ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 5/1 ojú ìwé 8-13
  • Ìṣúra Tá À Ń wá Kiri Mú Èrè Ayérayé Wá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣúra Tá À Ń wá Kiri Mú Èrè Ayérayé Wá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Wá Ìṣúra Náà Kiri
  • Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ Ọwọ́ Mi Ń Tẹ Ohun Tí Mò Ń Lé
  • Ara Mi Ti Wà Lọ́nà Láti Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìwàásù Alákòókò-Kíkún
  • Àtakò Kò Dí Wa Lọ́wọ́
  • Ọjọ́ Tí Mi Ò Lè Gbàgbé
  • Àwa Méjèèjì Jọ Lọ Sílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
  • Bá A Ṣe Wá Ìṣúra Lórílẹ̀-Èdè Chile
  • A Rí Àwọn Ìṣúra Nínú “Erùpẹ̀”
  • A Tún Rí Ọ̀pọ̀ Ìṣúra Sí I ní “Etíkun Fífẹ̀”
  • Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Fífi Tayọ̀tayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ìdarí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Pípa Gbogbo Àfiyèsí Pọ̀ Sórí Ẹ̀bùn náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 5/1 ojú ìwé 8-13

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ìṣúra Tá À Ń wá Kiri Mú Èrè Ayérayé Wá

Gẹ́gẹ́ bí Dorothea Smith àti Dora Ward ṣe sọ ọ́

Irú ìṣúra wo là ń wá kiri ná? Ọ̀dọ́mọbìnrin méjì ni wá, ó sì wù wá gan-an láti ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ nígbà tó sọ pé: ‘Ẹ lọ kí ẹ máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.’ (Mátíù 28:19) Ẹ jẹ́ ká ṣàlàyé ọ̀nà tí ohun tá à ń wá kiri yìí gbà yọrí sí ìbùkún ayérayé.

Ọ̀RỌ̀ DOROTHEA: Ọdún 1915 ni wọ́n bí mi, ìyẹn kété lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ̀rẹ̀. Èmi ni ọmọ kẹta tí wọ́n bí nínú ìdílé wa. Ìtòsí ìlú Howell, tó wà ní ìpínlẹ̀ Michigan, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà là ń gbé. Bàbá mi kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn, àmọ́ màmá mi jẹ́ ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run gan-an. Ó gbìyànjú láti kọ́ wa pé ká máa tẹ̀ lé Òfin Mẹ́wàá, àmọ́ ó máa ń dùn ún pé èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Willis àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Viola kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kankan.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìlá, màmá mi sọ pé kí n ṣèrìbọmi nínú Ìjọ Pirẹsibitéríà. Mo rántí ọjọ́ tí mo ṣèrìbọmi yẹn dáadáa. Èmi àtàwọn ọmọ ọwọ́ méjì tí ìyá wọn gbé lọ́wọ́ la jọ ṣèrìbọmi lọ́jọ́ yẹn. Ó tì mí lójú gan-an pé èmi àtàwọn ọmọ ọwọ́ la jọ ṣèrìbọmi. Àlùfáà náà wọ́n omi díẹ̀ sí mi lórí, ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ kan tí kò yé mi. Ká sòótọ́, báwọn ọmọ ọwọ́ wọ̀nyẹn ò ṣe mọ ohunkóhun nípa ìrìbọmi yẹn lèmi náà ò ṣe fì bẹ́ẹ̀ lóye rẹ̀!

Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1932, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan yà wọ ọ̀nà tó wá síwájú ilé wa, màmá mi sì ṣílẹ̀kùn fáwọn tó wá sẹ́nu ọ̀nà ilé wa. Bó ṣe rí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin méjì tí wọ́n ń pín àwọn ìwé ìsìn nìyẹn. Ọ̀kan lára wọn sọ pé Albert Schroeder lorúkọ òun. Ó fi àwọn ìwé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde han màmá mi. Màmá mi sì gba àwọn ìwé náà. Àwọn ìwé wọ̀nyẹn ran màmá mi lọ́wọ́ láti fara mọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

A Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Wá Ìṣúra Náà Kiri

Nígbà tó yá, mo lọ ń gbé lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó wà nílùú Detroit. Ibẹ̀ ni mo ti rí obìnrin àgbàlagbà kan tó wá ń kọ́ ẹ̀gbọ́n mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ máa ń sọ mú mi rántí ètò kan tí mo máa ń tẹ́tí sí lórí rédíò nígbà tí mo ṣì wá nílé lọ́dọ̀ màmá mi. Ètò yẹn jẹ́ ọ̀rọ̀ tó máa ń dá lórí kókó kan látinú Bíbélì, Arákùnrin J. F. Rutherford tó ń darí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lákòókò yẹn ló sì máa ń sọ ọ̀rọ̀ náà fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Nígbà tó di ọdún 1937, a bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́kọ́ wà nílùú Detroit. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni mo ṣèrìbọmi.

Níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940, wọ́n kéde pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dá ilé ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀, èyí tí wọ́n pè ní Gílíádì, nílùú South Lansing ní ìpínlẹ̀ New York. Ibẹ̀ ni wọ́n ti fẹ́ máa dá àwọn tó fẹ́ di míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí mo gbọ́ pé wọ́n á ní káwọn kan lára àwọn tó bá kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ náà lọ sìn lókè òkun, mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘màá fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ yẹn!’ Bí mo ṣe fi lílọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣe ohun tí mò ń lé nìyẹn. Àǹfààní ńlá gbáà ló máa jẹ́ láti lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn láti wá “àwọn ìṣúra,” ìyẹn àwọn èèyàn tó fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Kristi Jésù!—Hágáì 2:6, 7.

Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ Ọwọ́ Mi Ń Tẹ Ohun Tí Mò Ń Lé

Lóṣù April ọdún 1942, mo kọ̀wé fiṣẹ́ tí mò ń ṣe sílẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tàbí ajíhìnrere alákòókò-kíkún, nílùú Findlay, ní ìpínlẹ̀ Ohio. Èmi àtàwọn arábìnrin márùn-ún mìíràn la jọ wà níbẹ̀. Kò sí ìjọ kankan tá a ti lè máa lọ sípàdé, àmọ́ a máa ń fún ara wa níṣìírí nípa jíjùmọ̀ ka àwọn àpilẹ̀kọ látinú àwọn ìwé táwa Kristẹni ń tẹ̀ jáde. Ìwé márùndínlọ́gọ́rùn-ún ni mo fi sóde lóṣù àkọ́kọ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà! Ní nǹkan bí ọdún kan àtààbọ̀ lẹ́yìn ìyẹn, mo gba lẹ́tà tí wọ́n fi ní kí n lọ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Chambersburg, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Ibẹ̀ ni mo ti dara pọ̀ mọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà márùn-ún mìíràn, ọ̀kan lára wọn ni Arábìnrin Dora Ward tó wá láti ìpínlẹ̀ lowa. Èmi àti Dora sì dẹni tá a wá jọ ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pa pọ̀. Ọdún kan náà làwa méjèèjì ṣèrìbọmi, àwa méjèèjì ló sì wù láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ká sì lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè.

Ọjọ́ pàtàkì náà dé níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1944! Wọ́n pe àwa méjèèjì pé ká wá sí kíláàsì kẹrin ti Gílíádì. A sì wọlé lóṣù August ọdún yẹn. Àmọ́ kí n tó máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ, ẹ jẹ́ kí Dora sọ fún un yín bóun ṣe wá dẹnì kejì mi tá a ti jọ ń wá ìṣúra bọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

Ara Mi Ti Wà Lọ́nà Láti Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìwàásù Alákòókò-Kíkún

