ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 1/1 ojú ìwé 2-4
  • Ibi Yí Ire Ká

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibi Yí Ire Ká
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwà Ibi Ń Peléke Sí I
  • Ire Ní Ìdojú-ìjà Kọ Ibi—Ijakadi Àtọjọ́mọ́jọ́ Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ire Yoo Ha Bori Ibi Lae Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bí Ire Ṣe Máa Borí Ibi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìyà Tó Ń jẹ Ẹ̀dá Èèyàn Tojú Súni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 1/1 ojú ìwé 2-4

Ibi Yí Ire Ká

NÍNÚ ayé lónìí, agbára káká la fi lè rí àwọn èèyàn tó múra tán láti lo ara wọn fáwọn ẹlòmíì. Síbẹ̀ náà, àwọn kan wà tí wọ́n fẹ́ ṣe ohun tó máa ṣe àwọn ẹlòmíì láǹfààní láwọn ọ̀nà kan. Ọdọọdún ni àìmọye èèyàn ń fi ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là ṣètọrẹ fáwọn àjọ tí wọ́n ń ṣe àwọn aláìní lóore. Bí àpẹẹrẹ, owó táwọn èèyàn dá láti fi ṣètọrẹ àánú nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2002 pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó wọ bílíọ̀nù mẹ́tàlá dọ́là. Láti ọdún 1999 sí àkókò tá a wà yìí, ó lé ní bílíọ̀nù méjìdínlógójì dọ́là táwọn mẹ́wàá kan tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú tí wọ́n sì lawọ́ gan-an fi ṣètọrẹ tàbí tí wọ́n ṣèlérí pé àwọn a fi ran àwọn aláìní lọ́wọ́.

Lára àwọn iṣẹ́ rere táwọn aláàánú máa ń ṣe ni sísan owó táwọn ìdílé tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ máa fi gbàtọ́jú nílé ìwòsàn, rírán àwọn ọmọ olóbìí-kan lọ sílé ìwé, àti nínáwó lórí abẹ́rẹ́ àjẹsára láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Wọ́n tún máa ń ra ìwé tuntun fáwọn ọmọ tálákà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́. Kíkó àwọn ẹran ọ̀sìn fáwọn àgbẹ̀ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì tún wà lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe, títí kan kíkó nǹkan ìrànwọ́ lọ fáwọn tí àjálù bá.

Àwọn ohun tá a sọ lókè yìí fi hàn pé àwọn èèyàn lẹ́mìí àtiṣe ohun tó dára fún ọmọnìkejì wọn. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn kan tún wà tí wọ́n máa ń hùwà ibi tó kọjá sísọ.

Ìwà Ibi Ń Peléke Sí I

Látìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ti parí, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà àádọ́ta tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ pé wọ́n pa odindi ẹ̀yà run àti pé wọ́n pa ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́ẹ̀kan náà nítorí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Ìwé àtìgbàdégbà kan tó ń jẹ́ American Political Science Review, sọ pé: “Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ti gba ẹ̀mí àwọn ológun tó lé ní mílíọ̀nù méjìlá, wọ́n sì ti pa àwọn tí kì í ṣe ológun tó pọ̀ tó mílíọ̀nù méjìlélógún. Kódà iye yẹn pọ̀ ju gbogbo àwọn tó ti kú sáwọn ogun abẹ́lé àtàwọn ogun láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè láti ọdún 1945.”

Láàárín apá tó kẹ́yìn nínú ọ̀rúndún ogún, ó tó mílíọ̀nù méjì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba èèyàn tí wọ́n pa ní orílẹ̀-èdè Cambodia nítorí ọ̀ràn ìṣèlú. Àwọn èèyàn tó kú nílẹ̀ Rwanda lọ́kùnrin, lóbìnrin, títí kan àwọn ọmọdé nítorí ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà lé ní ogójì ọ̀kẹ́ [800,000]. Àwọn èèyàn tó kú nítorí ìjà ẹ̀sìn àti ìṣèlú ní Bosnia lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba [200,000].

Nígbà tí ọ̀gá àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà ibi tó tún wáyé, ohun tó sọ lọ́dún 2004 ni pé: “Ní orílẹ̀-èdè Ìráàkì, wọ́n pa àwọn tí kì í ṣe ológun nípakúpa láìsí ojú àánú rárá. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n tún mú àwọn tó wá ṣèrànwọ́ àtàwọn oníròyìn, àtàwọn èèyàn míì tí wọ́n kì í ṣe sójà lóǹdè, tí wọ́n sì pa wọ́n ní ipa ìkà. Bákan náà la tún rí i bí wọ́n ṣe hùwà àìdáa tó ń dójú tini sáwọn ọmọ ilẹ̀ Ìráàkì tó wà lẹ́wọ̀n. A rí i bí wọ́n ṣe fipá lé gbogbo àwọn tó ń gbé ní àgbègbè Darfur kúrò nílùú wọn, tí wọ́n wó ilé wọn, tí wọ́n sì tún mọ̀ọ́mọ̀ fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀ láti dá wọn lóró. Ní orílẹ̀-èdè Uganda tó wà níhà àríwá, a rí àwọn ọmọdé tí wọ́n sọ di aláàbọ̀ ara tí wọ́n sì tún fagbára mú wọn láti lọ́wọ́ nínú ìwà ìkà tó burú jáì. A tún rí i bí wọ́n ṣe ti àwọn ọmọdé mọ́ inú ilé kan nílùú Beslan, tí wọ́n sì pa wọ́n nípakúpa.”

Kódà láwọn orílẹ̀-èdè tá a lè sọ pé ó ti gòkè àgbà pàápàá, ńṣe nìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn ẹ̀yà kan túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Independent News sọ lọ́dún 2004 pé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, “àwọn èèyàn tí wọ́n pa tàbí tí wọ́n fìyà jẹ nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹ̀yà mìíràn pọ̀ sí i ní ìlọ́po mọ́kànlá láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá.”

Kí nìdí táwọn èèyàn tó lè ṣe ọ̀pọ̀ ohun tó dára fún ọmọnìkejì wọn ṣe ń hu àwọn ìwà ibi tó burú jáì bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ ìwà ibi yóò kásẹ̀ nílẹ̀ láé? Bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, Bíbélì fún wa láwọn ìdáhùn tó fini lọ́kàn balẹ̀ sáwọn ìbéèrè tó tojú súni wọ̀nyí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Mark Edwards/Still Pictures/Peter Arnold, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́