Ó Bá Àwọn Ọmọ Kíláàsì Rẹ̀ Sọ̀rọ̀ Nípa Ẹ̀sìn Rẹ̀
ṢÉ WÀÁ fẹ́ ran àwọn ọmọ kíláàsì rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lóye ìgbàgbọ́ rẹ tá a gbé karí Bíbélì? Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Magdalena, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún tó ń lọ sílé ìwé girama ní orílẹ̀-èdè Poland máa ń bá àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣe. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń bi í láwọn ìbéèrè bíi, ‘Irú èèyàn wo ni ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà?’ àti ‘Ṣé o ò gba Jésù Kristi gbọ́ ni?’ Báwo ni ọmọbìnrin yìí ṣe máa ran àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ lọ́wọ́? Magdalena gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà, ó sì sapá láti ṣiṣẹ́ lórí àdúrà rẹ̀.—Jákọ́bù 1:5.
Lọ́jọ́ kan, Magdalena lọ bá olùkọ́ kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn Magdalena, ó sì bi í bóyá òun lè fi fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Namea [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ètò Àjọ Tí Ń Jẹ́ Orúkọ Yẹn] han àwọn ọmọ kíláàsì òun. Olùkọ́ náà gbà pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Magdalena wá sọ fáwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ pé: “Mò ń ṣètò bí ọ̀rẹ́ mi kan ṣe máa wá bá kíláàsì wa fọ̀rọ̀wérọ̀ fún wákàtí kan ààbọ̀. A óò wo fídíò kan lákòókò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà, a óò sì sọ̀rọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú. Ṣé ẹ máa wá síbẹ̀?” Gbogbo wọn sọ pé àwọn máa wá. Bí Magdalena àti Wojciech, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù alákòókò-kíkún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í múra ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí nìyẹn.
Ètò tí wọ́n ṣe ni pé àwọn á bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ogún ìṣẹ́jú tó dá lórí ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?b ìbéèrè àti ìdáhùn á wá tẹ̀ lé e. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n á wá wo fídíò ní yàrá ìkówèésí ilé ìwé wọn. Wọ́n á sì fún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan nínú kíláàsì náà ní ẹ̀bùn kan, ìyẹn àpòòwé tí wọ́n kó àwọn ìwé pẹlẹbẹ mélòó kan, ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́,c àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú mélòó kan àtàwọn ìwé ìròyìn, sínú rẹ̀.
Lọ́jọ́ tí wọ́n fi ètò náà sí, àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ mẹ́rìnlá ló wà níbẹ̀, olùkọ́ yẹn náà wà níbẹ̀ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin mìíràn tí wọ́n wà ní yàrá ìkówèésí lákòókò náà. Wojciech kọ́kọ́ ṣàlàyé pé àwọn akéwì àtàwọn òǹkọ̀wé bíi mélòó kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Poland lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, nínú àwọn ìwé wọn. Ó tún mẹ́nu kan àwọn ògbólógbòó ìwé katikísìmù ti àwọn Kátólíìkì tí orúkọ Ọlọ́run wà nínú rẹ̀. Nígbà tó ń ṣàlàyé ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní, ó fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí àwòrán onírúurú ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa wà nínú rẹ̀ àtàwọn fọ́tò Gbọ̀ngàn Àpéjọ bíi mélòó kan hàn wọ́n.
Ìjíròrò alárinrin wá tẹ̀ lé e. Magdalena àti Wojciech sì fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Èyí wú àwọn tó wà níbẹ̀ lórí gan-an, wọ́n sì wá rí i kedere pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í wàásù èrò ti ara wa. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí wọ́n béèrè, báwo ni wọ́n sì ṣe dáhùn?
Ìbéèrè: Ọ̀pọ̀ gbólóhùn tó ṣòro lóye àtàwọn àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ló wà nínú Bíbélì, téèyàn lè túmọ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà. Báwo lèèyàn ṣe lè máa ṣe ohun tí Bíbélì sọ?
Ìdáhùn: Àwọn kan sọ pé Bíbélì dà bíi gòjé téèyàn lè fi kọ orin tó bá wù ú. Àmọ́, ìwọ rò ó wò ná: Tó o bá fẹ́ mọ nípa ohun tí òǹkọ̀wé kan ní lọ́kàn tó fi kọ ohun tó wà nínú ìwé rẹ̀, ǹjẹ́ kò ní dára kó o lọ bi òun fúnra rẹ̀? Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó ni Bíbélì, wà láàyè lọ́jọ́kọ́jọ́, kò dà bí àwọn òǹkọ̀wé tó ti kú. (Róòmù 1:20; 1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Ohun tí wọ́n sọ ṣáájú àti lẹ́yìn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan lè jẹ́ ka mọ ohun tí ẹsẹ náà túmọ̀ sí. Àti pé Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ lórí kókó kan náà láwọn ibi mélòó kan, nítorí náà fífi ohun tó sọ lápá ibi kan wé ohun tó sọ lápá ibòmíràn lè ṣèrànwọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè jẹ́ kí Ọlọ́run darí èrò wa bí ẹni pé òun fúnra rẹ̀ ló ń ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà fún wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀, a ó sì máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì mu, àbí a ò ni lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Ìbéèrè: Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Kristẹni àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Ìdáhùn: Kristẹni ni wá! Àmọ́ dípò kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa fẹnu lásán pe ara wọn ní Kristẹni, wọ́n ń sapá láti fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ohun tí Ọlọ́run ń kọ́ wọn ṣèwà hù láti ṣe ara wọn láǹfààní. (Aísáyà 48:17, 18) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé orí Bíbélì ni wọ́n gbé gbogbo ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni kà, wọ́n mọ̀ dájú pé ìsìn tòótọ́ ni ẹ̀sìn àwọn.—Mátíù 7:13, 14, 21-23.
