Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Àwọn kan sọ pé erékùṣù mìíràn ni ọkọ̀ ti ri Pọ́ọ̀lù, pé kì í ṣe erékùṣù Málítà tó wà ní gúúsù ìlú Sísílì. Ibo wá ni ọkọ̀ ti rì í gan-an?
Ìbéèrè yìí tọ́ka sí ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ń sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé kì í ṣe erékùṣù Málítà ni ọkọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wọ̀ ti rì, bí kò ṣe erékùṣù Cephalonia (tàbí Kefallinía) tó wà nítòsí erékùṣù Corfu lórí òkun Ionia, lápá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Gíríìsì. Àkọsílẹ̀ onímìísí sọ fún wa pé ìlú Kesaréà ni Pọ́ọ̀lù ti gbéra, òun àti Júlíọ́sì, balógun ọ̀rún ará Róòmù tí wọ́n fi ṣe ọlọ́pàá rẹ̀ àtàwọn sójà míì àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe fi hàn nínú máàpù yìí, wọ́n wọkọ̀ ojú omi lọ sí Sídónì àti Máírà. Látibẹ̀, wọ́n wọ ọkọ̀ ńlá tí wọ́n fi ń ko ọkà tó ń bọ̀ láti ìlú Alẹkisáńdíríà ní Íjíbítì, wọ́n wá gba ọ̀nà ìwọ̀ oòrùn lọ sí Kínídọ́sì. Kò ṣeé ṣe fún wọn láti gba ọ̀nà tí wọ́n ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ pé àwọn fẹ́ gbà, ìyẹn ọ̀nà tó gba àárín Òkun Aegean kọjá, tó tún kọjá létí ìlú Gíríìsì títí lọ dé Róòmù. Ẹ̀fúùfù líle darí ọkọ̀ wọn lọ síhà gúúsù ìlú Kírétè àti sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ gọnbu tó wà létí omi. Wọ́n wá gúnlẹ̀ sí èbúté kan tí wọ́n ń pè ní Èbúté Rere. Bí wọ́n ṣe “ṣíkọ̀ sójú òkun láti Kírétè,” “ẹ̀fúùfù oníjì líle tí a ń pè ní Yúrákúílò” gba ọkọ̀ wọn “lọ́nà lílenípá.” Ni ọkọ̀ fàkìàfakia tí wọ́n fi ń kó ọkà yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ “síwá-sẹ́yìn lórí òkun” títí di òru kẹrìnlá. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [276] èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ náà rì sómi ní erékùṣù kan tí Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì pè ní Me·liʹte.—Ìṣe 27:1–28:1.
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, làwọn èèyàn wá ń dárúkọ onírúurú ibi tí wọ́n rò pé ó ṣeé ṣe kí erékùṣù Me·liʹte yìí wà. Àwọn kan rò pé òun ni erékùṣù Melite Illyrica, tá a mọ̀ sí Mljet nísinsìnyí, ní Òkun Adriatic nítòsí etíkun Croatia. Àmọ́, ó dà bí ẹni pé kì í ṣòun, nítorí pé apá ìbí tí àríwá erékùṣù Mljet wà kò bá àpèjúwe àwọn ibi tí Pọ́ọ̀lù gbà lẹ́yìn ìgbà yẹn mu, ìyẹn ìlú Sírákúsì ní Sísílì, lẹ́yìn náà ó gba ọ̀nà tó wà létíkun ìwọ̀ oòrùn Ítálì.—Ìṣe 28:11-13.
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn atúmọ̀ Bíbélì ló gbà pé Me·liʹte tọ́ka sí erékùṣù Melite Africanus, tá a mọ̀ sí Malta lóde òní. Ibi tí ọkọ̀ tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ ti dúró kẹ́yìn lójú ọ̀nà ni èbúté kan tí wọ́n ń pé ní Èbúté Rere, ní Kírétè. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni ẹ̀fúùfù líle wá darí ọkọ̀ wọn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn lápá ìlú Káúdà. Ìgbì náà kàn ṣáà ń gbé ọkọ̀ náà lọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ọkọ̀ tí ẹ̀fúùfù líle ń gbé lọ yìí yóò lọ jìnnà sápá ìwọ̀ oòrùn títí lọ dé erékùṣù Málítà.
Nígbà tí Conybeare àti Howson ro ti ẹ̀fúùfù tó sábà máa ń fẹ́ láyé ìgbà yẹn àti “ibi tí ìgbì darí ọkọ̀ náà sí àti bó ṣe yára gbé e lọ tó,” wọ́n sọ nínú ìwé wọn The Life and Epistles of St. Paul pé: “Díẹ̀ ló fi dín ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́rin [770] kìlómítà tí Clauda [tàbí Káúdà] àti erékùṣù Málítà fi jìnnà síra wọn. Àpèjúwe yẹn bá a mú lọ́nà tó bùáyà, tó fi jẹ́ pé èèyàn á gbà pé kò sí ilẹ̀ mìíràn táwọn awakọ̀ ojú omi náà [sún mọ́ tòsí rẹ̀] ní òru kẹrìnlá náà ju erékùṣù Málítà lọ. Erékùṣù náà ló tiẹ̀ máa jẹ́.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn láǹfààní láti dárúkọ ibòmíì tí wọ́n rò pé ó jẹ́, síbẹ̀ ọkọ̀ tó rì sómi ní erékùṣù Málítà tá a fi hàn nínú máàpù tó wà níbí yìí bá ohun tí Bíbélì wí mu.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Jerúsálẹ́mù
Kesaréà
Sídónì
Máírà
Kínídọ́sì
KÍRÉTÈ
KÁÚDÀ
MÁLÍTÀ
SÍSÍLÌ
Sírákúsì
Róòmù
MLJET
GÍRÍÌSÌ
CEPHALONIA