Bí Nǹkan Ṣe Rí Fáwọn Tálákà Lónìí
Ọ̀GBẸ́NI kan tó ń jẹ́ Vicentea sábà máa ń ti ọmọlanke tí oríṣiríṣi nǹkan kún inú rẹ̀ kọjá láwọn òpópónà ìlú São Paulo lórílẹ̀-èdè Brazil. Páálí, agolo, àti ike táwọn èèyàn kó dà nù ló máa ń ṣà kiri. Nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú, Vicente á to páálí sábẹ́ ọmọlanke rẹ̀, á sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀. Ó dà bíi pé ariwo àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àtàwọn bọ́ọ̀sì tó ń lọ tó ń bọ̀ lójú títì kì í dí i lọ́wọ́ níbi tó ń sùn sí lálaalẹ́ yìí. Ó ti níṣẹ́ lọ́wọ́ rí, bẹ́ẹ̀ ló sì ní ilé àti ìdílé tẹ́lẹ̀, àmọ́ gbogbo ìwọ̀nyẹn kò sí mọ́. Eku káká ló fi ń rówó jẹun báyìí látinú iṣẹ́ tó ń ṣe kiri òpópónà.
Ó ṣeni láàánú pé káàkiri ayé, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló wà nípò òṣì bíi ti Vicente yìí. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ọ̀pọ̀ kò rí ọgbọ́n mìíràn ta sí i ju kí wọ́n lọ máa gbé lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì tàbí láwọn ibi táwọn akúṣẹ̀ẹ́ pọ̀ sí. Ìgbà gbogbo lèèyàn sì máa ń rí àwọn tó ń tọrọ báárà. Báwọn arọ àtàwọn afọ́jú ṣe wà lára wọn làwọn obìnrin tó ń fọ́mọ lọ́mú náà wà lára wọn. Bẹ́ẹ̀ lèèyàn á tún rí àwọn ọmọdé tó máa ń sáré gba àárín àwọn ọkọ̀ láti ta ìpápánu kí wọ́n lè rówó díẹ̀ mú lọ sílé.
Ó ṣòro láti ṣàlàyé ìdí tí irú ipò òṣì báyìí fi wà. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ The Economist sọ pé: “Kò tíì sígbà kan ti ọmọ aráyé ní ọrọ̀, ìmọ̀ ìṣègùn, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó fakíki, àti ọpọlọ pípé tí wọ́n nílò láti rẹ́yìn ìṣẹ́ àti òṣì tó ti àkókò yìí.” Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ti jàǹfààní látinú ìmọ̀ àti ọgbọ́n yìí. Ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ńṣe ni ojú pópó àwọn ìlú ńlá máa ń kún fáwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun tó ń dán gbinrin. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde máa ń kúnnú àwọn ṣọ́ọ̀bù ìtajà fọ́fọ́, tó sì jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn máa ń rọ́ wá nígbà gbogbo láti rà wọ́n. Lórílẹ̀-èdè Brazil, àwọn ibi ìtajà méjì kan polówó ọjà wọn lọ́nà àkànṣe. Ṣíṣí sílẹ̀ làwọn ṣọ́ọ̀bù ibi ìtajà náà wà lóru ọjọ́ kẹtàlélógún mọ́jú ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù December ọdún 2004. Ọ̀kan lára àwọn ibi ìtajà náà tiẹ̀ háyà àwọn oníjó sáńbà kí wọ́n máa dá àwọn tó bá wá rajà lára yá. Àwọn tó sì wá rajà nítorí ohun tí wọ́n ṣe yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì mílíọ̀nù èèyàn!
Síbẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni kò rí àǹfààní kankan jẹ látinú owó táwọn ọlọ́rọ̀ ní. Ìyàtọ̀ ńláǹlà tó sì wà láàárín àwọn olówó àtàwọn tálákà ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé ó yẹ kí wọ́n tètè wá nǹkan ṣe sí ìṣẹ́ àti òṣì. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Brazil kan tó ń jẹ́ Veja sọ pé: “Lọ́dún yìí [2005], mímú ìṣẹ́ àti òṣì kúrò ló gbọ́dọ̀ jẹ́ olórí ohun táwọn aṣáájú ayé máa jíròrò rẹ̀.” Ìwé ìròyìn yìí tún sọ̀rọ̀ nípa ètò kan tó ń jẹ́ Ètò Marshall tí wọ́n ń gbèrò láti gbé kalẹ̀ lákọ̀tun láti fi ran àwọn orílẹ̀-èdè tó kúṣẹ̀ẹ́ jù lọ lọ́wọ́, pàápàá ní ilẹ̀ Áfíríkà.b Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn èròǹgbà báwọ̀nyí máa ń jẹ́ kó dà bíi pé ìtẹ̀síwájú wà, ìwé ìròyìn yẹn sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìdí ló lè mú kéèyàn máa ṣiyèméjì pé bóyá làwọn èròǹgbà náà yóò yọrí sí rere. Ohun tó sì máa ń mú kí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́ tìkọ̀ láti gbé owó sílẹ̀ fún irú àwọn èròǹgbà bẹ́ẹ̀ ni pé eku káká làwọn owó náà fi ń dé ọwọ́ àwọn tí wọ́n dìídì fẹ́ fi ràn lọ́wọ́.” Ó dunni pé nítorí ìkówójẹ àti nítorí onírúurú fọ́ọ̀mù táwọn èèyàn ní láti kọ nǹkan sí, ọ̀pọ̀ lára owó táwọn ìjọba, àwọn àjọ ńláńlá, àtàwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn ń gbé sílẹ̀ ni kì í dọ́wọ́ àwọn tó nílò rẹ̀.
Jésù mọ̀ pé ìṣòro ipò òṣì kì í ṣe ìṣòro tí yóò kásẹ̀ nílẹ̀ bọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo.” (Mátíù 26:11) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé títí láé ni ipò òṣì yóò máa wà lórí ilẹ̀ ayé ni? Ṣé kò sí ohunkóhun tá a lè ṣe láti mú ìṣòro yìí kúrò ni? Kí làwọn Kristẹni lè ṣe láti ran àwọn tó jẹ́ tálákà lọ́wọ́?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
b Ètò Marshall ni ètò kan tí ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ láti fi ran ilẹ̀ Yúróòpù lọ́wọ́ kí ètò ọrọ̀ ajé wọn lè padà bọ̀ sípò lẹ́yìn ogun àgbáyé kejì.