Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Lè Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Jálẹ̀ Ọdún?
“Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.”—Lúùkù 2:14.
ÀRÀÁDỌ́TA Ọ̀KẸ́ èèyàn ló mọ ọ̀rọ̀ yìí táwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ nígbà tí wọ́n ń kéde ìbí Jésù fáwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn lóru. Tó bá ti ń tó ìgbà táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sọ pé wọ́n bí Jésù, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó pera wọn ní Kristẹni máa ń gbìyànjú gidigidi láti hùwà tó dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Wọ́n máa ń fẹ́ ṣe ohun táwọn áńgẹ́lì náà mẹ́nu kàn nínú ìkéde wọn, ìyẹn ni pé wọ́n máa ń fẹ́ láti láyọ̀, wọ́n máa ń fẹ́ fẹ̀mí àlàáfíà bá àwọn èèyàn lò, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti ṣe ọmọnìkejì wọn lóore.
Kódà, àwọn tí wọn ò ṣe Kérésìmesì gẹ́gẹ́ bí ayẹyẹ ìsìn pàápàá nífẹ̀ẹ́ sí irú ẹ̀mí rere táwọn èèyàn máa ń fẹ́ fi hàn nígbà Kérésì. Àwọn náà mọyì ìwà rere tó dà bíi pé ayẹyẹ Kérésì máa ń mú káwọn èèyàn hù lákòókò tí wọ́n bá ń ṣe é. Àwọn kan máa ń rí ìsinmi gbà níbi iṣẹ́ wọn tàbí ní iléèwé lákòókò Kérésì, èyí sì máa ń jẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti fún ara ní ìsinmi, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fara mọ́ ìdílé wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn, tàbí kí wọ́n sáà gbádùn ara wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn tiẹ̀ sọ pé Jésù Kristi làwọn ń fi ayẹyẹ náà bọlá fún ní pàtàkì.
Ohun tó wù kí wọ́n máa sọ pé ó jẹ́ ìdí tí Kérésì fi ṣe pàtàkì, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló gbà pé rere tí Kérésì ń mú káwọn èèyàn ṣe kì í wà pẹ́. Àwọn èèyàn kì í pẹ́ padà sí ìwà tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀. Àpilẹ̀kọ kan tí ó ní àkọlé náà, Ẹ̀mí Àlàáfíà Nígbà Kérésì, tí ilé ìfowópamọ́ Royal Bank of Canada gbé jáde, sọ pé: “Ọ̀sẹ̀ mélòó kan làwọn tí wọ́n pera wọn ní Kristẹni fi máa ń hùwà rere tó yẹ kí Kristẹni máa hù, ìwọ̀nba ọ̀sẹ̀ yẹn náà ni wọ́n sì fi ń ṣe inú rere sí ọmọnìkejì wọn. Lẹ́yìn Ọdún Tuntun, ńṣe ni wọ́n tún máa ń padà sí ìwà ‘bó-o-bá-a-o-pa-á, bó-ò-ba-o-bù-ú-lẹ́sẹ̀’ tí wọ́n ti ń hù tẹ́lẹ̀, tí àánú ọmọnìkejì wọn tójú ń pọ́n kì í sì í ṣe wọ́n.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé ohun tó “burú” nínú ẹ̀mí àlàáfíà tí wọ́n láwọn ní àti ohun rere tí wọ́n ní Kérésì máa ń mú àwọn ṣe ni pé wọn kì í ṣe rere ọ̀hún “jálẹ̀ ọdún,” àkókò Kérésì nìkan ló máa ń mọ.
Yálà o fara mọ́ àlàyé yìí tàbí o ò fara mọ́ ọn, ó dájú pé ó mú káwọn ìbéèrè pàtàkì kan wá síni lọ́kàn. Àwọn ìbéèrè náà ni pé: Ǹjẹ́ ìgbà kan tiẹ̀ máa wà táwọn èèyàn máa jẹ́ ọ̀làwọ́ àti onínú rere síra wọn títí láé? Ǹjẹ́ ìrètí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà pé ìkéde àlàáfíà táwọn áńgẹ́lì ṣe lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù á nímùúṣẹ? Àbí àlá tí ò lè ṣẹ ni pé àlàáfíà máa wà?