Ìbùkún Ni Fún Àwọn Tó Ń fi Ògo Fún Ọlọ́run
“Wọn yóò sì tẹrí ba níwájú rẹ, Jèhófà, wọn yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ.”—Sáàmù 86:9.
1. Kí nìdí tá a fi lè fi ògo fún Ọlọ́run làwọn ọ̀nà tó ga ju ti àwọn ìṣẹ̀dá aláìlẹ́mìí?
JÈHÓFÀ lẹ́tọ̀ọ́ sí ìyìn látọ̀dọ̀ gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀. Àwọn nǹkan aláìlẹ́mìí tí Ọlọ́run dá máa ń fi ògo fún un láìfọhùn, àmọ́ àwa ẹ̀dá èèyàn ní agbára láti ronú, láti lóye nǹkan, láti mọrírì nǹkan àti láti jọ́sìn. A jẹ́ pé àwa ni onísáàmù náà ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Ẹ fi ayọ̀ ìṣẹ́gun kígbe sí Ọlọ́run, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé. Ẹ kọ orin atunilára sí ògo orúkọ rẹ̀. Ẹ ṣe ìyìn rẹ̀ ní ológo.”—Sáàmù 66:1, 2.
2. Àwọn wo ló pa àṣẹ tó sọ pé ká fi ògo fún Ọlọ́run mọ́, kí sì nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀?
2 Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ẹ̀dá èèyàn ló kọ̀ láti mọ Ọlọ́run tàbí láti fi ògo fún un. Àmọ́, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní igba ó lé márùnlélọ́gbọ̀n orílẹ̀-èdè, tí wọ́n ń fi hàn pé àwọn ń rí “àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí” nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, tí wọ́n sì tún ń fi hàn pé àwọn ti “gbọ́” ẹ̀rí táwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ń jẹ́ láìfọhùn. (Róòmù 1:20; Sáàmù 19:2, 3) Ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì tí mu kí wọ́n mọ Jèhófà, ó sì ti mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Sáàmù 86:9, 10 sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ṣe yóò tìkára wọn wá, wọn yóò sì tẹrí ba níwájú rẹ, Jèhófà, wọn yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ. Nítorí pé ẹni ńlá ni ọ́, o sì ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu; ìwọ ni Ọlọ́run, ìwọ nìkan ṣoṣo.”
3. Báwo ni àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ṣe ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ tọ̀sán-tòru”?
3 Bákan náà ni Ìṣípayá 7:9, 15 ṣàpèjúwe “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn olùjọsìn pé wọ́n “ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” Kì í ṣe pé Ọlọ́run sọ pé kí àwọn ìránṣẹ́ òun máa fi ògo fún òun láìdáwọ́dúró o, àmọ́ inú ètò àjọ kan tó kárí ayé ni àwọn olùjọsìn rẹ̀ wà. Nítorí náà, nígbà tó bá jẹ́ òru ní àwọn apá ibì kan lágbàáyé, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà ní àwọn apá ibòmíràn tó jẹ́ ọ̀sán ní àkókò yẹn ń bá iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà lọ. Ìdí nìyẹn tá a fi lè sọ pé àwọn tó ń fi ògo fún Jèhófà ń ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀sán-tòru. Láìpẹ́, “gbogbo ohun eléèémí” ni yóò gbé ohùn wọn sókè láti yin Jèhófà. (Sáàmù 150:6) Àmọ́ ní báyìí ná, kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wá lè ṣe láti fi ògo fún Ọlọ́run? Àwọn ìṣòro wo la lè dojú kọ? Àwọn ìbùkún wo ló sì ń dúró de àwọn tó ń fi ògo fún Ọlọ́run? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé ìtàn Bíbélì kan yẹ̀ wò nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà Gádì.
Ìṣòro Kan Tó Wáyé Láyé Ìgbàanì
4. Ìṣòro wo ló dojú kọ ẹ̀yà Gádì?
4 Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà Gádì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ káwọn tẹ̀dó sí àgbègbè kan tó dáa fún ohun ọ̀sìn ní apá ìlà oòrùn odò Jọ́dánì. (Númérì 32:1-5) Gbígbé ní ibi tá a ń wí yìí yóò gba pé kí wọ́n fara da àwọn ìṣòro líle koko. Àfonífojì Jọ́dánì tó jẹ́ ìdènà fún àwọn tó bá fẹ́ gbógun dìde yóò jẹ́ ààbò fún àwọn ẹ̀yà tó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn. (Jóṣúà 3:13-17) Àmọ́, ohun tí ìwé The Historical Geography of the Holy Land, tí George Adam Smith kọ sọ nípa ilẹ̀ tó wà ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì ni pé: “Gbogbo ilẹ̀ náà ló tẹ́jú pẹrẹsẹ láìsí ìdènà kankan lórí òkè ńlá olórí pẹrẹsẹ ti àwọn ará Arabia. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo ìgbà làwọn alákòókiri tí ebi ń pa máa ń ya bò wọ́n, àwọn kan lára wọn sì máa ń fi ibẹ̀ ṣe pápá ìjẹko lọ́dọọdún.”
5. Kí ni Jékọ́bù gba àwọn ẹ̀yà Gádì níyànjú láti ṣe nígbà tí wọ́n bá gbógun tì wọ́n?
5 Kí ni ẹ̀yà Gádì máa ṣe nínú irú ìṣòro tí kò dáwọ́ dúró bẹ́ẹ̀? Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jékọ́bù baba ńlá wọn kú ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò yẹn, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ní ti Gádì, ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí yóò gbé sùnmọ̀mí lọ bá a, ṣùgbọ́n òun yóò gbé sùnmọ̀mí lọ bá apá ẹ̀yìn pátápátá.” (Jẹ́nẹ́sísì 49:19) Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn lè kọ́kọ́ dà bí èyí tó ń bani nínú jẹ́. Àmọ́ ní ti gidi, ó túmọ̀ sí pé a ní kí àwọn ọmọ Gádì gbẹ̀san lára wọn. Jékọ́bù mú un dá wọn lójú pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn onísùnmọ̀mí náà yóò fi ìtìjú sá padà, àwọn ọmọ Gádì yóò sì lépa wọn láti ẹ̀yìn.
Àwọn Ìṣòro Tó Dojú Kọ Ìjọsìn Wa Lónìí
6, 7. Báwo ni ipò táwọn Kristẹni wà lónìí ṣe jọ ti ẹ̀yà Gádì?
6 Bíi ti ẹ̀yà Gádì náà làwọn Kristẹni òde òní ṣe ń dojú kọ àwọn ìṣòro àtàwọn ìnira tí ètò Sátánì fà; kò sí iṣẹ́ ìyanu kankan tí kò ní jẹ́ ká dojú kọ ìṣòro. (Jóòbù 1:10-12) Ọ̀pọ̀ lára wa ló ní láti dojú kọ ìṣòro lílọ sílé ìwé, gbígbọ́ bùkátà àti títọ́ àwọn ọmọ. Àwọn ìṣòro kan tá ò lè gbójú fò dá wà tó jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni tàbí àwọn tí kò hàn síta. Àwọn kan ń fara da ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara wọn’ nítorí àìsàn lílé koko kan tàbí ìṣòro jíjẹ́ aláàbọ̀ ara. (2 Kọ́ríńtì 12:7-10) Ohun tó jẹ́ ìṣòro àwọn kan ni ríronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkankan. “Àwọn ọjọ́ oníỵọnu àjálù” ti ọjọ́ ogbó lè máà jẹ́ kí àwọn Kristẹni tó jẹ́ arúgbó sin Jèhófà pẹ̀lú irú okun tí wọ́n ní nígbà kan rí.—Oníwàásù 12:1.
