ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 8/1 ojú ìwé 13-15
  • Ìgbà Wo Ló Yẹ Kéèyàn Bínú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Ló Yẹ Kéèyàn Bínú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Táwọn Kan Dá sí Jèhófà
  • Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Ńlá Táwọn Èèyàn Ṣẹ Èèyàn Ẹlẹgbẹ́ Wọn
  • Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Kéékèèké
  • Kí Ni Ìdáríjì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • ‘Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Dídáríji Ara Yín Lẹ́nì Kíní Kejì’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ẹ Máa Dárí Jini Látọkàn Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 8/1 ojú ìwé 13-15

Ìgbà Wo Ló Yẹ Kéèyàn Bínú?

BÍBÉLÌ sọ nínú ONÍWÀÁSÙ 7:9 pé: “Fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.” Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé kò yẹ ká máa bínú sódì tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa dárí jini.

Àmọ́, ṣé ohun tí Oníwàásù 7:9 ń sọ ni pé kò yẹ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni mú wa bínú? Ṣé ohun tó ń sọ ni pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ la gbọ́dọ̀ dárí rẹ̀ jini láìka bí ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe tóbi tó tàbí láìka bí ẹni náà ṣe ṣẹ̀ wá lemọ́lemọ́ tó? Ṣé ó sì yẹ ká fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ láìyanjú? Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa múnú bí àwọn ẹlòmíràn nínú ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe wa ká má sì bìkítà nítorí a mọ̀ pé ó yẹ kẹ́ni tá a ṣẹ̀ dárí jì wá? Rárá o, kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.

Kò sẹ́ni tó ní ìfẹ́, àánú, ìdáríjì àti ìpamọ́ra tó Jèhófà Ọlọ́run. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì sọ pé àwọn kan ṣẹ Ọlọ́run. Bí ẹ̀ṣẹ̀ náà bá burú gan-an, ó máa ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ náà. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Táwọn Kan Dá sí Jèhófà

Àkọsílẹ̀ tó wà ní 1 Àwọn Ọba 15:30 sọ nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù ‘èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀, àti nítorí ìmúnibínú rẹ̀, èyí tí ó fi mú Jèhófà bínú.’ Bíbélì sọ nípa Áhásì Ọba Júdà ní 2 Kíróníkà 28:25 pé: ‘Ó sì ṣe àwọn ibi gíga fún rírú èéfín ẹbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn tí ó fi jẹ́ pé ó mú Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀ bínú.’ A tún rí àpẹẹrẹ mìíràn nínú Onídàájọ́ 2:11-14, ó ní: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣubú sínú ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, wọ́n sì ń sin àwọn Báálì . . . , tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi mú Jèhófà bínú. . . . Látàrí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí Ísírẹ́lì, tí ó fi fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn akóni-ní-ìkógun.”

Àwọn ohun mìíràn tún wà tó mú Jèhófà bínú tó sì gba pé kó fìyà tó múná jẹ àwọn tó ṣe nǹkan náà. Bí àpẹẹrẹ, ní Ẹ́kísódù 22:18-20 a kà pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pa oníṣẹ́ àjẹ́ mọ́ láàyè. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sùn ti ẹranko ni kí a fi ikú pa dájúdájú. Ẹni tí ó bá rúbọ sí àwọn ọlọ́run èyíkéyìí bí kò ṣe sí Jèhófà nìkan ṣoṣo ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun.”

Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣẹ̀ jì wọ́n, bí wọ́n ti ń múnú bí i tí wọn ò sì ronú pìwà dà. Níkẹyìn, Ọlọ́run pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ náà run, nítorí pé wọn ò ronú pìwà dà àti pé kò sí àmì pé wọ́n múra tán láti yí ìwà wọn padà kí wọ́n sì ṣègbọràn sí Jèhófà. Èyí ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí àwọn ará Bábílónì pa á run, àti nígbà tí àwọn ará Róòmù tún pa á run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni.

Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà máa ń bínú nígbà táwọn èèyàn bá ṣe ohun búburú tàbí tí wọ́n bá sọ ohun búburú, kódà ó máa ń pa àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn pàpọ̀jù tí wọn ò sì ronú pìwà dà run. Àmọ́, ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé Jèhófà wà lára àwọn tí Oníwàásù 7:9 ń sọ? Rárá o. Jèhófà jàre bó ṣe ń bínú sáwọn tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó sì máa ń dá wọ́n lẹ́jọ́ bó ṣe tọ́. Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.”—Diutarónómì 32:4.

Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Ńlá Táwọn Èèyàn Ṣẹ Èèyàn Ẹlẹgbẹ́ Wọn

Lábẹ́ Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, wọ́n máa ń fìyà ńlá jẹ ẹni tó bá ṣẹ èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bí olè kan bá wọlé kan lóru tí onílé náà sì pa á, kò sí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lọ́rùn onílé náà. Ọrùn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá náà. Nítorí ìdí yìí, a kà pé: “Bí a bá rí olè kan tí ń fọ́lé tí a sì lù ú, tí ó sì kú, kò sí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ [lọ́rùn onílé náà].”—Ẹ́kísódù 22:2.

Obìnrin kan tí ọkùnrin kan fipá bá lò pọ̀ lẹ́tọ̀ọ́ láti bínú gan-an sẹ́ni tó dá ẹ̀ṣẹ̀ náà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni lójú Ọlọ́run. Lábẹ́ Òfin Mósè ọkùnrin tó bá fipá bá obìnrin kan lò pọ̀ yóò kú “bí ìgbà tí ọkùnrin kan dìde sí ọmọnìkejì rẹ̀, tí ó sì ṣìkà pa á ní ti gidi.” (Diutarónómì 22:25, 26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò sí lábẹ́ Òfin yẹn mọ́, ó ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí ìfipábánilòpọ̀ tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an ṣe rí lójú Jèhófà.

Ní àkókò tiwa yìí náà, ìfipábánilòpọ̀ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó gba kí wọ́n fìyà tó múná jẹ ẹni tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ náà. Ó yẹ kẹ́ni tí wọ́n ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí sọ fún ọlọ́pàá. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn aláṣẹ a fìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀ náà. Bí ẹni tẹ́nì kan fipá bá lò pọ̀ bá jẹ́ ọmọdé, àwọn òbí lè fẹjọ́ sun àwọn aláṣẹ.

Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Kéékèèké

Bó ti wù kó rí, kì í ṣe gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ làwọn aláṣẹ ń fìyà jẹni nítorí rẹ̀. Nítorí náà, kò yẹ ká máa bínú nítorí àwọn àṣìṣe kéékèèké táwọn èèyàn bá ṣe, ńṣe ló yẹ ká máa dárí rẹ̀ jì wọ́n. Ẹ̀ẹ̀melòó ló yẹ́ ka dárí ji àwọn èèyàn? Àpọ́sítélì Pétérù bi Jésù léèrè pé: “Olúwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mí, tí èmi yóò sì dárí jì í? Títí dé ìgbà méje ni bí?” Jésù wí fún un pé: “Mo wí fún ọ, kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.”—Mátíù 18:21, 22.

Síbẹ̀ náà o, a ní láti máa bá a nìṣó láti tún ìwà wa ṣe gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ká má bàa máa fìgbà gbogbo ṣẹ àwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí nǹkan bá da ìwọ àtàwọn ẹlòmíràn pọ̀, ǹjẹ́ o máa ń la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀? Ṣé ẹlẹ́nu mímú ni ọ́, tàbí o máa ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀? Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè bí àwọn èèyàn nínú. Dípò kéèyàn máa dẹ́bi fún ẹni téèyàn ṣẹ̀ pé onítọ̀hún ló yẹ kó dárí ji òun, ó yẹ kó mọ̀ pé òun lòun fà á tẹ́ni náà fi bínú. Ó yẹ kẹ́ni tó ń múnú bí èèyàn wá nǹkan ṣe sí ìṣe àti ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kó má bàa máa múnú bíni. Ìsapá yìí kò ní jẹ ká máa mú àwọn ẹlòmíràn bínú ní gbogbo ìgbà. Bíbélì rán wa létí pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Tá a bá ṣẹ àwọn ẹlòmíràn, kódà ká tiẹ̀ ní a ò mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ̀ wọ́n, títọrọ àforíjì yóò mú kí ọ̀ràn náà yanjú.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká “máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 14:19) Tá a bá ń fi ọgbọ́n báni sọ̀rọ̀ tá a sì ní ìyọ́nú, a jẹ́ pé a fi ohun tí òwe kan sọ sílò nìyẹn pé: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 25:11) Ẹ wo bí èyí ṣe dára tó, ẹ sì wo bó ṣe múnú ẹni dùn tó! Ọ̀rọ̀ tá a fi ọgbọ́n sọ tó sì mára tuni tiẹ̀ lè yí ìwà líle àwọn èèyàn padà pàápàá, nítorí pé, ‘ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lè fọ́ egungun.’—Òwe 25:15.

Nítorí ìdí yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kólósè 4:6) Ìtumọ̀ gbólóhùn náà, “tí a fi iyọ̀ dùn” ni pé, ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa máa dùn mọ́ àwọn èèyàn, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún mímúnú bí àwọn èèyàn. Nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe, àwọn Kristẹni máa ń gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, èyí tó sọ pé: “Máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.”—1 Pétérù 3:11.

Nítorí náà, ó ṣe kedere pé ohun tí Oníwàásù 7:9 túmọ̀ sí ni pé kò yẹ ká máa bínú nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké táwọn èèyàn lè ṣẹ̀ wá. Ó lè jẹ́ pé àìpé ẹ̀dá ló fà á tàbí kẹ́ni náà tiẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é pàápàá, síbẹ̀ wọ́n kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tó yẹ kéèyàn fún ìka mọ́. Àmọ́ nígbà tí ìwà àìtọ́ náà bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ó yẹ ká mọ̀ pé ẹni tá a ṣẹ̀ náà lè bínú, ó sì lè fẹ́ ṣe nǹkan kan nípa ọ̀ràn náà.—Mátíù 18:15-17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Jèhófà lo àwọn ará Róòmù láti pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò ronú pìwà dà run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

“Bí àwọn èso ápù ti wúrà . . . ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́