Ọ̀RỌ̀ DORA: Gbogbo ọkàn ni màmá mi fi ń gbàdúrà pé kóun lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́jọ́ Sunday kan báyìí, mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tá a gbọ́ àsọyé kan tí J. F. Rutherford sọ lórí rédíò. Lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ náà tán, màmá mi kígbe pé, “Òtítọ́ ni èyí!” Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde. Lọ́dún 1935, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, mo lọ síbì kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti sọ̀rọ̀ lórí ìrìbọmi, ó sì wù mí látọkànwá pé kémi náà ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn ni mo ṣèrìbọmi. Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tí mo ṣe yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an láwọn ọdún díẹ̀ tó kù tí mo máa lò nílé ìwé, ó jẹ́ kí ọkàn mi lè wà lórí àwọn ohun tí mò ń lé. Ńṣe ló ń wù mi kí n tètè parí ẹ̀kọ́ mi nílé ìwé kí n lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Lákòókò yẹn, àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tá à ń dara pọ̀ mọ́ máa ń ṣèpàdé nílùú Fort Dodge, ní ìpínlẹ̀ Iowa. Lílọ sípàdé Kristẹni gba kéèyàn sapá gan-an lákòókò yẹn. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, wọn kì í kọ ìbéèrè táwọn ará máa dáhùn sínú àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ tá a máa kà nípàdé. Ńṣe ni wọ́n máa ń sọ pé ká fún arákùnrin tó ń darí Ilé Ìṣọ́ ní ìbéèrè tá a ti kọ wá látilé. Láwọn alẹ́ ọjọ́ Monday, èmi àti màmá mi á múra Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀, a ó sì wá ìbéèrè fún ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, a ó wá mú ìbéèrè náà fún arákùnrin tó ń dárí Ilé Ìṣọ́, kó lè mú èyí tó bá wù ú lára wọn.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìjọ wa máa ń gba alábòójútó arìnrìn-àjò lálejò. Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà ni Arákùnrin John Booth, tó fi bí wọ́n ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé hàn mí nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, mo béèrè bí mo ṣe máa kọ ọ̀rọ̀ sínú ìwé tí wọ́n fi ń wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Mi ò mọ̀ pé èmi pẹ̀lú rẹ̀ tún máa pàdé nígbà tó bá yá tá a ó sì máa ṣọ̀rẹ́ títí lọ!

Nígbà tí mo di aṣáájú-ọ̀nà, èmi pẹ̀lú Arábìnrin Dorothy Aronson la jọ máa ń ṣiṣẹ́, ajíhìnrere tó máa ń wàásù gan-an ni arábìnrin yìí, nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló sì fi jù mí lọ. Àwa méjèèjì la jọ máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ títí dìgbà tí wọ́n pè é sí kíláàsì àkọ́kọ́ ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1943. Lẹ́yìn ìyẹn, èmi nìkan wá ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ.

Àtakò Kò Dí Wa Lọ́wọ́

Nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wa rárá láwọn ọdún 1940 nítorí ọ̀ràn ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tí Ogun Àgbáyé Kejì dá sílẹ̀. Nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń ju àwọn ẹyin tó ti bà jẹ́ àtàwọn tòmátì tó ti pọ́n lù wá, kódà wọ́n máa ń ju òkò nígbà mìíràn! Ìgbà tá à ń pín àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lẹ́gbẹ́ ọ̀nà ni ìdánwò náà wá lágbára gan-an. Àwọn ọlọ́pàá táwọn onísìn máa ń sún láti ṣàtakò wa á wá bá wa, wọ́n á sì halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa mú wa tí wọ́n bá tún rí wa tá à ń wàásù fáwọn èèyàn.

Àmọ́, a ò jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, bí wọ́n ṣe mú wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá nìyẹn tí wọ́n lọ fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò. Nígbà tí wọ́n ní ká máa lọ, a padà sí ojú pópó kan náà yẹn a sì tún ń pín àwọn ìwé ìròyìn náà fáwọn èèyàn. Àwọn alàgbà kan gbà wá níyànjú pé ká máa lo Aísáyà 61:1, 2 láti gba ara wa sílẹ̀. Nígbà kan tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ ọlọ́pàá wá bá mi, mo sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. Ó yà mí lẹ́nu pé ńṣe ló yíjú padà tó sì ń lọ! Lójú mi, àwọn áńgẹ́lì ló ń dáàbò bò wá.