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà tún rán wa létí pé “àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Gbogbo ìgbà la máa ń rí “ẹ̀mí ayé” yìí, ìyẹn ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ àti ti ìwà ìbàjẹ́ tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń gbé lárugẹ. (1 Kọ́ríńtì 2:12; Éfésù 2:2, 3) Bíi ti Lọ́ọ̀tì tó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwọn ohun búburú táwọn èèyàn ń sọ àtèyí tí wọ́n máa ń ṣe lóde òní lè máa bà wá nínú jẹ́. (2 Pétérù 2:7) Sátánì fúnra rẹ̀ tún máa ń gbéjà kò wá. Sátánì ń gbógun ti ìyókù àwọn ẹni àmì òróró, ìyẹn “àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 12:17) Àwọn “àgùntàn mìíràn” tí Jésù ní pàápàá máa ń dojú kọ àtakò Sátánì, bíi ká fòfin de iṣẹ́ wọn tàbí ká máa ṣe inúnibíni sí wọn.—Jòhánù 10:16.
Ṣé Ká Juwọ́ Sílẹ̀ Ni àbí Ká Gbéjà Kò Ó?
8. Kí ló yẹ ká ṣe nípa àtakò Sátánì, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
8 Kí lo yẹ ká ṣe sí àtakò Sátánì? Bíi ti ẹ̀yà Gádì ìgbàanì, àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí, ká gbéjà kò ó ní ìbámu pẹ̀lú ìdarí Ọlọ́run. Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan tí ń juwọ́ sílẹ̀ nítorí àwọn pákáǹleke ìgbésí ayé, wọ́n fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹrù iṣẹ́ wọn nípa tẹ̀mí. (Mátíù 13:20-22) Ohun tí Ẹlẹ́rìí kan sọ nípa ìdí táwọn tó ń wá sípàdé ṣe túbọ̀ ń dín kù nínú ìjọ tó wà nìyí, ó ní: “Àárẹ̀ ti ń mú àwọn ará. Wàhálà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa wọ́n.” Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń jẹ́ kí àárẹ̀ mú àwọn èèyàn lóde òní. Nítorí èyí, ó rọrùn láti ka ìjọsìn Ọlọ́run sí wàhálà kan, ìyẹn ohun àìgbọ́dọ̀máṣe tó ń fa ìnira. Àmọ́, ṣé èrò tó tọ̀nà nìyẹn?
9. Báwo ni gbígba àjàgà Kristi sọ́rùn ṣe lè fúnni ní ìtura?
9 Gbé ohun tí Jésù sọ fún àwọn èèyàn ọjọ́ ayé rẹ̀ yẹ̀ wò, ìyẹn àwọn tí pákáǹleke ìgbésí ayé ti sọ di aláàárẹ̀, ó ní: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.” Ǹjẹ́ Jésù sọ pé dídín iṣẹ́ ìsìn ẹni sí Ọlọ́run kù ló máa mú ìtura wá? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” Àjàgà jẹ́ ohun kan tá a fi igi tàbí irin ṣe tó ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún èèyàn tàbí ẹranko láti gbé ẹrù wíwúwo. Kí nìdí tí ẹnì kan á wá fẹ́ gba irú àjàgà bẹ́ẹ̀ sọ́rùn? Ǹjẹ́ “ẹrù [tá a dì] wọ̀ [wá] lọ́rùn” kò ti tó? Bẹ́ẹ̀ ni o, àmọ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Gíríìkì yẹn tún lè kà pé: “Ẹ jẹ́ kí a jọ ti ọrùn bọ àjàgà mi.” Ìwọ rò ó wò ná, Jésù sọ pé òun á ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ẹrù wa! A ò ní láti fi agbára tiwa nìkan gbé e.—Mátíù 9:36; 11:28, 29, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW; 2 Kọ́ríńtì 4:7.
