ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 27-28
Pọ́ọ̀lù Wọkọ̀ Ojú Omi Lọ sí Róòmù
Gbogbo ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń wàásù, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó wà lẹ́wọ̀n. Kódà, ó wàásù fún àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ ojú omi. Lẹ́yìn tí ọkọ̀ wọn rì ní ìlú Málítà, ó dájú pé ó fi àǹfààní yẹn wàásù fún àwọn tó wò sàn. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó dé Róòmù, ó pe àwọn tí wọ́n jẹ́ sàràkí-sàràkí jọ lára àwọn Júù tó wà ní Róòmù kó bàa lè wàásù fún wọn. Kódà ní gbogbo ọdún méjì tó lò ní àtìmọ́lé, ṣe ló ń wàásù fún àwọn tó wá kí i.
Kí lo lè ṣe láti wàásù ìhìn rere láìka ìṣòro èyíkéyìí tó o bá ní sí?