Ọjọ́ Tí Mi Ò Lè Gbàgbé

Lọ́dún 1941, inú mi dùn gan-an pé mo lè lọ sí àpéjọ kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fún odindi ọjọ́ mẹ́jọ gbáko nílùú St. Louis, ní ìpínlẹ̀ Missouri. Nígbà tí àpéjọ yẹn ń lọ lọ́wọ́, Arákùnrin Rutherford ni kí gbogbo ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùn-ún sí méjìdínlógún kóra jọ síbi ọwọ́ iwájú pápá ìṣeré náà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọdé sì kora jọ síbẹ̀. Arákùnrin Rutherford wá fi áńkáṣíìfù rẹ̀ juwọ́ sí wa láti kí wa káàbọ̀. Àwa náà sì juwọ́ sí i padà. Lẹ́yìn tó sọ̀rọ̀ fún odindi wákàtí kan, ó wá sọ pé: “Ẹyìn ọmọdé tẹ́ ẹ ti gbà láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tẹ́ ẹ sì ti gbà láti fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù, tẹ́ ẹ sì múra tán láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti Ọba rẹ̀, ẹ jọ̀wọ́ ẹ dìde dúró.” Bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ọmọdé tó wà níbẹ̀ ṣe dìde dúró lẹ́ẹ̀kan náà nìyẹn, èmi náà sì wà lára wọn! Arákùnrin náà wá fi kún un pé: “Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ máa ṣe ohun tẹ́ ẹ bá lè ṣe láti sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìbùkún tó máa mú wá fáwọn èèyàn, ẹ jọ̀wọ́ ẹ sọ pé, A ó ṣe bẹ́ẹ̀.” Gbogbo wa sì sọ pé a ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí àtẹ́wọ́ ṣe sọ nìyẹn.

Ó wá kéde pé a ti mú ìwé tó ń jẹ́ Childrena jáde, àwa ọmọdé sì tò síwájú pèpéle, níbi ti Arákùnrin Rutherford ti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé tuntun náà. Ó mórí wa wú gan-an! Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gba ẹ̀dà ìwé yẹn lọ́jọ́ tá à ń wí yìí ṣì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn jákèjádò ayé, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ fáwọn èèyàn.—Sáàmù 148:12, 13.

Lẹ́yìn tí mo ti dá ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún odindi ọdún mẹ́ta, ẹ wá wo bínú mi ṣe dùn tó nígbà tí mo gba lẹ́tà tí wọ́n fi yàn mí sí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Chambersburg! Ibẹ̀ ni èmi àti Dorothea ti pàdé, kò sì pẹ́ táwa méjèèjì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ wà lára wa, a sì lágbára gan-an. Ara àwa méjèèjì wà lọ́nà láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Bá a ṣe jọ bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìṣúra nìyẹn o, gbogbo ìgbésí ayé wa la sì fi wá a.—Sáàmù 110:3.

Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tá a bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe la bá arákùnrin kan tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì àkọ́kọ́ ti Gílíádì pàdé, Albert Mann lórúkọ rẹ̀. Ó ti ń múra àtilọ síbi tí wọ́n yàn án sí nílẹ̀ òkèèrè. Ó gbà wá níyànjú pé ká fara mọ́ ibikíbi tí wọ́n bá yàn wá sí pé ká ti lọ sìn.

