Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Ní Ẹ̀sìn Tìrẹ?
‘KÒ DÌGBÀ tí mo bá dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan tàbí tí mò ń lọ sí ilé ìsìn déédéé kí n tó lè sọ pé mo gba Ọlọ́run gbọ́!’ Èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní tó bá kan ọ̀ràn dídara pọ̀ mọ́ ìjọ tàbí ètò ìsìn kan nìyẹn. Àní sẹ́, àwọn kan tiẹ̀ sọ pé àwọn túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run nígbà táwọn bá jáde síta tí àwọn ń wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ju ìgbà táwọn bá lọ ṣe ìsìn ní ilé ìjọsìn lọ. Èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lónìí ni pé, kì í ṣe kéèyàn kàn dara pọ̀ mọ́ ìjọ tàbí ètò ìsìn kan la máa fi mọ̀ pé onítọ̀hún gba Ọlọ́run gbọ́.
Àmọ́, èrò tí àwọn kan ní nípa ọ̀rọ̀ náà yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Wọ́n sọ pé tí ẹnì kan bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ ní ẹ̀sìn kan tó ń ṣe kó sì máa lọ sílé ìjọsìn déédéé. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ yìí ti wá kọjá ọ̀rọ̀ pé ká máa ka iye àwọn tó gbà pé ẹ̀sìn pọn dandan tàbí kò pọn dandan, tàbí ká máa fojú ohun táwọn ọ̀mọ̀wé sọ nípa ọ̀rọ̀ náà wò ó. Bó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ náà ti kan àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run, ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká mọ èrò Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ náà? Nígbà náà, kí la lè rí kọ́ nípa ọ̀ràn yìí látinú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀?
Bí Ọlọ́run Ṣe Bá Àwọn Èèyàn Lò Láyé Ìgbàanì
Ní nǹkan bi ẹgbàajì ó lè irínwó [4,400] ọdún sẹ́yìn, omi ya bo gbogbo ilẹ̀ ayé yìí pátá. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ò ṣeé gbàgbé, kódà onírúurú ẹ̀yà káàkiri ayé ló ní ìtàn náà nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìtàn náà yàtọ̀ síra, síbẹ̀ àwọn ìtàn náà bára mu ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà títí kan pé èèyàn díẹ̀ àtàwọn ẹranko mélòó kan ló la ìkún omi náà já.
Ṣé nítorí pé olóríire làwọn tó la Ìkún Omi náà jà ni wọ́n ò ṣe pa run? Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Bíbélì fi hàn pé bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀ràn rí. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Ọlọ́run kò sọ fún àwọn èèyàn yẹn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé Ìkún Omi ń bọ̀. Dípò ìyẹn Nóà ni Ọlọ́run sọ fún, Nóà yìí ló wá kìlọ̀ fáwọn tí wọ́n jọ wà láyé nígbà náà pé Àkúnya Omi ń bọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 6:13-16; 2 Pétérù 2:5.
Kí ẹnikẹ́ni tó lè la ìkún omi náà já, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Nóà, ó sì gbọ́dọ̀ ṣe tán láti tẹ́ lè ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún Nóà. Àní, tìtorí pé àwọn ẹranko tí ń bẹ nínú ọkọ̀ áàkì wà lára ẹgbẹ́ Nóà yìí ni wọ́n ṣe là Ìkún Omi náà já. Ọlọ́run fún Nóà nítọ̀ọ́ni tó ṣe pàtó pé kó ṣètò tó yẹ fún ìgbàlà àwọn ẹranko.—Jẹ́nẹ́sísì 6:17–7:8.
Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, àwọn àtọmọdọ́mọ Nóà tó wá láti ìlà ìdílé Ṣémù di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì. Síbẹ̀, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé òun yóò dá wọn nídè àti pé òun yóò kó wọn wá sí ilẹ̀ tí òun ti ṣèlérí fún Ábúráhámù, baba ńlá wọn. Ọlọ́run ò tún fi èyí náà han ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, àmọ́ ó kọ́kọ́ fi han àwọn tí ó yàn ṣe olórí wọn, ìyẹn Mósè àti Áárónì. (Ẹ́kísódù 3:7-10; 4:27-31) Lẹ́yìn tí àwọn ẹrú yìí fi ilẹ̀ Íjíbítì sílẹ̀, wọ́n gba Òfin Ọlọ́run lórí Òkè Sínáì, á sì sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.—Ẹ́kísódù 19:1-6.
Ohun tó mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ìgbàlà ni pé wọ́n jẹ́ ara ẹgbẹ́ tí Ọlọ́run dá sílẹ̀ àti pé wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn tá a yàn ṣe olórí ẹgbẹ́ náà. A tún fún àwọn ọmọ Íjíbítì kọ̀ọ̀kan láǹfààní láti dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tí ó hàn gbangba pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà yìí. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, lára àwọn ọmọ Íjíbítì bá wọn lọ, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ara wọn sí ipò àtí rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 12:37, 38.
Nígbà tó di ọ̀rúndún kìíní, Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, ó tún kó àwọn èèyàn jọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó bá wọn lò gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, bẹ́ẹ̀ náà ló sì tún fi ìfẹ́ hàn sí wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ipò wọn ṣe gbà. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́ pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan.” (Lúùkù 22:28, 29) Nígbà tó yá, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bà lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà nígbà tí wọ́n wà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan.—Ìṣe 2:1-4.
Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi hàn ní kedere pé ní ayé ọjọ́un, Ọlọ́run máa ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan. Àwọn mélòó kan tí Ọlọ́run dìídì bá lò ní tààràtà, irú bíi Nóà, Mósè àti Jésù àtàwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwọn tí Ọlọ́run gbẹ́nu wọn bá àwùjọ kan tó wà pa pọ̀ sọ́rọ̀. Ó dá wa lójú pé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá àwọn èèyàn lò nígbà yẹn ló gbà ń bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò lóde òní. Àmọ́, èyí á mú ká béèrè ìbéèrè mìíràn tó sọ pé: Ṣé dídara pọ̀ mọ́ ìsìn kan tó bá sáà ti wuni ti tó? A óò gbé ìbéèrè pàtàkì yìí yẹ̀ wo nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ó ti pẹ́ gan-an tí Ọlọ́run ti ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan tá a ṣètò