Ìbéèrè: Kí nìdí tẹ́ ẹ lọ ń bá àwọn tẹ́ ò mọ̀ rí rárá, tẹ́ ẹ ó sì sọ pé àfi dandan kẹ́ ẹ bá wọn sọ̀rọ̀? Ṣé ìyẹn kì í ṣe pé ẹ̀ ń fipá sọ ohun tẹ́ ẹ gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíràn?
Ìdáhùn: Ṣé o rò pé ohun tó burú ni kí ẹnì kan bá ọ sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lójú pópó, kó sì béèrè èrò rẹ nípa ohun kan? (Jeremáyà 5:1; Sefanáyà 2:2, 3) (Wojciech àti Magdalena wá ṣe àṣefihàn ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń rìn lójú pópó bóyá Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn tí ìkún omi tó wáyé ní ilẹ̀ Poland láìpẹ́ yìí ṣe lọ́ṣẹ́.) Lẹ́yìn tá a bá gbọ́ èrò onítọ̀hún, àá wá sọ ohun tí Bíbélì wí fún un. Tí ẹnì kan ò bá sì fẹ́ bá wa sọ̀rọ̀, ńṣe la máa kí onítọ̀hún pé ó dàbọ̀, a ó sì máa bá tiwa lọ. (Mátíù 10:11-14) Ṣé à ń fipá bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nìyẹn? Àbí èèyàn ò tún gbọ́dọ̀ bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀ mọ́ ni?
Ìbéèrè: Kí nìdí tẹ́ ẹ kì í ṣọdún?
Ìdáhùn: Ayẹyẹ kan ṣoṣo tí Bíbélì sọ pé ká máa ṣe là ń ṣe, ìyẹn ni Ìrántí Ikú Jésù Kristi. (1 Kọ́ríńtì 11:23-26) Ní ti àwọn ayẹyẹ ọdún wọ̀nyẹn, ẹ lè yẹ àwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀ àtàwọn ìwé mìíràn tó ṣeé fọkàn tán wò kẹ́ ẹ lè mọ ìtàn bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀. Tẹ́ ẹ bá yẹ àwọn ìwé yẹn wò, ẹ óò rí ìdí tá ò fi ń ṣe irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 6:14-18.
Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni wọ́n tún béèrè lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n sì dáhùn gbogbo ẹ̀. Ìjíròrò náà gba àkókò tó pọ̀ gan-an débi pé wọ́n ní láti fi fídíò wíwò sí ọjọ́ mìíràn.
Kí ni àwọn ọmọ ilé ìwé náà ṣe nígbà ìjíròrò náà? Ẹ jẹ́ kí Magdalena sọ fún wa, ó ní: “Ó yà mi lẹ́nu pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n máa ń ṣe bí ẹni tí ò lọ́pọlọ tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì máa ń fi èèyàn ṣe yẹ̀yẹ́ béèrè àwọn ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ pé àwọn ò gbà pé Ọlọ́run wà, síbẹ̀ ní àkókò ìjíròrò náà wọ́n fi hàn pé àwọn gbà pé Ọlọ́run wà!” Tayọ̀tayọ̀ làwọn tó wà níbẹ̀ fi gba àwọn ẹ̀bùn tá a fún wọn, àpapọ̀ ohun tá a sì fún wọn jẹ́ ìwé ńlá márùndínlógójì, ìwé pẹlẹbẹ mẹ́tàlélọ́gọ́ta, àti ìwé ìròyìn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n.
Ẹ ò rí i pé àbájáde ohun tí wọ́n ṣe nílé ìwé yìí kọyọyọ! Kì í ṣe pé ó ran àwọn ọmọ kíláàsì Magdalena lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí wọ́n sì lóye wọn dáadáa nìkan ni, àmọ́ ó tún jẹ́ ìṣírí fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ náà láti ronú lórí ìdí téèyàn fi wà láyé. Ṣé wàá gbìyànjú láti ran àwọn ọmọ kíláàsì rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde.
c Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Magdalena àti Wojciech ń múra ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ sọ náà sílẹ̀