10. Kí ló máa ń jẹ́ àbájáde ipa tá à ń sà láti fi ògo fún Ọlọ́run?
10 Nígbà tá a bá gba àjàgà dídi ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ́rùn, ńṣe là ń kọjú ìjà sí Sátánì. Ìwé Jákọ́bù 4:7 ṣèlérí pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ o. Sísin Ọlọ́run gba pé ká sapá dé àyè kan. (Lúùkù 13:24) Àmọ́ Bíbélì ṣe ìlérí yìí nínú Sáàmù 126:5 pé: “Àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn yóò fi igbe ìdùnnú ká a.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run tá a ń sin kì í ṣe aláìmoore. Ó jẹ́ “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a,” ó sì ń bù kún àwọn tó ń fi ògo fún un.—Hébérù 11:6.
Fífi Ògo fún Ọlọ́run Bá A Ṣe Jẹ́ Oníwàásù Ìjọba
11. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe jẹ́ ohun tá a fi ń dènà àtakò Sátánì?
11 Jésù pa á láṣẹ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Iṣẹ́ ìwàásù ni olórí ọ̀nà tá a gbà ń “rú ẹbọ ìyìn” sí Ọlọ́run. (Mátíù 28:19; Hébérù 13:15) Jíjẹ́ kí ‘ẹsẹ̀ wa di èyí tí a fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ̀ ní bàtà’ jẹ́ apá kan tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lára “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun” wa, ìyẹn ohun tá a fi ń dènà àtakò Sátánì. (Éfésù 6:11-15) Yíyin Ọlọ́run lógo lóde ẹ̀rí tún jẹ́ ọ̀nà àtàtà kan láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun. (2 Kọ́ríńtì 4:13) Ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí ọkàn wa ro èrò òdì. (Fílípì 4:8) Kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọsìn.
12, 13. Báwo ni lílọ sí òde ẹ̀rí déédéé ṣe lè ṣàǹfààní fáwọn ìdílé? Sọ àpẹẹrẹ kan.
12 Iṣẹ́ ìwàásù tún lè jẹ́ ìgbòkègbodò tó gbámúṣé fún ìdílé. Ká sòótọ́, àwọn ọmọdé nílò eré ìtura ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àmọ́, àkókò tí ìdílé kan bá lò lóde ẹ̀rí kò ní láti jẹ́ èyí tó ń kó àárẹ̀ báni. Àwọn òbí lè jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ gbádùn mọ́ àwọn ọmọ wọn nípa kíkọ́ wọn láti jẹ́ ọ̀jáfáfá nígbà tí wọ́n bá wà lóde ẹ̀rí. Ǹjẹ́ inú àwọn ọmọdé kì í dùn sí ohun tí wọ́n bá mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa? Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti túbọ̀ gbádùn ìṣẹ́ ìwàásù nípa gbígba tiwọn rò, kí wọ́n má sọ pé kí wọ́n ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ.—Jẹ́nẹ́sísì 33:13, 14.
13 Ní àfikún sí i, ìdè ìdílé tó ń yin Ọlọ́run pa pọ̀ máa ń lágbára gan-an. Gbé ọ̀ràn arábìnrin kan yẹ̀ wò, ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ pa òun àtàwọn ọmọ márùn-ún tì. Ó wá di dandan fún un láti wáṣẹ́ ṣe kó lè rí owó gbọ́ bùkátà àwọn ọmọ rẹ̀. Ǹjẹ́ ó jẹ́ kí ọwọ́ òun dí débi tí kò ti ráyè bójú tó ire tẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ̀? Ó sọ pé: “Mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì taápọntaápọn, mò sì gbìyànjú láti fi ohun tí mo kà sílò. Mo máa ń kó àwọn ọmọ lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé. Kí ni àbájáde ìsapá tí mo ṣe yìí? Gbogbo àwọn ọmọ mi márààrún ló ti ṣèrìbọmi.” Kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà déédéé lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ nínú bó o ṣe ń sapá láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.
14. (a) Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè fi ògo fún Ọlọ́run nílé ìwé? (b) Kí ló lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ tí wọn ò fi ní “tijú ìhìn rere” náà?
