Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ọbadáyà, Ìwé Jónà, àti Ìwé Míkà
“ÌRAN Ọbadáyà.” (Ọbadáyà 1) Ọ̀rọ̀ yìí ló bẹ̀rẹ̀ ìwé Ọbadáyà nínú Bíbélì. Wòlíì yìí kò sọ ohunkóhun nípa ara rẹ̀ nínú ìwé rẹ̀ yìí, èyí tó kọ lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ju pé ó kàn dárúkọ ara rẹ̀ lọ. Wòlíì Jónà náà parí kíkọ ìwé tirẹ̀ lóhun tó lé ní igba ọdún ṣáájú àkókò yẹn, kò sì fi nǹkan kan pa mọ́ nígbà tó ń sọ ohun tójú rẹ̀ rí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì rẹ̀. Wòlíì Míkà fi ọgọ́ta ọdún sàsọtẹ́lẹ̀, èyí sì bọ́ sáàárín àkókò tí Ọbadáyà àti Jónà ń jẹ́ iṣẹ́ tiwọn, ìyẹn láàárín ọdún 777 sí ọdún 717 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Gbogbo ohun tí Míkà sọ nípa ara rẹ̀ kò ju pé òun wá láti abúlé Móréṣétì, àti pé òun gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà “ní àwọn ọjọ́ Jótámù, Áhásì, [àti] Hesekáyà, àwọn ọba Júdà.” (Míkà 1:1) Àwọn àpèjúwe tí wòlíì yìí lò láti fi gbé àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ fi hàn pé ìgbèríko ló dàgbà sí.
“A Ó KÉ [ÉDÓMÙ] KÚRÒ FÚN ÀKÓKÒ TÍ Ó LỌ KÁNRIN”
Ọbadáyà sọ nípa Édómù pé: “Nítorí ìwà ipá sí Jékọ́bù arákùnrin rẹ, ìtìjú yóò bò ọ́, dájúdájú, a ó ké ọ kúrò fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Wòlíì yìí ṣì rántí ìwà ìkà táwọn ará Édómù hù sáwọn ọmọ Jékọ́bù, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láìpẹ́ sígbà yẹn. Lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run, àwọn ará Édómù “dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan” wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ “àwọn àjèjì” tó wá kógun ja àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Ọbadáyà 10, 11.
Àmọ́ a ó mú ilé Jékọ́bù padà bọ̀ sípò. Àsọtẹ́lẹ̀ Ọbadáyà sọ pé: “Òkè Ńlá Síónì sì ni ibi tí àwọn tí ó sá àsálà yóò wà, yóò sì di ohun mímọ́.”—Ọbadáyà 17.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
5-8—Kí nìdí tí Ọbadáyà ṣe fi ìparun Édómù wé báwọn afiniṣèjẹ ṣe máa ń wá ní òru, tó sì tún fi wé àwọn olùkó èso àjàrà? Ká láwọn olè ló wá sí Édómù ni, kìkì ohun tí wọ́n fẹ́ ni wọn ì bá kó. Ká láwọn olùkórè ló sì wá ni, wọ́n ì bá fi irè oko díẹ̀ sílẹ̀ fáwọn tí ń pèéṣẹ́. Àmọ́ nígbà tí Édómù bá ṣubú, “gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà nínú májẹ̀mú pẹ̀lú [rẹ̀],” ìyẹn àwọn ará Bábílónì tí wọ́n jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún un, yóò wá gbogbo ìṣúra rẹ̀ rí wọn yóò sì kó o lọ ráúráú.—Jeremáyà 49:9, 10.
10—Báwo la ṣe “ké [Édómù] kúrò fún àkókò tí ó lọ kánrin?” Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, orílẹ̀-èdè Édómù, tó ní ìjọba tirẹ̀ àti ibi pàtó táwọn èèyàn rẹ̀ ń gbé láyé, di èyí tí kò sí mọ́. Nábónídọ́sì tó jẹ́ ọba Bábílónì ṣẹ́gun Édómù ní nǹkan bí ìdajì ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àgbègbè tó jẹ́ ti àwọn ará Édómù wá di ibi táwọn ará Nabataea ń gbé, àwọn ará Édómù sì ní láti lọ máa gbé lápá gúúsù ilẹ̀ Jùdíà, ìyẹn àgbègbè Négébù tó wá di Ídúmíà nígbà tó yá. Ẹ̀yìn ìgbà táwọn ará Róòmù pa ìlú Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni làwọn ará Édómù dẹni tí kò sí mọ́.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
3, 4. Nítorí pé àgbègbè tó ṣòro láti rìn táwọn òkè gíga àtàwọn àfonífojì jíjìn sí pọ̀ níbẹ̀ làwọn ará Édómù ń gbé, ó ṣòro gan-an fáwọn ọ̀tá láti wá kógun jà wọ́n. Ó ṣeé ṣe kí èyí ti fi àwọn ará Édómù lọ́kàn balẹ̀ kí wọ́n sì máa rò pé kò séwu fáwọn. Àmọ́ kò sí béèyàn ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Jèhófà.
