilé eré ìmárale wọ̀nyí. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn ọ̀dọ́kùnrin látinú ìdílé ọlọ́lá, tí wọ́n lè fi àkókò wọn kàwé dípò kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ló sábà máa ń lọ sí ibẹ̀. Níbí yìí, àwọn eléré ìdárayá máa ń ṣe ìmúrasílẹ̀ tó le gan-an tó sì ń gba ọ̀pọ̀ àkókò. Àwọn olùkọ́ wọn ló máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, tí wọ́n máa ń sọ irú oúnjẹ tó yẹ kí wọ́n máa jẹ, tí wọ́n sì ń rí i dájú pé àwọn eléré ìdárayá náà yẹra fún ìbálòpọ̀.
Ìpàtẹ tó wáyé ní Gbọ̀ngàn Ìwòran náà fún àwọn èèyàn láǹfààní láti rí àwọn ère tó lẹ́wà táwọn ará Róòmù ṣe láti fi àwọn eléré ìdárayá ayé àtijọ́ hàn, ọ̀pọ̀ lára àwọn ère náà ló sì jẹ́ pé ti àwọn ará Gíríìkì ni wọ́n wò ṣe é. Nínú èròǹgbà àwọn ará Gíríìkì ayé ọjọ́un, jíjẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ le fi hàn pé èèyàn jẹ́ onílàákàyè, àwọn ọ̀tọ̀kùlú nìkan ni ara wọn sì máa ń rí bẹ́ẹ̀. Ara dídá ṣáṣá tí àwọn olùborí ní fi hàn pé wọ́n jẹ́ olórí pípé. Àwọn ará Róòmù mọyì àwọn iṣẹ́ ọnà wọ̀nyí gan-an, ọ̀pọ̀ lára àwọn ère gbígbẹ́ náà ni wọ́n sì fi ṣe pápá ìṣeré, ilé ìwẹ̀, ilé ńláńlá àti ààfin wọn lọ́ṣọ̀ọ́.
Àwọn ará Róòmù fẹ́ràn àwọn eré oníwà ipá gan-an, nítorí náà, nínú gbogbo àwọn eré ìdárayá ilẹ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń ṣe ní Róòmù, ẹ̀ṣẹ́ kíkàn, ìjàkadì àti eré ìdárayá tó ní ẹ̀ṣẹ́ kíkàn àti ìjàkadì nínú ni wọ́n fẹ́ràn jù lọ. Àwọn ará Róòmù kò ka irú àwọn eré ìdárayá bẹ́ẹ̀ sí ìjà àjàmọ̀gá láàárín àwọn tó tó ara wọn mú, àmọ́ eré ìnàjú lásán ni wọ́n kà á sí. Wọn kò gbà pẹ̀lú àwọn ará Gíríìkì pé eré ìdárayá jẹ́ ara ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀tọ̀kùlú tó fẹ́ di jagunjagun àti eléré ìdárayá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn èèyàn Róòmù sọ àwọn eré ìdárayá Gíríìkì di eré ìmárale tí wọ́n ń ṣe ṣáájú kí wọ́n tó wẹ̀ tàbí eré ìdárayá tí àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ ń ṣe fún àwọn òǹwòran, irú bíi ìdíje ìjà àjàkú-akátá.
Ojú Tó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Fi Wo Ìdíje
Ọ̀ràn ìsìn tó so mọ́ àwọn eré ìdárayá wọ̀nyẹn jẹ́ ìdí kan tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi yàgò fún wọn, nítorí pé “ìfohùnṣọ̀kan wo . . . ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà?” (2 Kọ́ríńtì 6:14, 16) Àwọn eré ìdárayá òde òní ńkọ́?
Ó ṣe kedere pé wọn kò fi àwọn eré ìdárayá òde òní júbà àwọn ọlọ́run kèfèrí. Àmọ́, ǹjẹ́ a lè sọ pé kì í ṣe ẹ̀mí ìtara òdì làwọn ééyàn fi ń kópa nínú àwọn eré ìdárayá kan, bíi ti ayé àtijọ́? Àfi tá a bá fẹ́ tanra wa jẹ. Ìyẹn nìkan sì kọ́ o, onírúurú ìròyìn ti fi hàn pé láwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí, nítorí kí àwọn eléré ìdárayá kan lè borí, wọ́n máa ń lo àwọn oògùn olóró tó máa mú kí wọ́n lè ṣe dáadáa, èyí sì ń ṣàkóbá fún ìlera wọn tàbí kó ṣekú pa wọ́n pàápàá.
Lójú àwọn Kristẹni, àṣeyọrí nípa tara kọ́ ló ṣe pàtàkì. Àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tí í ṣe “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà” làwọn ohun tó ń mú ká jẹ́ ẹlẹ́wà lójú Ọlọ́run. (1 Pétérù 3:3, 4) A gbà pé kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń kópa nínú eré ìdárayá lóde òní ló ń fi ẹ̀mí ìbára-ẹni-díje tó gbóná ṣe é, àmọ́ ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ bíbá wọn kẹ́gbẹ́ á ràn wá lọ́wọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Ìwé Mímọ́ gbani pé ‘ká má ṣe ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n ká ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú?’ Àbí irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní yọrí sí “ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà”?—Fílípì 2:3; Gálátíà 5:19-21.
Ọ̀pọ̀ eré ìdárayá òde òní táwọn tó ń kópa nínú wọn máa ń fara gbúnra ló máa ń yọrí sí ìwà ipá. Ó yẹ kí ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí irú eré ìdárayá bẹ́ẹ̀ rántí ọ̀rọ̀ inú ìwé Sáàmù 11:5 pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”
Bá a bá fojú tó tọ́ wo eré ìmárale, ohun téèyàn ń gbádùn gan-an ni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì sọ pé “ara títọ́ ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀.” (1 Tímótì 4:7-10) Àmọ́ o, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa eré ìdárayá àwọn ará Gíríìkì, ńṣe ló kàn tọ́ka sí wọn láti fi wọ́n ṣàpèjúwe fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n ní àwọn ànímọ́ bí ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìfaradà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń lépa ni gbígba “adé” ìyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run ń fúnni. (1 Kọ́ríńtì 9:24-27; 1 Tímótì 6:12) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nike ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń lò fún “ìṣẹ́gun.”
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ìrísí Akànṣẹ́ Lẹ́yìn Ìjà
Ère tí wọ́n fi idẹ ṣe yìí, tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kẹrin ṣáájú Sànmánì Tiwa fi bí ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ayé ọjọ́un ṣe burú tó hàn. Ìwé tó sọ nípa ìpàtẹ tó wáyé nílùú Róòmù sọ pé, “ìjàraburabu akànṣẹ́ nínú ìjà àjàkúdórógbó, níbi tí wọ́n ti ń ‘fi ọgbẹ́ fún ọgbẹ́,’ ni wọ́n kà sí àpẹẹrẹ rere láti máa tẹ̀ lé.” Àpèjúwe náà ń bá a nìṣó pé: “Ọgbẹ́ tí wọ́n ní nínú ìjà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jà parí yóò wá jẹ́ àfikún sí èyí tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Fífi kẹ̀kẹ́ ẹṣin sáré ni eré ìdárayá tó gbayì jù lọ nínú àwọn ìdíje ayé àtijọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwọn ayàwòrán ayé àtijọ́ ya àwòrán bí Nike, tí í ṣe abo ọlọ́run ìṣẹ́gun abìyẹ́lápá, ṣe ń dé ẹni tó ṣẹ́gun ládé