14 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, tẹ́ ẹ bá ń gbé ni orílẹ̀-èdè tí òfin ti fàyè gbà á, ǹjẹ́ ẹ máa ń fi ògo fún Ọlọ́run nípa jíjẹ́rìí nílé ìwé, àbí ńṣe lẹ máa ń jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn kò ìrẹ̀wẹ̀sì bá yín? (Òwe 29:25) Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá ní Puerto Rico kọ̀wé pé: “Ojú kì í tì mí láti wàásù nílé ìwé nítorí mo mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tí mò ń sọ. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń nawọ́ mi sókè nínú kíláàsì tí máa sì sọ ohun tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì fún wọn. Tí kò bá ti sí ohun tá à ń ṣe nínú kíláàsì, ibi ìkówèésí ni mo máa ń lọ tí máa sì lọ máa ka ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè.”a Ǹjẹ́ Jèhófà bù kún ìsapá rẹ̀ yìí? Ọmọbìnrin náà ròyìn pé: “Àwọn ọmọ kíláàsì mi máa ń bí mi láwọn ìbéèrè nígbà mìíràn, wọ́n tiẹ̀ ní kí n wá fún wọn ní ẹ̀dà ìwé náà pàápàá.” Tí o kò bá tíì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe èyí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó ṣì ní láti mú “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé” dá ara rẹ lójú nípa dídákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì taápọntaápọn. (Róòmù 12:2) Nígbà tó bá ti dá ọ lójú pé òtítọ́ ni ohun tó ò ń kọ́, wàá rí i pé o ò ní “tijú ìhìn rere” náà mọ́.—Róòmù 1:16.
‘Ilẹ̀kùn Ṣíṣísílẹ̀’ Kan fún Iṣẹ́ Ìsìn
15, 16. “Ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” wo làwọn Kristẹni kan tí wọnú rẹ̀, àwọn ìbùkún wo ló sì ti tibẹ̀ jáde?
15 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé a ti ṣí “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” sílẹ̀ fún òun. (1 Kọ́ríńtì 16:9) Ǹjẹ́ ipò tó o wà lè fún ọ láyè láti wọnú ilẹ̀kùn ìgbòkègbodò kan? Bí àpẹẹrẹ, ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé tàbí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ yóò gba pé kéèyàn máa lo àádọ́rin tàbí àádọ́ta wákàtí nínú iṣẹ́ ìwàásù náà lóṣooṣù. Ohun tá a mọ̀ ni pé àwọn Kristẹni máa ń mọyì iṣẹ́ ìsìn tòótọ́ táwọn aṣáájú ọ̀nà ń ṣe. Àmọ́, lílo tí wọ́n ń lo ọ̀pọ̀ àkókò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà kò mú kí wọ́n rò pé àwọn sàn ju àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, irú ẹ̀mí tí Jésù gbani níyànjú rẹ̀ ni wọ́n ní, tó sọ pé: “Àwa jẹ́ ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun. Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.”—Lúùkù 17:10.
16 Ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà gbà pé kéèyàn sẹ́ ara rẹ̀, kó ṣètò ara rẹ̀, kó sí ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan. Àmọ́, àwọn ìbùkún ibẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀dọ́ aṣáájú ọ̀nà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamika sọ pé: “Ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti mọ bí a ṣe ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ òtítọ́. Tó o bá ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, wàá máa lo Bíbélì gan-an. Ní báyìí, bí mo bá ti ń lọ láti ilé dé ilé, mo mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ipò onílé kọ̀ọ̀kan mu.” (2 Tímótì 2:15) Aṣáájú ọ̀nà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mica sọ pé: “Rírí i bí òtítọ́ ṣe ń nípa lórí ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn tún jẹ́ àgbàyanu ìbùkún.” Bákan náà ni ọ̀dọ́ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Matthew sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ tó wà nínú “rírí ẹnì kan tó wá sínú òtítọ́. Kò sí ayọ̀ tó lè rọ́pò èyí.”
