ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 1/1 ojú ìwé 13-15
  • Wọ́n Múnú Àwọn Òbí Wọn Dùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Múnú Àwọn Òbí Wọn Dùn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Tí Wọ́n Máa Gbà Múnú Àwọn Èèyàn Dùn
  • Iṣẹ́ Ìsìn Wọn Ń Méso Jáde
  • Jíjẹ́rìí Láìjáfara
  • Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà Kí Ẹ Sì Kún fún Ìdùnnú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Wọ́n Rọ Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Pé Kí Wọ́n “Máa Walẹ̀ Jìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ile-ẹkọ Gilead Pé 50 Ọdun Ó Sì Ń Ṣaṣeyọri!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Inú Wọn Dùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 1/1 ojú ìwé 13-15

Wọ́n Múnú Àwọn Òbí Wọn Dùn

“ỌMỌ mi, bí ọkàn-àyà rẹ bá gbọ́n, ọkàn-àyà mi yóò yọ̀, àní tèmi.” (Òwe 23:15) Láìsí àní-àní, inú àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń dùn gan-an nígbà táwọn ọmọ wọn bá ní ọgbọ́n àtọ̀runwá. Lọ́jọ́ Sátidé, September 10, 2005, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mọ́kàndínlọ́gọ́ta [6,859] èèyàn tí wọ́n wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́fà [119] ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead. Ọkàn gbogbo wọn kún fún ayọ̀, àgàgà àwọn tó jẹ́ òbí àwọn mẹ́rìndínlọ́gọ́ta tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà.

Arákùnrin David Walker, tó ti pẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló fi àdúrà àtọkànwá ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni alága, ìyẹn Arákùnrin David Splane tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wá bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà nípa sísọ fáwọn bàbá àtàwọn ìyá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Ó yẹ ká yìn yín gan-an ni. Àwọn ànímọ́ rere tẹ́ ẹ gbìn sọ́kàn àwọn ọmọ yín ló mú kí wọ́n tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì.” Ó ṣeé ṣe káwọn òbí wọ̀nyẹn máa ṣàníyàn nítorí pé àwọn ọmọ wọn ò ní pẹ́ fi wọ́n sílẹ̀ lọ sáwọn ibi jíjìnnà réré tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àmọ́, Arákùnrin Splane fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe ṣàníyàn nípa àwọn ọmọ yín. Jèhófà á bójú tó wọn lọ́nà tó dára gan-an ju bí ẹ ṣe lè bójú tó wọn lọ.” Ó wá sọ pé: “Ẹ ronú nípa ohun rere táwọn ọmọ yín máa gbé ṣe. Àwọn èèyàn tó wà nínú ìpọ́njú yóò tipasẹ̀ wọn rí ojúlówó ìtùnú fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé wọn.”

Ọ̀nà Tí Wọ́n Máa Gbà Múnú Àwọn Èèyàn Dùn

Alága wá pe àwọn olùbánisọ̀rọ̀ mẹ́rin. Arákùnrin Ralph Walls tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni ẹni àkọ́kọ́, ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Ẹ La Ojú Yín Sílẹ̀.” Ó sọ pé kéèyàn jẹ́ afọ́jú nípa tẹ̀mí burú gan-an ju kéèyàn fọ́jú nípa tara. Ìjọ Laodíkíà ọ̀rúndún kìíní fọ́jú nípa tẹ̀mí. Àwọn Kristẹni tójú wọn fọ́ nípa tẹ̀mí nínú ìjọ yẹn rí ìrànlọ́wọ́ gbà lóòótọ́, àmọ́ ohun tó dára jù lọ ni ká dènà irú ìfọ́jú bẹ́ẹ̀ nípa líla ojú wa nípa tẹ̀mí sílẹ̀ kedere. (Ìṣípayá 3:14-18) Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá sọ pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀ dáadáa, ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ọkùnrin tó ń mú ipò iwájú ni kẹ́yin náà máa fi wò wọ́n.” Àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ò gbọ́dọ̀ máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ táwọn ìṣòro bá wà nínú ìjọ. Jésù Kristi Olúwa mọ̀ nípa gbogbo irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. Yóò sì rí i dájú pé àwọn ọ̀ràn náà yanjú lásìkò tó yẹ.

Arákùnrin Samuel Herd tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e, òun ló wá dáhùn ìbéèrè tó sọ pé “Ṣé Ẹ Ti Gbára Dì?” Bí arìnrìn-àjò kan ṣe máa ń kó àwọn aṣọ tó máa lò dání, bẹ́ẹ̀ náà làwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ṣe gbọ́dọ̀ máa fi àwọn àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara wọn láṣọ nígbà gbogbo. Wọ́n gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìyọ́nú bíi ti Jésù. Nígbà tí adẹ́tẹ̀ kan sọ fún un pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́,” Jésù sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” (Máàkù 1:40-42) Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá sọ pé: “Tẹ́ ẹ bá dìídì fẹ́ ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn, ẹ óò rí ọgbọ́n tẹ́ ẹ máa dá sí i.” Ìwé Fílípì 2:3 sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n gbà pé “àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù” wọ́n lọ. Arákùnrin Herd sọ pé: “Kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an ju kéèyàn ní ìmọ̀ lọ. Káwọn tẹ́ ẹ bá ń bá pàdé lóde ẹ̀rí àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin yín nínú ìjọ tó lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ yín, ẹ ní láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.” Ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé táwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà bá lè máa fi ìfẹ́ Kristẹni wọ ara wọn láṣọ ní gbogbo ìgbà, a jẹ́ pé wọ́n ti múra tán láti forí lé ibi tá a yàn wọ́n sí nìyẹn, pẹ̀lú ìdánilójú pé wọ́n á kẹ́sẹ járí.—Kólósè 3:14.

Arákùnrin Mark Noumair tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì fojú àwọn èèyàn sọ́nà nípasẹ̀ àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó sọ pé, “Ṣé Wàá Máa Mọyì Rẹ̀ Títí Lọ?” Mọyì kí ni? Ìmọrírì tá a ní fún oore Jèhófà ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Sáàmù 103:2 sọ pé: “Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi, má sì gbàgbé gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ rẹ̀.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún mánà tó gbé ẹ̀mí wọn ró, wọ́n pè é ní “oúnjẹ játijàti.” (Númérì 21:5) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé bí àkókò ti ń lọ, bí mánà ṣe ṣe pàtàkì tó kò yí padà, àmọ́ wọn ò mọrírì rẹ̀ mọ́. Olùkọ́ náà wá sọ pé: “Tẹ́ ẹ bá gbàgbé àwọn iṣẹ́ Jèhófà, tẹ́ ẹ sì jẹ́ kí iṣẹ́ ìsìn yín nílẹ̀ òkèèrè di nǹkan yẹpẹrẹ, ìyẹn lè nípa lórí ọwọ́ tẹ́ ẹ fi ń mú iṣẹ́ ti Jèhófà gbé lé yín lọ́wọ́.” Sáàmù 103:4 sọ pé Jèhófà “ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ . . . dé ọ ládé.” Àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà yóò rí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run láwọn ìjọ tí wọ́n bá lọ.

Arákùnrin Lawrence Bowen, tóun náà jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, sọ̀rọ̀ lórí kókó tó sọ pé “Ṣé O Fẹ́ Kí Ìbùkún Wá Sórí Rẹ?” Ó sọ pé àwọn ọmọ kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́fà [119] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti gba ẹ̀kọ́ tó jíire kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ní láti rọ̀ mọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì gbájú mọ́ iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́. Ìwé Ìṣípayá 14:1-4 sọ pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni “àwọn tí ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ.” Gbogbo àwọn tó wà nínú agbo yẹn ló fi ìṣòtítọ́ rọ̀ mọ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ láìfi àdánwò èyíkéyìí tí wọ́n bá dojú kọ pè, ọwọ́ wọn sì tẹ ohun tí wọ́n ń wá. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá sọ pé: “Ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, àwa náà lè fi ìṣòtítọ́ rọ̀ mọ́ Jèhófà, ká má sì kúrò nídìí iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́.” Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà yóò rí i pé ìbùkún Jèhófà á wá sórí wọn.—Diutarónómì 28:2.

Iṣẹ́ Ìsìn Wọn Ń Méso Jáde

Gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ làwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù lákòókò tí wọ́n wà nílé ẹ̀kọ́. Ọ̀rọ̀ tí Wallace Liverance, tó máa ń forúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ náà bá wọn sọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fi hàn pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàṣeyọrí. Wọ́n wàásù ìhìn rere náà ní àwọn èdè bíi mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan. Tọkọtaya kan tó wà lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣèkẹ́kọ̀ọ́ náà nígbà méjì, wọ́n ní kí ọkùnrin náà sọ bí mímọ̀ tó mọ̀ nípa Jèhófà ṣe rí lára rẹ̀. Ó ṣí Bíbélì rẹ̀ ó sì ní kí wọ́n ka Jòhánù 17:3. Ọkùnrin náà gbà pé òun ti wà ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè.

Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn arákùnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire, Dominican Republic, àti Ecuador. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti ń retí wọn, wọ́n á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ibi tá a yàn wọ́n sí lè bá wọn lára mu.

Ẹ̀yìn ìyẹn ni Leonard Pearson tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àtàwọn arákùnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, láti orílẹ̀-èdè olómìnira ti Kóńgò, Papua New Guinea, àti Uganda wá jùmọ̀ sọ̀rọ̀. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà níyànjú pé kí wọ́n máa fi gbogbo ọkàn ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà déédéé. Àwọn tọkọtaya míṣọ́nnárì kan tí wọ́n ti lo ọdún mọ́kànlélógún ní orílẹ̀-èdè Kóńgò ti ran ọgọ́ta èèyàn lọ́wọ́ láti di ẹni tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Àwọn tọkọtaya yẹn ń darí ọgbọ̀n ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, méjìlélógún lára àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló sì ń wá sáwọn ìpàdé ìjọ. Irú ọ̀pọ̀ yanturu ìkórè tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àkókò tó dára jù lọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì la wà yìí.

Jíjẹ́rìí Láìjáfara

Arákùnrin Gerrit Lösch tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Sísọ̀rọ̀ Nípa Ọlọ́run àti Jíjẹ́rìí sí Jésù ní Ọjọ́ Olúwa.” Ìgbà mọ́kàndínlógún ni àwọn ọ̀rọ̀ bíi “jẹ́rìí,” “àwọn ẹlẹ́rìí,” àti “jíjẹ́rìí” fara hàn nínú ìwé Ìṣípayá. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ti fi iṣẹ́ tó fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ ṣe hàn wọ́n ní kedere. Ìgbà wo ló yẹ ká jẹ́ irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀? “Ọjọ́ Olúwa” ni. (Ìṣípayá 1:9, 10) Ọjọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914, ó sì ń bá a lọ títí di àkókò tiwa yìí, ó sì tún máa nasẹ̀ dé ọjọ́ iwájú. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ìṣípayá 14:6, 7 sọ, àwọn áńgẹ́lì ń ti iṣẹ́ sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run lẹ́yìn. Ìṣípayá 22:17 fi hàn pé àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró la yan iṣẹ́ dídarí iṣẹ́ ìjẹ́rìí Jésù fún. Àmọ́ gbogbo wa la gbọ́dọ̀ lo àǹfààní yẹn báyìí. Ní ẹsẹ ogún, Jésù sọ pé: “Mo ń bọ̀ kíákíá.” Arákùnrin Lösch wá gba gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ sọ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá ‘gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.’ Jésù ń bọ̀ kíákíá. Ṣé a ti gbára dì?”

Arákùnrin Fred Rusk, tó jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì fún ọdún mọ́kànlá ló kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà pẹ̀lú àdúrà ìdúpẹ́ sí Jèhófà. Àdúrà náà sì wọ gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́kàn ṣinṣin. Bí àṣeyẹ tó kún fún ìdùnnú lọ́jọ́ náà ṣe parí lọ́nà tó gbayì nìyẹn!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 10

Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 25

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 56

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 32.5

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 16.4

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún: 12.1

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́fà [119] Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Helgesen, S.; Daugaard, H.; Pierluissi, A.; Joseph, I.; Racanelli, C. (2) Byrge, T.; Butler, D.; Freedlun, J.; Nuñez, K.; Pavageau, C.; Doumen, T. (3) Camacho, O.; Lindqvist, L.; Broomer, A.; Wessels, E.; Burton, J.; Woodhouse, O.; Doumen, A. (4) Tirion, A.; Connally, L.; Fournier, C.; Gil, A.; Johnsson, K.; Hamilton, L. (5) Byrd, D.; Scribner, I.; Camacho, B.; Laschinski, H.; Hallahan, M.; Libuda, O. (6) Joseph, A.; Lindqvist, M.; Helgesen, C.; Nuñez, D.; Scribner, S.; Fournier, J. (7) Pierluissi, F.; Pavageau, T.; Broomer, C.; Racanelli, P.; Butler, T.; Woodhouse, M.; Libuda, J. (8) Laschinski, M.; Freedlun, S.; Burton, I.; Tirion, M.; Byrd, M.; Byrge, J. (9) Wessels, T.; Hallahan, D.; Connally, S.; Gil, D.; Daugaard, P.; Hamilton, S.; Johnsson, T.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́