ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 3/1 ojú ìwé 28-29
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ìjọ Máa Yin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ọkùnrin àti Obìnrin Ipò Iyì Ni Ọlọ́run Fi Kálukú Wọn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ṣé O Máa Ń Mú Kí Àwọn Ìpàdé Ìjọ Gbéni Ró?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ẹ Máa Fún Àwọn Arábìnrin Níṣìírí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 3/1 ojú ìwé 28-29

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé àwọn obìnrin ní láti “máa dákẹ́ nínú àwọn ìjọ”?

Nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú gbogbo ìjọ àwọn ẹni mímọ́, kí àwọn obìnrin máa dákẹ́ nínú àwọn ìjọ, nítorí a kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀.” (1 Kọ́ríńtì 14:33, 34) Ká tó lè lóye ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, yóò dára ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí ká.

Ní Kọ́ríńtì Kìíní orí Kẹrìnlá, Pọ́ọ̀lù jíròrò àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìpàdé Kristẹni. Ó sọ àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n máa jíròrò nírú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀ àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa darí wọn. (1 Kọ́ríńtì 14:1-6, 26-34) Bákan náà, ó tún tẹnu mọ́ ohun táwọn ìpàdé náà wà fún, ìyẹn sì ni “kí ìjọ lè rí ìgbéniró gbà.”—1 Kọ́ríǹtì 14:4, 5, 12, 26.

Ìgbà mẹ́ta ni ìtọni tí Pọ́ọ̀lù fúnni láti “máa dákẹ́” fara hàn nínú Kọ́ríńtì Kìíní orí Kẹrìnlá. Ní gbogbo ìgbà tó sì fara hàn náà, àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìjọ ló darí ọ̀rọ̀ náà sí. Àmọ́ fún ìdí kan náà ni Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́ ní gbogbo ìgbà tó sọ ọ́, ìdí ọ̀hún sì ni pé “kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́ríńtì 14:40.

Ìgbà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù sọ ọ́, ó ní: “Bí ẹnì kan bá . . . ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì, kí a fi mọ sí méjì tàbí mẹ́ta, ó pọ̀ jù lọ, kí ó sì jẹ́ ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé; kí ẹnì kan sì máa ṣe ìtumọ̀. Ṣùgbọ́n bí kò bá sí olùtumọ̀, kí ó dákẹ́ nínú ìjọ, kí ó sì máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.” (1 Kọ́ríńtì 14:27, 28) Èyí kò túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ mọ́ nínú ìpàdé, ohun tó túmọ̀ sí ni pé àwọn àkókò kan wà tó ní láti máa dákẹ́. Ó ṣe tán, káwọn ará lè gbé ara wọn ró lẹ́nì kìíní kejì ni wọ́n fi ń wá sípàdé, àmọ́ èyí kò ní ṣeé ṣe bí ẹni náà bá ń sọ̀rọ̀ lédè tí kò yé ẹnì kankan.

Nígbà kejì, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, kí àwọn yòókù fi òye mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí a bá fi ìṣípayá fún ẹlòmíràn nígbà tí ó jókòó níbẹ̀, kí ẹni àkọ́kọ́ dákẹ́.” Kì í ṣe pé kí wòlíì àkọ́kọ́ má sọ̀rọ̀ mọ́ rárá nínú ìpàdé lohun tí èyí túmọ̀ sí, àmọ́ pé ó ní láti máa dákẹ́ nígbà míì. Lẹ́yìn náà, ẹni tá a fún ní ìṣípayá lọ́nà ìyanu lè wá bá ìjọ sọ̀rọ̀. Ohun tí ìpàdé náà sì wà fún, ìyẹn láti ‘fún gbogbo èèyàn ní ìṣírí,’ yóò sì wá rí bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 14:26, 29-31.

Nígbà kẹta, àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni nìkan ni Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀. Ó ní: “Kí àwọn obìnrin máa dákẹ́ nínú àwọn ìjọ, nítorí a kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n kí wọ́n wà ní ìtẹríba.” (1 Kọ́ríńtì 14:34) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi pa àṣẹ yìí fáwọn arábìnrin? Nítorí kí nǹkan lè wà létòlétò nínú ìjọ ni. Ó sọ pé: “Bí ó bá wá jẹ́ pé wọ́n fẹ́ kọ́ nǹkan kan, kí wọ́n bi àwọn ọkọ tiwọn léèrè ní ilé, nítorí ohun ìtìjú ni kí obìnrin máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.”—1 Kọ́ríńtì 14:35.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn arábìnrin kan ń ta ko ohun táwọn arákùnrin ń sọ nínú ìjọ. Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ran àwọn arábìnrin lọ́wọ́ láti yẹra fún irú ẹ̀mí màdàrú bẹ́ẹ̀ ó sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ipò wọn nínú ètò ipò orí tí Jèhófà ṣe, ní pàtàkì jù lọ nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá àwọn ọkọ wọn lò. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Yàtọ̀ síyẹn, dídákẹ́ táwọn arábìnrin bá ń dákẹ́ á fi hàn pé wọn ò wá ọ̀nà láti di olùkọ́ nínú ìjọ. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì, ó fi hàn pé kò bójú mu kí obìnrin máa ṣe olùkọ́ nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Èmi kò gba obìnrin láyè láti kọ́ni, tàbí láti lo ọlá àṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe láti wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.”—1 Tímótì 2:12.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn arábìnrin kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ rárá nínú pàdé ìjọ ni? Rárá o. Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn ìgbà míì wà táwọn arábìnrin gbàdúrà tàbí tí wọ́n sàsọtẹ́lẹ̀ nínú ìjọ, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀. Nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fi nǹkan borí wọn láti fi hàn pé àwọn mọ ipò àwọn.a (1 Kọ́ríńtì 11:5) Ìyẹn nìkan kọ́, nígbà ayé Pọ́ọ̀lù àti lóde òní náà, àti arábìnrin àti arákùnrin ni Bíbélì rọ̀ pé kí wọ́n máa polongo ìrètí wọn ní gbangba. (Hébérù 10:23-25) Yàtọ̀ sí pé àwọn arábìnrin ń polongo ìrètí wọn yìí lóde ìwàásù, wọ́n tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífún àwọn mìíràn níṣìírí nípasẹ̀ àwọn ìdáhùn wọn tó mọ́yán lórí nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n láti dáhùn nípàdé. Wọ́n sì tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣe àwọn àṣefihàn nínú ìpàdé tàbí tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.

Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀nà táwọn arábìnrin ń gbà “dákẹ́” ni pé wọn kì í gbìyànjú láti ṣe ohun tó jẹ́ ojúṣe ọkùnrin tàbí kí wọ́n máa kọ́ni nínú ìjọ. Wọn kì í béèrè àwọn ìbéèrè tó lè dá àríyànjiyàn sílẹ̀, èyí tó lè ta ko àṣẹ àwọn tó ń kọ́ni. Bí àwọn arábìnrin ti ń bójú tó ojúṣe tó tọ́ sí wọn nínú ìjọ, wọ́n ń ṣe gudugudu méje láti mú kí àlàáfíà wà, èyí tó ń mú kí “ohun gbogbo [nínú àwọn ìpàdé ìjọ] máa ṣẹlẹ̀ fún ìgbéniró.”—1 Kọ́ríńtì 14:26, 33.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lóde òní, àwọn arábìnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó ohun kan tó yẹ kí arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi nínú ìjọ bójú tó nítorí àwọn ipò kan.—Wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 2002, ojú ìwé 26.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́