Àwa Méjèèjì Jọ Lọ Sílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Ọ̀RỌ̀ DORA ÀTI DOROTHEA: Tẹ́ ẹ bá rí i bínú àwa méjèèjì ṣe dùn tó nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti di míṣọ́nnárì! Lọ́jọ́ tá a kọ́kọ́ dé ilé ẹ̀kọ́ náà, Arákùnrin Albert Schroeder ló kọ orúkọ wa sílẹ̀, arákùnrin yìí ló fún màmá Dorothea ní ìwé Studies in the Scriptures ní ọdún méjìlá ṣáájú àkókò yẹn. Arákùnrin John Booth wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Ó ti wá di alábòójútó oko ní Oko Society tó wà níbi tí ilé ẹ̀kọ́ náà wà. Nígbà tó yá, àwọn arákùnrin méjèèjì náà di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn òtítọ́ tó jinlẹ̀ gan-an nínú Bíbélì la kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àgbà ẹ̀kọ́ ni ẹ̀kọ́ náà. Àwa akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìnlélọ́gọ́rùn-ún la wà ní kíláàsì wa, títí kan akẹ́kọ̀ọ́ kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Òun lẹni àkọ́kọ́ tó wá sí kíláàsì náà láti orílẹ̀-èdè mìíràn. Òun ń gbìyànjú láti túbọ̀ mọ èdè òyìnbó sọ nígbà táwa ń kọ́ èdè Sípáníìṣì. Inú wa dùn gan-an lọ́jọ́ tí Arákùnrin Nathan H. Knorr pín ibi táwa akẹ́kọ̀ọ́ ti máa lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè fún wa! Àwọn tó pọ̀ jù lọ ni wọ́n yàn sí Amẹ́ríkà ti Àárín àti Amẹ́ríkà ti Gúúsù; àmọ́ orílẹ̀-èdè Chile ni wọ́n ní kí àwa lọ.

Bá A Ṣe Wá Ìṣúra Lórílẹ̀-Èdè Chile

Ká tó lè wọ orílẹ̀-èdè Chile, ó di dandan ká gba ìwé àṣẹ wíwọ orílẹ̀-èdè míì, èyí sì gba àkókò gan-an. Èyí mú ká ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún odindi ọdún kan àtààbọ̀ ní ìpínlẹ̀ Washington, D.C. lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege lóṣù January ọdún 1945. Nígbà tó yá, a rí ìwé àṣẹ ìwọ̀lú gbà, a sì wà lára àwọn míṣọ́nnárì mẹ́sàn-án tó rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè Chile. Àwọn méje lára wa ti kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì láwọn kíláàsì tó ṣáájú tiwa.

Àwọn arákùnrin bíi mélòó kan wá pàdé wa nígbà tá a dé ìlú Santiago tó jẹ́ olú ìlú wọn. Ọ̀kan lára wọn ni Albert Mann, tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì. Òun ló gbà wá níyànjú lọ́dún díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. Ó ti wá sí orílẹ̀-èdè Chile lọ́dún kan ṣáájú ìgbà yẹn, òun àti Joseph Ferrari tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kejì ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àwọn akéde tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè Chile kò pé ọgọ́rùn-ún nígbà tá a débẹ̀. Ara wa wà lọ́nà gan-an láti túbọ̀ wá àwọn ohun ìṣúra rí, ìyẹn àwọn èèyàn tó dìídì fẹ́ mọ òtítọ́, níbi tí wọ́n yàn wá sí.

Wọ́n ní ká lọ sílé àwọn míṣọ́nnárì kan tó wà nílùú Santiago, ká sì máa sìn nílùú náà. Bá a ṣe ń gbé níbì kan náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ míṣọ́nnárì jẹ́ ohun kan tó ṣàjèjì sí wa. Yàtọ̀ sí pé ó níye wákàtí tá a gbọ́dọ̀ fi wàásù, gbogbo àwa míṣọ́nnárì la máa ń gba oúnjẹ sè lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ fún ìdílé náà. Àwọn ìgbà kan wà tá a ṣe ohun tó ń tini lójú. Nígbà kan, a ṣe búrẹ́dì tó máa jẹ́ oúnjẹ àárọ̀ fún àwa míṣọ́nnárì tí ebi ti ń pa, àmọ́ nígbà tá a gbé búrẹ́dì náà jáde látinú ààrò ta a fi yan án, a rí i pé ó ń run òórùn kan tí kò dára. A ti ṣèèṣì lo nǹkan mìíràn dípò ohun amú-nǹkan-wú tó yẹ ká lò! Ìdí ni pé ẹni tó lẹ bébà mọ́ ara agolo náà ṣe àṣìṣe.

