ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 5/1 ojú ìwé 3-4
  • Ìbànújẹ́ Tí Kì Í Tán Bọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbànújẹ́ Tí Kì Í Tán Bọ̀rọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tínú Wọn Fi Máa Ń Bàjẹ́ Tó Bẹ́ẹ̀?
  • Ìrànwọ́ Láti Ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run Tí Ń Pèsè Ìfaradà àti Ìtùnú”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Báwo Ni Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?
    Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ̀yin Èwe Ẹ Lè Múnú Àwọn Òbí Yín Dùn Tàbí Kẹ́ Ẹ Bà Wọ́n Nínú Jẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 5/1 ojú ìwé 3-4

Ìbànújẹ́ Tí Kì Í Tán Bọ̀rọ̀

LẸ́NU àìpẹ́ yìí, ẹnì kan tó ń ṣèwádìí fẹ́ mọ bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn lẹ́yìn ọdún bíi mélòó kan tí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ àwọn èèyàn wọn tó kú. Ó fi ìwé tá a fi ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn èèyàn ránṣẹ́ sáwọn òbí bíi mélòó kan táwọn ọmọ wọn kú lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn. Kì í ṣe gbogbo òbí tó fìwé náà ránṣẹ́ sí ló fèsì padà. Bàbá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vladimir, tí ọmọ rẹ̀ kú lọ́dún márùn-ún sẹ́yìn, ṣàlàyé pé ó ṣì máa ń ṣòro fóun gan-an láti sọ̀rọ̀ nípa ọmọ òun tó kú.a

Ìbànújẹ́ tí kì í tán bọ̀rọ̀ yẹn wọ́pọ̀ láàárín àwọn òbí tọ́mọ wọn kú. Ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni ọmọ William, tó jẹ́ ọmọkùnrin, tó sì ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún kú sómi. William wá kọ̀wé pé, “Ìbànújẹ́ yẹn kò kúrò lọ́kàn mi, kò sì lè kúrò títí mo fi máa kú.” Lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí àìsàn òjijì pa ọmọ Lucy, tó jẹ́ ọmọkùnrin, ó kọ̀wé pé: “Lọ́jọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn tó ṣẹlẹ̀, mò ń sọ lọ́kàn mi pé ‘rárá o, kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀.’ Ńṣe ló ń ṣe mi bíi pé àlá burúkú kan ni mò ń lá lọ́wọ́, pé mi ò ní pẹ́ jí lójú oorun. Ìgbà tó yá ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ náà, pé ọmọ mi ò ní padà wálé mọ́. Ọdún kárùn-ún tí ọmọ mi ti kú rèé, àmọ́ ikú rẹ̀ ṣì máa ń pa mí lẹ́kún nígbà míì tí mo bá dá nìkan wà.”

Kí nìdí táwọn òbí tọ́mọ wọ́n kú bíi ti Vladimir, William, àti Lucy, fi máa ń ní ìbànújẹ́ tí kì í tán bọ̀rọ̀? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tó máa ń fà á.

Kí Nìdí Tínú Wọn Fi Máa Ń Bàjẹ́ Tó Bẹ́ẹ̀?

Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ọmọ tuntun nínú ìdílé kan, inú àwọn òbí máa ń dùn gan-an, wọ́n sì máa ń ní ayọ̀ téèyàn ò lè rí níbòmíràn. Bí wọ́n ṣe ń di ọwọ́ ọmọ wọn jòjòló mú, tí wọ́n ń wo bó ṣe ń sùn, tàbí tí wọ́n ń wò ó bó ṣe ń rẹ́rìn-ín músẹ́, máa ń fún wọn láyọ̀ àti ìdùnnú ńlá. Àwọn òbí rere máa ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ wọn. Wọ́n máa ń kọ́ wọn láti máa hùwà rere kí wọ́n sì jẹ́ ọmọlúàbí. (1 Tẹsalóníkà 2:7, 11) Báwọn ọmọ bá ṣe ń dàgbà tí wọ́n sì ń fi gbogbo nǹkan tí wọ́n ń kọ́ wọn yìí sílò, orí àwọn òbí á máa wú, wọ́n á sì máa retí pé àwọn ọmọ náà yóò di èèyàn àtàtà lọ́jọ́ kan.

Àwọn òbí rere máa ń ṣiṣẹ́ kára láti pèsè ohun táwọn ọmọ wọn nílò fún wọn. Wọ́n lè máa fi owó pa mọ́ fún wọn tàbí kí wọ́n máa kó àwọn ohun ìní jọ kí wọ́n lè fi ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìdílé tiwọn lọ́jọ́ iwájú. (2 Kọ́ríńtì 12:14) Iṣẹ́ ńlá tí wọ́n ń ṣe yìí, tí wọ́n ń náwó-nára, tí wọ́n tún ń ná àkókò, fi ohun kan hàn kedere, ìyẹn ni pé àwọn òbí fẹ́ káwọn ọmọ wọn wà láàyè ni, wọn ò fẹ́ kí wọ́n kú. Nígbà tí ọmọ kan bá kú, gbogbo iṣẹ́ táwọn òbí rẹ̀ ti ṣe láti tọ́ ọmọ náà forí ṣánpọ́n nìyẹn, ìrètí wọn sì wọmi. Ikú ti fòpin sí ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí òbí náà ní sọ́mọ rẹ̀. Ibi tí ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin yìí wà lọ́kàn wọn tẹ́lẹ̀ á wá ṣófo. Àwọn òbí yìí yóò wá ní ìbànújẹ́ ọkàn tí kì í tán bọ̀rọ̀.

Bíbélì pàápàá sọ pé àwọn tí ọmọ wọn kú máa ń ní ìbànújẹ́ tó pọ̀ gan-an tí kì í sì í tán bọ̀rọ̀. Nígbà tí Bíbélì ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò tí Jékọ́bù gbọ́ pé Jósẹ́fù ọmọ òun ti kú, ó ní: “Jékọ́bù gbọn aṣọ àlàbora rẹ̀ ya, ó sì sán aṣọ àpò ìdọ̀họ mọ́ ìgbáròkó rẹ̀, ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣọ̀fọ̀ ọmọkùnrin rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sì ń dìde láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n ó ń kọ̀ láti gba ìtùnú, ó wí pé: ‘Nítorí èmi yóò máa bá a lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọkùnrin mi wọnú Ṣìọ́ọ̀lù [tàbí sàréè]!’” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Jékọ́bù ṣì ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ tó rò pé ó ti kú yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 37:34, 35; 42:36-38) Àpẹẹrẹ mìíràn tó tún wà nínú Bíbélì ni ti obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Náómì tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì kú. Inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an débi pé ó fẹ́ yí orúkọ rẹ̀ padà kúrò ní Náómì, tó túmọ̀ sí adùn, kó sì máa jẹ́ Márà, tó túmọ̀ sí ìkorò.—Rúùtù 1:3-5, 20, 21.

Àmọ́, Bíbélì kò fi ọ̀rọ̀ mọ sórí ìbànújẹ́ táwọn òbí máa ń ní nígbà tọ́mọ wọn bá kú. Ó tún sọ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń fún àwọn tó ní ìbànújẹ́ ọkàn lókun. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a ó jíròrò díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run máa ń gbà tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́