Ọkùnrin àti Obìnrin Ọlọ́run Dá Wọn Láti Ṣàlékún Ara Wọn
ÀTÌGBÀ tí Ọlọ́run ti dá ọkùnrin àtobìnrin ló ti máa ń wù wọ́n pé kí wọ́n jọ wà pa pọ̀. Ìdí tó sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé Ọlọ́run ló dá ìfẹ́ yẹn mọ́ wọn. Jèhófà wò ó pé kò dáa kí Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, máa gbé lóun nìkan. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe “olùrànlọ́wọ́ kan [fún ọkùnrin náà], gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.”
Bí Jèhófà ṣe ṣe é ni pé ó fi oorun àsùnwọra kun Ádámù, lẹ́yìn ìyẹn ó yọ egungun ìhà rẹ̀ kan ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí fi egungun ìhà . . . náà mọ obìnrin, ó sì mú un wá fún ọkùnrin náà.” Nígbà tí Ádámù rí òrékelẹ́wà tí Jèhófà dá fún un yìí, inú rẹ̀ dùn gan-an débi pé, ó ní: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi.” Ànímọ́ obìnrin tí Ọlọ́run dá mọ́ Éfà, ẹni pípé, mú kó jẹ́ ẹni tí Ádámù á máa nífẹ̀ẹ́. Iyì ọkùnrin tí Ọlọ́run sì gbé wọ Ádámù, ẹni pípé, mú kó jẹ́ ẹni tí Éfà á máa bọ̀wọ̀ fún. Ńṣe ni Ọlọ́run dá àwọn méjèèjì láti ṣàlékún ara wọn. Bíbélì sọ pé: “Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24.
Àmọ́ lóde òní, ọ̀pọ̀ ìdílé ló ti tú ká, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló máa ń han ara wọn léèmọ̀ tí àwọn míì sì máa ń rọ̀jò kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sórí ara wọn tàbí kí wọ́n jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Ẹ̀mí ìbáradíje tó wà láàárín ọkùnrin àtobìnrin wà lára àwọn ohun tó ń dájà sílẹ̀ láàárín wọn. Àmọ́ kì í ṣe bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rí nìyẹn nígbà tó dá wọn níbẹ̀rẹ̀. Nígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin, ojúṣe pàtàkì kan wà tó yàn fún un. Ojúṣe tó sì yàn fún obìnrin jẹ́ èyí tó yàtọ̀ tó sì níyì, ìyẹn ni pé kó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọkọ rẹ̀. Ńṣe ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn méjèèjì mọwọ́ ara wọn. Látìgbà téèyàn ti wà lórí ilẹ̀ ayé làwọn ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ti ń ṣe ojúṣe tí Jèhófà fún kálukú wọn, ìyẹn sì ti jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ní ayọ̀ tí inú wọn sì ń dùn pé àwọn ń ṣe ohun tó yẹ káwọn ṣe. Àmọ́ ojúṣe wo nìyẹn, báwo sì ni ọkùnrin àtobìnrin ṣe lè ṣe é?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ọlọ́run fi ọkùnrin àtobìnrin sí ipò iyì nínú ètò tó ṣe