8, 9, 15. Ọgbọ́n ẹ̀dá èèyàn àti agbára tí wọ́n ní kò lè dáàbò bò wọ́n ní “ọjọ́ Jèhófà.”—Jeremáyà 49:7, 22.
12-14. Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n làwọn ará Édómù jẹ́ fáwọn tó ń yọ̀ nítorí ìṣòro tó ń dojú kọ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Jèhófà kì í fojú kékeré wo ìyà táwọn kan lè máa fi jẹ àwọn èèyàn rẹ̀.
17-20. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí, tó sọ pé àwọn ọmọ Jékọ́bù yóò padà sí ilẹ̀ wọn, bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ nígbà táwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó lọ sígbèkùn nílẹ̀ Bábílónì padà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá sọ máa ń nímùúṣẹ. A lè fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.
‘A Ó BI NÍNÉFÈ ṢUBÚ’
Dípò kí Jónà ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un, pé kó “lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà kí [ó] sì pòkìkí” ìdájọ́ Ọlọ́run, ńṣe ló sá gba ibòmíràn lọ. Jèhófà wá rán “ẹ̀fúùfù ńláǹlà jáde sí òkun,” ó tún lo “ẹja ńlá” kan láti gbé Jónà lọ síbi tó rán-an, ó sì rán an níṣẹ́ náà lẹ́ẹ̀kejì pé kó lọ sí Nínéfè tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Asíríà.—Jónà 1:2, 4, 17; 3:1, 2.
Jónà wọ ìlú Nínéfè lọ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Ó ní: “Kìkì ogójì ọjọ́ sí i, a ó sì bi Nínéfè ṣubú.” (Jónà 3:4) Jónà ò retí ohun tó wá jẹ́ àbájáde iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀, èyí sì mú kí ‘inú rẹ̀ ru fún ìbínú.’ Jèhófà lo “ewéko akèrègbè kan” láti kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kéèyàn jẹ́ aláàánú.—Jónà 4:1, 6.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
3:3—Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni ìlú Nínéfè tóbi tó ohun téèyàn ń rin “ìrìn ọjọ́ mẹ́ta” láàárín rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Láyé ọjọ́un, ó ṣeé ṣe káwọn ìgbèríko mìíràn wà lára ohun táwọn èèyàn mọ̀ sí ìlú Nínéfè, ìyẹn láti Kọsábádì lápá àríwá lọ dé Nímírúdù ní ìhà gúúsù. Gbogbo àwọn ìgbèríko tí wọ́n mọ̀ sí Nínéfè para pọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún kìlómítà níbùú lóròó.
3:4—Ǹjẹ́ Jónà ní láti kọ́ èdè Asíríà kó tó lè wàásù fáwọn ará Nínéfè? Ó ṣeé ṣe kí Jónà ti mọ èdè Asíríà sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún un láti sọ ọ́ lọ́nà ìyanu. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló ń jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ tó ṣe ṣàkó náà lédè Hébérù tẹ́nì kan sì ń túmọ̀ rẹ̀. Bó bá jẹ́ pé èyí tó kẹ́yìn yìí ló ṣẹlẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti ní láti túbọ̀ mú káwọn èèyàn fẹ́ láti gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:1-3. Mímọ̀ọ́mọ̀ lọ máa ṣe àwọn nǹkan mìíràn nítorí kéèyàn má bàa kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ wíwàásù ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn fi hàn pé èrò tí kò dára lẹni náà ní lọ́kàn. A lè sọ pé ńṣe lẹni tó bá ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sá lọ kó má bàa ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run.
1:1, 2; 3:10. Àánú Jèhófà kò mọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè kan tàbí ẹ̀yà kan tàbí àwọn èèyàn kan pàtó. “Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.”—Sáàmù 145:9.
1:17; 2:10. Gbígbé tí ẹja ńlá kan gbé Jónà mì fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó ń ṣàpèjúwe ikú àti àjíǹde Jésù.—Mátíù 12:39, 40; 16:21.
