‘Ẹ Gbé Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Wọ̀’
ỌKÙNRIN kan wà tó wá láti ìlú kan tó lókìkí. Látìgbà tí wọ́n ti bí i ló ti jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Róòmù, èyí tó jẹ́ ohun táwọn èèyàn fi máa ń yangàn nígbà yẹn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìdílé pàtàkì ló ti wá. Sọ́ọ̀lù ni ọkùnrin tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni ló gbà. Ó kéré tán, ó ń sọ èdè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì wà lára àwọn Farisí, tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ kan tó gbajúmọ̀ gan-an nínú ẹ̀sìn àwọn Júù.
Ó ṣeé ṣe kó ti mọ́ Sọ́ọ̀lù lára láti máa fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn gbáàtúù èèyàn kó sì máa yangàn pé olódodo lòun. (Lúùkù 18:11, 12; Ìṣe 26:5) Àwọn Farisí bíi ti Sọ́ọ̀lù náà gbà pé àwọn sàn ju àwọn èèyàn yòókù lọ. Wọ́n máa ń fẹ́ káwọn èèyàn ka àwọn sẹ́ni pàtàkì, wọ́n sì fẹ́ràn oyè kàǹkàkàǹkà. (Mátíù 23:6, 7; Lúùkù 11:43) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú àwọn èèyàn tí Sọ́ọ̀lù ń bá rìn yìí ló mú kó jọ ara rẹ̀ lójú. A mọ̀ pé ó ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni gan-an. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tó ti di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sọ pé nígbà kan, òun jẹ́ “asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi.”—1 Tímótì 1:13.
Bẹ́ẹ̀ ni, Sọ́ọ̀lù di Kristẹni, ìyẹn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ìwà rẹ̀ sì yí padà pátápátá. Ó ti di àpọ́sítélì nígbà tó sọ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé òun ni “ẹni tí ó kéré ju kékeré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́.” (Éfésù 3:8) Oníwàásù tó dáńgájíá ni, àmọ́ kò sọ pé nípa agbára òun lóun fi dà bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ló fi ògo fún. (1 Kọ́ríńtì 3:5-9; 2 Kọ́ríńtì 11:7) Pọ́ọ̀lù yìí lẹni tó gba àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:12.
Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn yìí wúlò fáwa tí à ń gbé lákòókò tá a wà yìí? Ǹjẹ́ àǹfààní tiẹ̀ wà nínú kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Ṣé òótọ́ ni pé téèyàn bá nírẹ̀lẹ̀, ànímọ́ tó dára gan-an lèèyàn ní?
Ǹjẹ́ Ẹlẹ́dàá Ayé àti Ọ̀run Ní Ìrẹ̀lẹ̀?
Ká tó lè sọ ohunkóhun nípa ìrẹ̀lẹ̀, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ronú nípa ohun tó jẹ́ èrò Ọlọ́run lórí ànímọ́ yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé òun ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, òun sì ni Ẹlẹ́dàá wa. A ní láti gbà pé àwa ní tiwa ò lágbára tó Ọlọ́run. A ò lè dá ṣe ohunkóhun láìsí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Láyé ọjọ́un, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Élíhù sọ pé: “Ní ti Olódùmarè, àwa kò lè rídìí rẹ̀; ó ga ní agbára.” (Jóòbù 37:23) Àní, kìkì ríronú nípa bí ayé tá a wà nínú rẹ̀ yìí ṣe tóbi tó àti bí ọ̀run ṣe fẹ̀ lọ salalu ti tó láti mú ká gbà pé a ò jẹ́ nǹkan kan! Wòlíì Aísáyà rọ̀ wá pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”—Aísáyà 40:26.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ni alágbára gbogbo, síbẹ̀ ó nírẹ̀lẹ̀. Ọba Dáfídì gbàdúrà sí i pé: “Ìwọ yóò sì fún mi ní apata ìgbàlà rẹ, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni ó sọ mí di ńlá.” (2 Sámúẹ́lì 22:36) Ohun tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni pé, ó bìkítà gan-an nípa àwọn ẹni rírẹlẹ̀ tí wọ́n ń sapá láti ṣe ohun tó wù ú, ó sì máa ń fi àánú hàn sí wọn. Jèhófà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti ọ̀run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kó bàa lè fìfẹ́ bá àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ lò.—Sáàmù 113:5-7.
Kò tán síbẹ̀ o, Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pétérù 5:5) Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ojú tí Ọlọ́run fi wo ẹ̀mí ìgbéraga, ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Òwe 16:5) Àmọ́ kí nìdí tá a fi lè sọ pé ànímọ́ tó dára gan-an lẹni tó bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ní?
Ohun Tí Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Kò Jẹ́
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kì í ṣe kéèyàn wà nípò ìrẹ̀sílẹ̀. Láwọn ibì kan láyé ọjọ́un, àwọn tó sábà máa ń lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ni àwọn ẹrú, ìyẹn àwọn tó wà lábẹ́ àwọn ẹlòmíràn, àwọn tó ní ìbànújẹ́ ọkàn, àtàwọn táráyé ń káàánú fún. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ńṣe ni jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ máa ń mú káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fúnni. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.” (Òwe 22:4) Ohun tí Sáàmù 138:6 sọ ni pé: “Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.”
Pé èèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kò túmọ̀ sí pé kò sóhun tónítọ̀hún mọ̀ ọ́n ṣe tàbí pé kò sí ohun kan tó ti gbé ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Jésù Kristi kò sọ nígbà kankan rí pé òun kì í ṣe Ọmọ ọ̀wọ́n kan ṣoṣo fún Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni kò díbọ́n pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun lórí ilẹ̀ ayé kò ṣe pàtàkì. (Máàkù 14:61, 62; Jòhánù 6:51) Síbẹ̀, Jésù fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn ní ti pé Bàbá rẹ̀ ló fi ògo àwọn iṣẹ́ tó ṣe fún, ó sì tún lo okun rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ dípò kó máa jẹ gàba lé wọn lórí tàbí kó máa ni wọ́n lára.
Àmì Pé Èèyàn Ní Ànímọ́ Tó Dára Gan-an
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n níbẹ̀ pé ohun tó mú káwọn èèyàn mọ Jésù Kristi ni “àwọn iṣẹ́ agbára” tó ṣe. (Ìṣe 2:22) Síbẹ̀, lójú àwọn kan, òun ni “ẹni rírẹlẹ̀ jù lọ nínú aráyé.” (Dáníẹ́lì 4:17) Kò gbé ìgbésí ayé ṣe-ká-rí-mi, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì kọ́ àwọn èèyàn pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ dára gan-an. (Lúùkù 9:48; Jòhánù 13:2-16) Àmọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ kò sọ ọ́ di òmùgọ̀ èèyàn. Kò bẹ̀rù rárá nígbà tó ń gbé orúkọ Bàbá rẹ̀ ga tó sì ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Fílípì 2:6-8) Bíbélì fi Jésù wé kìnnìún tí kì í bẹ̀rù. (Ìṣípayá 5:5) Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká rí i pé ànímọ́ tó dára gan-an làwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ní.
Bá a ti ń gbìyànjú láti ní ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, a rí i pé ó gba ìsapá gan-an kéèyàn tó lè jẹ́ ẹni tó ń fìrẹ̀lẹ̀ ṣèwàhù nígbèésí ayé rẹ̀. Ó ń béèrè pé ká máa ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo dípò ṣíṣe ohun tó bá ṣáà ti rọ̀ wá lọ́rùn tàbí ohun tí ẹran ara fẹ́. Níní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gba pé ká máa hùwà tó bójú mu, torí pé a gbọ́dọ̀ gbé èrò tara wa tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ká tó lè fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ sin Jèhófà àtàwọn ẹlòmíràn.
Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
Ohun tí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ túmọ̀ sí ni pé kéèyàn jẹ́ ẹni tí kò lẹ́mìí ìgbéraga tàbí ẹ̀mí ìjọra ẹni lójú. Ìwé Mímọ́ pe irú ìwà bẹ́ẹ̀ ní ‘ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú.’ (Éfésù 4:2) Kéèyàn mọ irú ẹni tóun jẹ́ dáadáa ló ń mú kéèyàn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ìyẹn ni pé ká mọ àwọn ibi tá a dára sí àtàwọn ibi tá a kù sí, ká tún mọ àwọn àṣeyọrí tá a ti ṣe àtàwọn àṣìṣe wa. Pọ́ọ̀lù fún wa ní ìmọ̀ràn kan tó dára gan-an lórí kókó yìí, ó sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.” (Róòmù 12:3) Ẹnikẹ́ni tó bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.
Ọ̀nà mìíràn tá a tún lè gbà fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn ni pé ká bìkítà nípa ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíràn ju tara wa lọ. Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti ṣí àwọn Kristẹni létí pé: “[Ẹ má ṣe ṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.” (Fílípì 2:3) Èyí bá àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mu pé: “Kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ òjíṣẹ́ yín. Ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ẹnì yòówù tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.”—Mátíù 23:11, 12.
Bẹ́ẹ̀ ni, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú máa ń mú kéèyàn níyì gan-an lójú Ọlọ́run. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù tẹnu mọ́ kókó yìí, ó ní: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ojú Jèhófà, yóò sì gbé yín ga.” (Jákọ́bù 4:10) Ta ni kò ní fẹ́ kí Ọlọ́run gbé òun ga?
Àìní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ti fa yánpọnyánrin àti gbọ́nmi-sí-i-omi-ò-tó-o láàárín ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti láàárín àwọn ọ̀rẹ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó ń mú kéèyàn jẹ́ ẹni tínú Ọlọ́run dùn sí. (Míkà 6:8) Yóò jẹ́ ká ní ìbàlẹ̀ ọkàn, nítorí pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ sábà máa ń láyọ̀, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀ ju tàwọn onígbèéraga èèyàn lọ. (Sáàmù 101:5) Àjọṣe àárín àwa àti ìdílé wa, àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àtàwọn mìíràn, yóò túbọ̀ dán mọ́rán sí i, á sì túbọ̀ lárinrin. Àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í fẹ́ ṣe ohun tó máa bí àwọn èèyàn nínú, wọn kì í sọ pé ohun tí wọ́n bá fẹ́ ni ẹlòmíràn gbọ́dọ̀ fẹ́, èyí tó sábà máa ń yọrí sí ìbínú, káwọn èèyàn máa yẹra fúnni, ìkórìíra, àti ìbànújẹ́ ọkàn.—Jákọ́bù 3:14-16.
Kò sírọ́ níbẹ̀ o, ọ̀nà kan tó dára gan-an tá a lè gbà mú kí àárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn gún régé ni pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro inú ayé tí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ẹ̀mí ìdíje kúnnú rẹ̀ yìí. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti borí ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú àti ẹ̀mí ìgbéraga tó ti ní tẹ́lẹ̀. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, á dára ká má ṣe jẹ́ kí èrò èyíkéyìí tó lè mú wa hùwà ìgbéraga máa wá sọ́kàn wa tàbí èrò pé a sàn ju àwọn mìíràn lọ. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” (Òwe 16:18) Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tá a sì fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, a ó rí i pé ‘fífi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara wa láṣọ’ jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu.—Kólósè 3:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti borí ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú àti ẹ̀mí ìgbéraga
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Níní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò mú kí àárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn gún régé
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Anglo-Australian Observatory/David Malin Images