ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 10/15 ojú ìwé 30
  • Sírákúsì Ìlú Tí Ọkọ̀ Òkun Tí Pọ́ọ̀lù Wọ̀ Ti Dúró Díẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sírákúsì Ìlú Tí Ọkọ̀ Òkun Tí Pọ́ọ̀lù Wọ̀ Ti Dúró Díẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • “Kò sí Ìkankan Lára Yín Tó Máa Ṣègbé”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • “Jẹ́rìí Kúnnákúnná”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Wọ́n Gbé Pọ́ọ̀lù Lọ sí Róòmù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 10/15 ojú ìwé 30

Sírákúsì Ìlú Tí Ọkọ̀ Òkun Tí Pọ́ọ̀lù Wọ̀ Ti Dúró Díẹ̀

NÍ NǸKAN bí ọdún 59 Sànmánì Kristẹni, ọkọ̀ òkun kan gbéra láti erékùṣù Málítà tó wà ní Òkun Mẹditaréníà, ó sì forí lé ilẹ̀ Ítálì. Ọkọ̀ òkun náà ní ère orí ọkọ̀ tí wọ́n pè ní “Àwọn Ọmọ Súúsì,” ìyẹn àwọn òrìṣà tí wọ́n gbà pé ó ń dáàbò bo àwọn arìnrìn àjò lójú òkun. Òǹkọ̀wé Bíbélì náà Lúùkù ròyìn pé, ọkọ̀ òkun náà ‘gúnlẹ̀ sí èbúté ọkọ̀ ní Sírákúsì’ tó wà ní etíkun gúúsù ìlà oòrùn Sísílì, ó sì “dúró fún ọjọ́ mẹ́ta.” (Ìṣe 28:11, 12) Àrísítákọ́sì wà nínú ọkọ̀ yẹn pẹ̀lú Lúùkù, àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù táwọn ọmọ ogun ń mú lọ jẹ́jọ́ nílùú Róòmù.—Ìṣe 27:2.

A ò lè sọ bóyá wọ́n gbà kí Pọ́ọ̀lù sọ kalẹ̀ nígbà tí wọ́n dé Sírákúsì. Tó bá jẹ́ pé wọ́n gbà kóun tàbí Lúùkù àti Àrísítákọ́sì tí wọ́n bá a rìnrìn àjò sọ̀ kalẹ̀, kí ló ṣeé ṣe kí wọ́n rí?

Nígbà tí ilẹ̀ Gíríìsì àti Róòmù wà lójú ọpọ́n, ìlú pàtàkì bí Áténì àti Róòmù ni Sírákúsì jẹ́. Ìtàn sọ pé àwọn ará Kọ́ríńtì ló tẹ ibẹ̀ dó lọ́dún 734 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn ìgbà kan wà tí ògo ìlú Sírákúsì yọ dáadáa, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó láyé ọjọ́un, irú bí Epicharmus tó ń kọ àwọn eré apanilẹ́rìn-ín, àti onímọ̀ ìṣirò náà, Archimedes. Àmọ́, nígbà tó di ọdún 212 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ilẹ̀ Róòmù ṣẹ́gun Sírákúsì.

Tó o bá lọ sí ìlú Sírákúsì lóde òní, wàá róye bí ìlú náà ṣe rí nígbà ayé Pọ́ọ̀lù. Apá méjì ni ìlú náà pín sí. Apá kan wà ní erékùṣù kékeré tó ń jẹ́ Ortygia níbi tó jọ pé ọkọ̀ tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ gúnlẹ̀ sí, apá kejì kì í sì í ṣe erékùṣù.

Lóde òní, tó o bá dé Sísílì, o lè rí àwókù tẹ́ńpìlì tọ́jọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ tí wọ́n kọ́ lọ́nà ṣákálá kan táwọn ará Gíríìsì gbà ń kọ́lé. Ó wà ní apá kejì ìlú Sírákúsì tó jẹ́ erékùṣù. Òrìṣà kan tí wọ́n ń pè ní Ápólò ni wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà fún, nǹkan bí ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n sì ti kọ́ ọ. Àwọn òpó kan tún wà lára tẹ́ńpìlì tí wọ́n yà sí mímọ́ fún òrìṣà Átẹ́nà, èyí tó ti wà níbẹ̀ láti nǹkan bí ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, kó tó di pé wọ́n wá kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ńlá kan mọ́ ọn.

Lóde òní, apá kejì ìlú Sírákúsì tí kì í ṣe erékùṣù ni ojúkò káràkátà wà. Ibẹ̀ lèèyàn sì ti máa rí ọgbà ńlá kan tí wọ́n kó ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí sí. Béèyàn bá ti wọnú ọgbà náà lèèyàn á ti rí gbọ̀ngàn ìṣeré ilẹ̀ Gíríìsì, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn gbọ̀ngàn ìṣeré tó fa kíki jù lọ táwọn ará Gíríìsì kọ́ láyé ọjọ́un tó ṣì wà títí dòní. Kíkọjú tí gbọ̀ngàn ìṣeré náà kọjú sí òkun mú kó jẹ́ ibi tó dára gan-an fún eré ṣíṣe. Gbọ̀ngàn ìṣeré ńlá kan táwọn ará Róòmù kọ́ ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Kristẹni tún wà nípẹ̀kun apá gúúsù ọgbà náà. Gbọ̀ngàn náà rí bìrìkìtì, ó gùn tó ogóje [140] mítà, ó sì fẹ̀ tó mítà mọ́kàndínlọ́gọ́fà [119]. Òun ló ṣìkẹta nínú àwọn gbọ̀ngàn ìṣeré tó tóbi jù ní Ítálì.

Tó o bá láǹfààní láti lọ sí Sírákúsì, o lè jókòó sórí àga tó wà létíkun ní Ortygia, kó o ṣí Bíbélì rẹ sí ìwé Ìṣe 28:12, kó o sì wá fojú inú wo bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe wọ ọkọ̀ òkun náà àti bó ṣe rọra gúnlẹ̀ sí èbúté ní Sírákúsì.

[Àwòrán/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 30]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Málítà

Sísílì

Sírákúsì

ÍTÁLÌ

Régíómù

Pútéólì

Róòmù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwókù gbọ̀ngàn ìṣeré kan táwọn ará Gírísì kọ́ sí Sírákúsì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́