1:17; 2:10; 4:6. Jèhófà kó Jónà yọ nínú òkun tó ń ru gùdù. Ọlọ́run tún “ṣètò ewéko akèrègbè kan, pé kí ó gòkè wá bo Jónà, kí ó bàa lè di ibòji lórí rẹ̀, láti dá a nídè kúrò nínú ipò oníyọnu àjálù rẹ̀.” Ó yẹ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run wọn àti nínú inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ pé yóò dáàbò bò wọ́n yóò sì gbà wọ́n.—Sáàmù 13:5; 40:11.
2:1, 2, 9, 10. Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ó sì máa ń tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ wọn.—Sáàmù 120:1; 130:1, 2.
3:8, 10. Ọlọ́run tòótọ́ “pèrò dà” lórí ìyọnu tó ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, “kò sì mú un wá.” Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ará Nínéfè “yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn.” Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lọ́jọ́ òní, Ọlọ́run lè yí ìdájọ́ tó fẹ́ mú wá sórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bá fi ẹ̀rí hàn pé òun ronú pìwà dà tọkàntọkàn.
4:1-4. Kò sí ẹ̀dá èèyàn kan tó lè sọ pé ibi báyìí ló yẹ kí àánú Ọlọ́run mọ. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má máa sọ pé àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fi àánú hàn kò dára.
4:11. Jèhófà ní sùúrù, ó ń jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wàásù Ìjọba rẹ̀ ní gbogbo ayé. Ìdí tó fi ń ṣe èyí ni pé, àánú àwọn “tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn” ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí àánú ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] èèyàn tó wà nílùú Nínéfè ti ṣe é. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àánú àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa máa ṣe àwa náà ká sì rí i pé à ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run gan-an àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn?—2 Pétérù 3:9.
‘A Ó MÚ ORÍ PÍPÁ WỌN FẸ̀ SÍ I’
Míkà tú ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì àti Júdà fó, ó sàsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn olú ìlú wọn yóò dahoro, ó sì tún ṣèlérí pé wọn á padà tún wọn kọ́. Samáríà yóò di “òkìtì àwókù inú pápá.” Nítorí ìwà ìbọ̀rìṣà Ísírẹ́lì àti Júdà, ‘orí pípá,’ ìyẹn ìtìjú tọ́ sí wọn. Nípa lílọ sí ìgbèkùn, orí pípá wọn á di èyí tó fẹ̀ sí i gẹ́gẹ́ “bí ti idì.” Kò sí àní-àní pé ẹyẹ igún kan tó máa ń ní ìwọ̀nba ìyẹ́ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ díẹ̀ lórí ni ẹyẹ yìí. Jèhófà ṣèlérí pé: “Èmi yóò kó Jékọ́bù jọ dájúdájú.” (Míkà 1:6, 16; 2:12) Nítorí àwọn aṣáájú tó ń hùwà ìbàjẹ́ àtàwọn wòlíì tó yàyàkuyà, Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ‘yóò di òkìtì àwókù lásán-làsàn.’ Àmọ́ Jèhófà yóò “kó [àwọn èèyàn rẹ̀] jọpọ̀.” Láti “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà” ni “ẹni tí yóò di olùṣàkóso Ísírẹ́lì” yóò ti wá.—Míkà 3:12; 4:12; 5:2.
Ṣé Jèhófà kò ṣe dáadáa sí Ísírẹ́lì ni? Ṣé àwọn òfin rẹ̀ ti le jù ni? Rárá o. Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ pé káwọn tó ń jọ́sìn òun ṣe kò ju pé kí wọ́n ṣe ‘ìdájọ́ òdodo, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà’ ní bíbá Ọlọ́run wọn rìn. (Míkà 6:8) Àmọ́ àwọn èèyàn ìgbà ayé Míkà ti di èèyànkéèyàn débi pé, “ẹni tí ó dára jù lọ nínú wọn dà bí ẹ̀gún ọ̀gàn, ẹni tí ó dúró ṣánṣán jù lọ nínú wọn burú ju ọgbà ẹ̀gún” tó máa ń gún ẹnikẹ́ni tó bá sún mọ́ ọn tí yóò sì dun ẹni náà. Àmọ́ wòlíì yìí béèrè pé: “Ta ni Ọlọ́run bí [Jèhófà]?” Ọlọ́run yóò tún fi àánú hàn sáwọn èèyàn rẹ̀ yóò sì “sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sínú ibú òkun.”—Míkà 7:4, 18, 19.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:12—Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa ‘kíkó àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Ísírẹ́lì jọpọ̀’ nímùúṣẹ? Ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ nímùúṣẹ nígbà táwọn Júù tó ṣẹ́ kù nígbèkùn Bábílónì padà sí ìlú wọn. Lóde òní, àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún ń nímùúṣẹ sára àwọn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16) Látọdún 1919 ni Ọlọ́run ti ń kó àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jọpọ̀ “bí agbo ẹran nínú ọgbà ẹran.” Níwọ̀n bí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó jẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” ti ń dara pọ̀ mọ́ wọn, pàápàá látọdún 1935, “ariwo” wọn wá pọ̀ gan-an. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Gbogbo wọn jọ ń fi tọkàntara ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́.