17. Báwo ni Kristẹni kan ṣe borí èrò òdì tó ní nípa iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà?
17 Ṣé wàá gbé ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà yẹ̀ wò? Ó ṣeé ṣe kó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ kó o máa rò pé o ò tóótun láti ṣe é. Arábìnrin ọ̀dọ́ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kenyatte sọ pé: “Mo máa ń ní èrò òdì nípa iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Mi ò gbà pé mo tóótun láti ṣe é. Mi ò mọ bí mo ṣe máa múra ọ̀rọ̀ tí mo máa fi bẹ̀rẹ̀ ìwàásù mi tàbí bí mo ṣe máa bá àwọn èèyàn fọ̀rọ̀ wérọ̀ látinú Ìwé Mímọ́.” Àmọ́, àwọn alàgbà wá yan arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan tó dàgbà dénú láti bá a ṣiṣẹ́. Kenyatte sọ pé: “Ìwúrí gidi ló jẹ́ fún mi láti bá a ṣiṣẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ kó wù mí láti di aṣáájú ọ̀nà.” Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣírí díẹ̀ àti ìdálẹ́kọ̀ọ́, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà fẹ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà.
18. Àwọn ìbùkún wo làwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì lè ní?
18 Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tún lè ṣí ilẹ̀kùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mìíràn sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tọkọtaya kan lè tóótun láti lọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ míṣọ́nnárì kí a lè rán wọn jáde lọ wàásù ní ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn míṣọ́nnárì gbọ́dọ̀ mú ara wọn bá ipò tó wà ní orílẹ̀-èdè tuntun náà mu, bóyá kí wọ́n tiẹ̀ kọ́ èdè tuntun, àṣà tuntun àti oúnjẹ tuntun pàápàá. Àmọ́ ìbùkún ibẹ̀ kì í jẹ́ kí wọ́n rántí àwọn ipò tí kò bára dé wọ̀nyí. Obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mildred, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Mẹ́síkò, sọ pé: “Mi ò kábàámọ̀ ìpinnu tí mo ṣe láti di míṣọ́nnárì rí. Láti kékeré ni iṣẹ́ ọ̀hún ti ń wù mí.” Àwọn ìbùkún wo ló ti rí gbà? Ó sọ pé: “Ó máa ń ṣòro gan-an láti rẹ́ni kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní orílẹ̀-èdè mi. Àmọ́ níbí yìí, àwọn bíi mẹ́rin lára àwọn tí mo ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sóde ẹ̀rí ní àkókò kan náà!”
19, 20. Báwo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe rí ìbùkún gbà nínú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, iṣẹ́ kárí ayé, àti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?
19 Ọ̀pọ̀ ìbùkún ló tún wà fún àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Sven, arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń sìn ní Jámánì sọ nípa iṣẹ́ tó ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì pé: “Mo rí i pé ohun tó ṣàǹfààní gan-an ni mò ń ṣe. Kì í ṣe pé mi ò lè rí nǹkan fi iṣẹ́ tí mo kọ ṣe nínú ayé. Àmọ́ ńṣe ló máa dà bíi ìgbà téèyàn ń fowó pa mọ́ sí báńkì kan tó ti fẹ́ kógbá sílé.” Lóòótọ́, ó gba pé kéèyàn yáàfí àwọn nǹkan kan kó tó lè máa sìn bí olùyọ̀ǹda ara ẹni tí kì í gba owó oṣù. Àmọ́ Sven sọ pé: “Nígbà tó o bá ti ibi iṣẹ́ dé sílé, o mọ̀ pé Jèhófà lo ṣe gbogbo ohun tó o ṣe lọ́jọ́ yẹn fún. Ìyẹn á sì múnú rẹ dùn gan-an.”
20 Àwọn arákùnrin kan ti gbádùn ìbùkún ṣíṣe iṣẹ́ kárí ayé, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ ní àwọn ilẹ̀ òkèèrè. Tọkọtaya kan tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kọ̀wé pé: “Àwọn ará tó wà níbí yìí ṣèèyàn gan-an. Ojú máa ń ro wá gan-an tá a bá fẹ́ fi wọ́n sílẹ̀, èyí ló sì máa jẹ́ ìgbà kẹjọ tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ‘ṣe’ wá. Ẹ ò rí i pé à ń gbádùn iṣẹ́ náà gan-an!” Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tún wà níbẹ̀. Ó ń fún àwọn arákùnrin àpọ́n tó tóótun láǹfààní àtigba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí. Ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege níbẹ̀ kọ̀wé pé: “Mi ò mọ ọ̀rọ̀ tí mo lè lò bí mo ṣe ń gbìyànjú láti wá ọ̀nà ti mo máa fi dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún irú àgbàyanu ilé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. Ètò àjọ wo ló lè sapá tó yẹn láti dá èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?”
21. Kí ni ohun tí gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run?
21 Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀pọ̀ ilẹ̀kùn ìgbòkègbodò ló ṣí sílẹ̀. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ju lọ wa ni kò láǹfààní àtisìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí nílẹ̀ òkèèrè. Jésù fúnra rẹ̀ mọ̀ pé iye “èso” táwọn Kristẹni máa so yóò yàtọ̀ síra nítorí onírúurú ipò tí wọ́n wà. (Mátíù 13:23) Ohun tó yẹ kí àwa Kristẹni ṣe nígbà náà ni pé ká lo ipòkípò tá a bá wà lọ́nà tó dára jù lọ, ká máa kó ipa kíkún nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bí ipò wa bá ṣe gbà. Nígbà tá a bá ṣe ìyẹn, Jèhófà ni à ń fi ògo fún, ó sì dá wa lójú pé inú rẹ̀ dùn sí ohun tá à ń ṣe. Wo àpẹẹrẹ Ethel, arábìnrin àgbàlagbà kan tó ń gbé ní ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó. Ó máa ń jẹ́rìí déédéé fún àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ilé kan náà, ó sì máa ń ṣe ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù pẹ̀lú. Tọkàntọkàn ló fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìfi ọjọ́ ogbó pè.—Mátíù 22:37.
22. (a) Àwọn ọ̀nà wo la tún lè gbà fi ògo fún Ọlọ́run? (b) Àkókò àgbàyanu wo ló ń dúró dè wá?
22 Àmọ́ ṣá o, rántí pé ìwàásù wulẹ̀ jẹ́ ọkàn lára àwọn ọ̀nà tá à ń gbà fi ògo fún Jèhófà. A óò mú ọkàn Jèhófà yọ̀ tí ìwà wa àti ìrísí wa bá jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa, nílé ìwé wa àti nínú ilé wa pẹ̀lú. (Òwe 27:11) Ìwé Òwe 28:20 ṣèlérí pé: “Ènìyàn tí ó ń ṣe àwọn ìṣe ìṣòtítọ́ yóò gba ọ̀pọ̀ ìbùkún.” Nítorí náà, ó yẹ ká “fúnrúgbìn yanturu” nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé a óò rí àwọn ìbùkún yanturu gbà. (2 Kọ́ríńtì 9:6) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí a ní àǹfààní láti wà láàyè ní àkókò àgbàyanu náà, nígbà tí “gbogbo ohun eléèémí” yóò fi ògo tí ó tọ́ sí Jèhófà fún un!—Sáàmù 150:6.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń sin Jèhófà “tọ̀sán-tòru”?
• Ìṣòro wo ni ẹ̀yà Gádì dojú kọ, ẹ̀kọ́ wo sì ni ìyẹn fi kọ́ àwa Kristẹni lónìí?
• Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àtakò Sátánì?
• ‘Ilẹ̀kùn ṣíṣísílẹ̀’ wo làwọn kan ti wọnú rẹ̀, kí sì làwọn ìbùkún tí wọ́n ti rí níbẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bí àwọn ọmọ Gádì ṣe bá agbo onísùnmọ̀mí jà, àwa Kristẹni náà gbọ́dọ̀ dójú ìjà kọ àtakò Sátánì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
A ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tí ń gbéni ró nínú iṣẹ́ ìwàásù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lè ṣí ilẹ̀kùn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mìíràn sílẹ̀, títí kan:
1. Iṣẹ́ kárí ayé
2. Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì
3. Iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì