Àwọn Èèyàn Ń Wá Aṣáájú Rere
“Mo ni kó o kúrò, o ò wúlò fún wa mọ́. Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́, kúrò lórí àlééfà!”—Oliver Cromwell ló sọ ọ̀rọ̀ yìí; Leopold Amery tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló tún ọ̀rọ̀ náà sọ.
Ó ti tó oṣù mẹ́jọ tí wọ́n ti ń ja Ogun Àgbáyé Kejì, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti bá a lọ, ó sì dà bíi pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àtàwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jọ lẹ̀dí àpò pọ̀ ò lè rọ́wọ́ mú nínú ogun náà mọ́. Èrò Leopold Amery àtàwọn mìíràn tí wọ́n jọ ń ṣèjọba nígbà náà ni pé, àwọn gbọ́dọ̀ ní aṣáájú tuntun. Nítorí náà, nígbà tó di May 7, 1940, Ọ̀gbẹ́ni Amery sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí fún Neville Chamberlain tó jẹ́ Olórí Ìjọba ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kékeré. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn ni ọ̀gbẹ́ni Chamberlain kúrò lórí àlééfà, Winston Churchill sì gbapò rẹ̀.
Ọ̀KAN lára ohun pàtàkì tí ẹ̀dá ènìyàn ń fẹ́ ni kí ẹnì kan jẹ́ aṣáájú wọn, àmọ́ kì í kàn án ṣe aṣáájú kan lásán. Kódà, nínú ìdílé pàápàá, bàbá gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó dáńgájíá tó láti mú ipò iwájú kí inú ìyàwó àtàwọn ọmọ tó lè dùn. Mélòó-mélòó wá ni ẹni tó jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè tàbí aṣáájú kan nínú ayé! Abájọ tó fi ṣòro láti rí àwọn aṣáájú rere.
Látàrí èyí, ọ̀pọ̀ ìfinijoyè, ìyípadà tegbòtigaga, ìdìtẹ̀ gbàjọba, gbígbé ẹnì kan gorí àlééfà, ìdìbò yanni, ìpànìyàn àti ọ̀pọ̀ ìyípadà ló ti wáyé láwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó ti kọjá. Ọ̀pọ̀ àwọn ọba, àwọn olórí ìjọba, àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè, àwọn ààrẹ, àwọn akọ̀wé àgbà, àtàwọn apàṣẹwàá ló ti fìgbà kan jẹ́ aṣáájú tí wọ́n sì ti kúrò lórí oyè. Àwọn ìyípadà kan tó ṣàdédé wáyé ti mú kí àwọn aṣáájú tó jẹ́ alágbára pàápàá kúrò lórí oyè. (Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Wọ́n Pàdánù Ipò Wọn Lójijì,” ni ojú ìwé 5.) Síbẹ̀, èèyàn ò tíì rí aṣáájú tó dáńgájíá tó sì wà pẹ́ títí.
“A Gbọ́dọ̀ Gba Èyí Tá A Ní Bẹ́ẹ̀,” àbí Òmíràn Wà?
Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gba pé a ò lè rí aṣáájú rere láé. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àkókò ìdìbò gan-an làwọn èèyàn máa ń hùwà kò-kàn-mi jù lọ tí wọ́n sì máa ń rò pé nǹkan ò lè dáa mọ́. Geoff Hill, tó jẹ́ akọ̀ròyìn ní ilẹ̀ Áfíríkà sọ pé: “Ìwà kò-kàn-mí àti káwọn èèyàn máa sá [fún ìbò dídì] máa ń wọ́pọ̀ nígbà táwọn èèyàn bá rí i pé kò sóhun táwọn lè ṣe láti tán ìyà tó ń jẹ àwọn. . . . Nílẹ̀ Áfíríkà, táwọn èèyàn ò bá dìbò, kò túmọ̀ sí pé wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n gbà ń wá ìrànlọ́wọ́ nítorí kó sẹ́ni tó bìkítà nípa ìyà tó ń jẹ wọ́n.” Bákan náà ni akọ̀ròyìn kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé nípa ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà, ó ní: “Ó wù mí kó jẹ́ pé ẹni pípé kan ló gbé àpótí láti ṣèjọba.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kò sírú èèyàn bẹ́ẹ̀ láyé yìí. A ò sì lè rí irú ẹni bẹ́ẹ̀ láé. A gbọ́dọ̀ gba èyí tá a ní bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀.”
Ṣé lóòótọ́ ni kò sóhun táwọn èèyàn lè ṣe ju pé kí wọ́n “gba” àwọn aṣáájú tó jẹ́ aláìpé wọ̀nyí “bẹ́ẹ̀”? Ṣé báwọn èèyàn tó jẹ́ aṣáájú ò ṣe lè tẹ́ àwọn ọmọ abẹ́ wọn lọ́rùn yìí wá túmọ̀ sí pé a ò lè ní aṣáájú rere mọ́ láé ni? Rárá o. Aṣáájú tó dára jù lọ wà. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò sọ aṣáájú tó pegedé jù lọ tí aráyé nílò àti bí ìjọba rẹ̀ yóò ṣe ṣàǹfààní fún ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn tí wọ́n wá láti ibi gbogbo, títí kan ìwọ alára.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ní òkè lápá òsì: Neville Chamberlain
Ní òkè lápá ọ̀tún: Leopold Amery
Nísàlẹ̀: Winston Churchill
[Àwọn Credit Line]
Chamberlain: Fọ́tò látọwọ́ Jimmy Sime/Central Press/Getty Images; Amery: Fọ́tò látọwọ́ Kurt Hutton/Picture Post/Getty Images; Churchill: The Trustees of the Imperial War Museum (MH 26392)