Àwọn nǹkan mìíràn tó tún tini lójú ni àwọn àṣìṣe tá a ṣe nígbà tá a ń kọ́ èdè Sípáníìṣì. Ìdílé ńlá kan tá a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ pé àwọn ò kẹ́kọ̀ọ́ mọ́ nítorí pé ọ̀rọ̀ wa ò yé wọn. Àmọ́ níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú Bíbélì tiwọn gan-an ni wọ́n ti ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá à ń kà, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, márùn-ún lára wọn sì di Ẹlẹ́rìí. Láwọn ọdún wọ̀nyẹn, kò sí ètò fún kíkọ èdè tuntun fáwọn míṣọ́nnárì. Ojú ẹsẹ̀ la máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù tá a sì máa ń gbìyànjú láti kọ́ èdè náà lọ́dọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún.

A darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀ gan-an, àwọn kan lára àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sì tẹ̀ síwájú kíákíá. Àmọ́, àwọn kan lára wọn gba ká ṣe sùúrù gan-an. Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Teresa Tello tẹ́tí sí ìhìn òtítọ́ náà, ó sì sọ pé, “Ẹ jọ́wọ́, ẹ tún padà wá bá mi sọ̀rọ̀ sí i.” A padà lọ síbẹ̀ nígbà méjìlá, àmọ́ á ò rí i. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, a lọ sí àpéjọ kan tá a ṣe ní gbọ̀ngàn ìṣeré kan nílùú Santiago. Bá a ṣe ń kúrò níbi àpéjọ náà lọ́jọ́ Sunday, ni a ṣàdédé ń gbọ́, “Àǹtí Dora, Àǹtí Dora!” Bá a ṣe bójú wẹ̀yìn báyìí, Teresa la rí. Ó wá kí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó ń gbé nítòsí ibẹ̀, ló bá wá síbi àpéjọ náà láti wá wo ohun tó ń lọ níbẹ̀. Inú wa dùn gan-an pé a tún padà rí i! A ṣètò bó ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ sí àkókò yẹn tó fi ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá, ó di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Láti nǹkan bí ọdún márùnlélógójì ni Teresa ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún, ó ṣì ń bá a lọ dòní olónìí.—Oníwàásù 11:1.

A Rí Àwọn Ìṣúra Nínú “Erùpẹ̀”

Lọ́dún 1959, wọ́n ní ká lọ sílùú Punta Arenas, tó túmọ̀ sí “Ibi Tí Erùpẹ̀ Pọ̀ sí” nípẹ̀kun apá gúúsù ilẹ̀ Chile. Ibẹ̀ jẹ́ etíkun tó gùn tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà. Àgbègbè kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Punta Arenas. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ilẹ̀ kì í ṣú títí di aago mọ́kànlá ààbọ̀ alẹ́. A máa ń ráyè lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, àmọ́ kì í ṣe pé kò síṣòro kankan o, nítorí pé ẹ̀fúùfù máa ń fẹ́ gan-an lákòókò yẹn. Nígbà òtútù, ibẹ̀ máa ń tutù gan-an, ilẹ̀ sì tètè máa ń ṣú.

Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro yìí, ìlú Punta Arenas ní ẹwà tiẹ̀. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ńṣe ni kùrukùru máa ń wọ́ lójú ọ̀run, tí òjò á sì ṣú sí apá ìwọ̀ oòrùn lójú sánmà. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, òjò á rọ̀ yàà lé ọ lórí, àmọ́ kíá ni afẹ́fẹ́ yóò máa fẹ́ tí ara rẹ á sì gbẹ. Òṣùmàrè kan tó lẹ́wà gan-an á sì yọ bí oòrùn bá ṣe ń gba inú ìkùukùu náà kọjá. Òṣùmàrè yìí máa ń pẹ́ gan-an kó tó pòórá nígbà míì tí oòrùn bá ń ràn lójú sánmà tí òjò ṣú sí.—Jóòbù 37:14.

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn akéde ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ nílùú Punta Arenas. Àwa arábìnrin la máa ń darí ìpàdé nínú ìjọ kékeré kan tó wà níbẹ̀. Jèhófà sì bù kún ìsapá wa. Ọdún mẹ́tàdínlógójì lẹ́yìn ìyẹn, a padà sí àgbègbè tá à ń wí yìí láti lọ wò wọ́n. Kí la rí nígbà tá a débẹ̀? Ìjọ mẹ́fà tó ń gbèèrú gan-an ti wà níbẹ̀, wọ́n sì tún ní Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta tó lẹ́wà gan-an. Inú wa mà dùn ò, pé Jèhófà jẹ́ ká lè rí àwọn ohun ìṣúra tẹ̀mí tó wà nínú erùpẹ̀ ìhà gúúsù yẹn!—Sekaráyà 4:10.

A Tún Rí Ọ̀pọ̀ Ìṣúra Sí I ní “Etíkun Fífẹ̀”

Lẹ́yìn tá a ti sìn fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ nílùú Punta Arenas, wọ́n tún ní ká lọ sìn ní ìlú Valparaiso tó wà ní etíkun. Ìlú náà ní àwọn òkè mọ́kànlélógójì tó wà ní etíkun Òkun Pàsífíìkì. Ọ̀kan lára àwọn òkè yẹn la ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa, Playa Ancha ni orúkọ ibẹ̀, èyí tó túmọ̀ sí “Etíkun Fífẹ̀.” Láàárín ọdún mẹ́rìndínlógún tá a fi wà níbẹ̀, a rí àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tí wọ́n tẹ̀ síwájú nínú ìjọ Ọlọ́run débi pé wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò àti alàgbà nínú ìjọ jákèjádò orílẹ̀-èdè Chile nísinsìnyí.

Ìlú Viña del Mar ni wọ́n tún ní ká lọ lẹ́yìn ìyẹn. A sìn níbẹ̀ fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ kó tó di pé ìmìtìtì ilẹ̀ ba ilé àwa míṣọ́nnárì tó wà níbẹ̀ jẹ́. A wá padà sí ìlú Santiago, níbi tá a ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa ní ogójì ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Àwọn nǹkan ti yí padà gan-an. Wọ́n ti kọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ tuntun síbẹ̀, ilé tí wọ́n sì ń lò fún ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa tẹ́lẹ̀ ti wá di ibi tí gbogbo àwọn míṣọ́nnárì tó ṣẹ́ kù sí orílẹ̀-èdè náà ń gbé. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo ilé yẹn fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Lákòókò yẹn, Jèhófà tún fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ hàn sí wa. Wọ́n ní káwa márùn-ún tá a jẹ́ míṣọ́nnárì tá a ti dàgbà lọ́jọ́ orí wá máa gbé ní Bẹ́tẹ́lì. Láàárín ìgbà tá a fi sìn ní orílẹ̀-èdè Chile yìí, a ti sìn ní ibi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. A ti rí i bí iṣẹ́ náà ṣe tẹ̀ síwájú gan-an látorí àwọn akéde tí kò tó ọgọ́rùn-ún sí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin akéde nísinsìnyí! Ayọ̀ wa pọ̀ gan-an bá a ṣe fi ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta wá àwọn ohun tó jẹ́ ìṣúra nílẹ̀ Chile!

A rí i pé ìbùkún ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà fún wa láǹfààní láti rí ọ̀pọ̀ èèyàn, ìyẹn àwọn tó jẹ́ ojúlówó ìṣúra, tí Jèhófà ṣì ń lò nínú ètò rẹ̀. Láàárín ohun tó lé lọ́gọ́ta ọdún tá a fi sìn Jèhófà pa pọ̀, tọkàntọkàn la fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú Dáfídì Ọba, tó kọ̀wé pé: “Oore rẹ mà pọ̀ yanturu o, èyí tí o ti tò pa mọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ!”—Sáàmù 31:19.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Dorothea rèé lọ́dún 2002 àti nígbà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́dún 1943

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

A ń wàásù lójú pópó nílùú Fort Dodge, tó wà ní ìpínlẹ̀ Iowa, nílẹ̀ Amẹ́ríkà, lọ́dún 1942

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Dora rèé lọ́dún 2002

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Dorothea àti Dora níwájú ilé míṣọ́nnárì tí wọ́n kọ́kọ́ gbé nílẹ̀ Chile lọ́dún 1946

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́