Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
OHUN tó ṣẹlẹ̀ sí ìran èèyàn níbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mà ga o! Áńgẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí sì ti Éfà obìnrin àkọ́kọ́ láti jẹ èso tí Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n má jẹ. Ohun tó sọ fún Éfà, èyí tó kan ọkọ rẹ̀ ni pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:1-5) Áńgẹ́lì yìí ló di ẹni tá a mọ̀ sí Èṣù àti Sátánì.—Ìṣípayá 12:9.
Ǹjẹ́ Éfà fetí sí ọ̀rọ̀ Sátánì? Bíbélì sọ fún wa pé “Obìnrin náà rí i pé igi náà dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni, bẹ́ẹ̀ ni, igi náà fani lọ́kàn mọ́ra láti wò. Nítorí náà, ó mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Bí Ádámù àti Éfà ṣe bá Sátánì lọ́wọ́ nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ nìyẹn. Ohun tí wọ́n ṣe yìí sì jẹ́ kí àwọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn pàdánù Párádísè. Àwọn ọmọ tí wọn ì bá bí gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé tí yóò máa wà láàyè títí láé wá di ẹni tó jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Róòmù 5:12.
Kí ni Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run wá ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí? Ó pinnu láti ṣètò ọ̀nà táwọn èèyàn á fi lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Róòmù 5:8) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà Ọlọ́run tún ṣètò pé kí ìjọba kan wà tí yóò yanjú ìṣòro yìí. Ìjọba yìí ni Bíbélì pè ní “Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 21:31) Ìjọba yìí máa wà lábẹ́ àkóso Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, ìdí pàtàkì kan sì wà tí Ọlọ́run fi gbé e kalẹ̀.
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbé Ìjọba yìí kalẹ̀? Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó mú kí ìjọba yìí dára gan-an, báwo sì ni ìwọ̀nyí ṣe rí tá a bá fi wé ìjọba èèyàn? Ìgbà wo ni Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso? Gbogbo ìbéèrè yìí ni àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn.