ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 8/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ìdí Tí Dáfídì Fi Gbọ́dọ̀ Sá Lọ
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • ‘Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 8/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì tán, kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù Ọba tún fi ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé “Ọmọkùnrin ta ni ọ́, ọmọdékùnrin?” nígbà tó jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ló ránṣẹ́ pe Dáfídì pé kó wá di ẹmẹ̀wà òun?—1 Sámúẹ́lì 16:22; 17:58.

Ìdáhùn kan tó wá sọ́kàn èèyàn ni pé ojú Sọ́ọ̀lù ti lọ lára Dáfídì, nítorí pé wọn ò jọ sọ̀rọ̀ púpọ̀ nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n pàdé. Àmọ́ ṣá o, kò dájú pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, nítorí pé àkọsílẹ̀ tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 16:18-23 fi hàn pé Sọ́ọ̀lù Ọba ló dìídì ránṣẹ́ pe Dáfídì, ó wá nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gidigidi, ó sì sọ ọ́ di arùhámọ́ra rẹ̀. Sọ́ọ̀lù ti gbọ́dọ̀ mọ Dáfídì dáadáa nìyẹn.

Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé lẹ́yìn tí wọ́n kọ Bíbélì tán ni wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ fi àkọsílẹ̀ tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 17:12-31 àti 17:55–18:5 kún Bíbélì, nítorí pé àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn kò sí nínú àwọn ẹ̀dà kan tó jẹ́ ti Bíbélì Greek Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n parí ìtumọ̀ rẹ̀ ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Kò ní bọ́gbọ́n mu láti sọ pé àfikún ni àwọn ẹsẹ yẹn jẹ́ kìkì nítorí pé àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyẹn kò sí nínú àwọn ẹ̀dà kan tó jẹ́ ti Bíbélì Septuagint, nígbà tó jẹ́ pé àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyẹn wà nínú àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n fọwọ́ kọ, tó sì ṣeé gbára lé.

Ó hàn gbangba pé kì í ṣe orúkọ bàbá Dáfídì nìkan ni Sọ́ọ̀lù fẹ́ mọ̀, nítorí pé ó kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Ábínérì nípa ọmọ ẹni tí Dáfídì jẹ́ kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá béèrè lọ́wọ́ Dáfídì alára. Ojú tí Sọ́ọ̀lù fi ń wo Dáfídì ti yàtọ̀ pátápátá látìgbà tó ti ṣẹ́gun Gòláyátì tó sì fi hàn pé ọmọ tó nígbàgbọ́ gan-an tó sì tún nígboyà lòun, nítorí ìdí yìí Sọ́ọ̀lù fẹ́ mọ ẹni tó tọ́ Dáfídì dàgbà. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí Sọ́ọ̀lù ní in lọ́kàn pé òun máa fi bàbá Dáfídì, ìyẹn Jésè tàbí àwọn aráalé rẹ̀ mìíràn kún àwọn ọmọ ogun òun, níwọ̀n bí àwọn náà yóò ti ní ọgbọ́n àti agbára bíi ti Dáfídì.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdáhùn ṣókí tí Dáfídì fún Sọ́ọ̀lù ló wà nínú 1 Sámúẹ́lì 17:58, tó sọ pé “Ọmọkùnrin Jésè ìránṣẹ́ rẹ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,” àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lè e fi hàn pé àwọn méjèèjì ṣì jọ sọ̀rọ̀ fún ìgbà pípẹ́. Fiyè sí ohun tí ọ̀gbẹ́ni Carl F. Keil àti Franz Delitzsch sọ lórí kókó yìí, wọ́n ní: “Ó hàn gbangba pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 18:1, tó sọ pé ‘gbàrà tí ó bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ tán,’ jẹ́ ká mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù béèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ nípa ìdílé tí Dáfídì ti wá lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí pé gbólóhùn yẹn fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣókí ní Sọ́ọ̀lù àti Dáfídì sọ.”

Pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí, a lè sọ pé nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń béèrè pé “Ọmọkùnrin ta ni ọ́, ọmọdékùnrin?” Kì í ṣe pé ó kàn fẹ́ mọ Dáfídì lásán, nítorí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tó fẹ́ mọ̀ ni irú ilé tí Dáfídì ti jáde wá.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi bi Dáfídì léèrè ọmọ ẹni tó jẹ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́