4:1-4—“Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà “ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” tó sì ń “mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá”? Àwọn gbólóhùn yìí, ìyẹn “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” àti “orílẹ̀-èdè alágbára ńlá” kò tọ́ka sáwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè tàbí àwọn olóṣèlú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn Jèhófà látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, làwọn gbólóhùn wọ̀nyí ń tọ́ka sí. Jèhófà ń ṣe ìdájọ́ ó sì tún ń mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti pé ó ń jẹ́ káwọn èèyàn wọ̀nyí ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú òun.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:6, 9; 3:12; 5:2. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ará Asíríà pa Samáríà run lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Míkà ṣì wà láàyè. (2 Àwọn Ọba 17:5, 6) Àwọn ará Asíríà tiẹ̀ dé Jerúsálẹ́mù nígbà tí Hesekáyà ń ṣàkóso lọ́wọ́. (2 Àwọn Ọba 18:13) Àwọn ará Bábílónì dáná sun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (2 Kíróníkà 36:19) Gẹ́gẹ́ bí Míkà ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ìlú “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà” ni wọ́n ti bí Mèsáyà. (Mátíù 2:3-6) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà máa ń nímùúṣẹ.
2:1, 2. Ó léwu gan-an ká máa sọ pé à ń sin Ọlọ́run àmọ́ kó jẹ́ pé lílé ọrọ̀ la fi ṣáájú wíwá “ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀.”—Mátíù 6:33; 1 Tímótì 6:9, 10.
3:1-3, 5. Jèhófà kò fẹ́ káwọn tó ń bójú tó àwọn èèyàn òun máa ṣojúsàájú.
3:4. Bá a bá fẹ́ kí Jèhófà máa dáhùn àwọn àdúrà wa, a ò gbọ́dọ̀ máa dẹ́ṣẹ̀ tàbí ká máa ṣe bíi pé olóòótọ́ èèyàn ni wá nígbà tó jẹ́ pé à ń ṣe ohun tí kò dára níkọ̀kọ̀.
3:8. Àyàfi tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà bá ràn wá lọ́wọ́ nìkan la fi lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tó gbé lé wa lọ́wọ́, títí kan kíkéde ìdájọ́ rẹ̀.
5:5. Àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí Mèsáyà yìí ń mú un dá wa lójú pé nígbà táwọn ọ̀tá bá dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò gbé “olùṣọ́ àgùntàn méje [tó dúró fún pípé pérépéré]” dìde, àti “mọ́gàjí mẹ́jọ,” ìyẹn ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọkùnrin tí wọ́n dáńgájíá, láti máa bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀.
5:7, 8. Gẹ́gẹ́ “bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,” ìyẹn ìbùkún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lóde òní ṣe jẹ́ sí ọ̀pọ̀ èèyàn. Ohun tó mú kí èyí rí bẹ́ẹ̀ ni pé Jèhófà ń lo àwọn ẹni àmì òróró láti máa kéde ọ̀rọ̀ Ìjọba rẹ̀. “Àwọn àgùntàn mìíràn” ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run nípa ṣíṣètìlẹyìn fáwọn ẹni àmì òróró lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Jòhánù 10:16) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ló jẹ́ fún wa pé a lè máa kópa nínú iṣẹ́ yìí, tó ń fún àwọn èèyàn ní ojúlówó ìtura!
6:3, 4. A gbọ́dọ̀ máa fara wé Jèhófà ká sì jẹ́ onínúure àti oníyọ̀ọ́nú kódà sáwọn tó ṣòro láti bá lò tàbí àwọn tí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà kò fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán.
7:7. Bá a ti ń kojú ìṣòro ní òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí, a ò gbọ́dọ̀ rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi ti Míkà, ńṣe ló yẹ ká “fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run” wa.
7:18, 19. Bí Jèhófà ti múra tán láti dárí àwọn àṣìṣe wa jì wá, ó yẹ káwa náà múra tán láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá.
“Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà” Títí Lọ
Àwọn tó ń bá Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀ jà ni a ó ‘ké kúrò fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ (Ọbadáyà 10) Àmọ́ Jèhófà lè dáwọ́ ìbínú rẹ̀ dúró bá a bá ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ rẹ̀ tá a sì ‘yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú.’ (Jónà 3:10) “Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ìyẹn ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tá a wà yìí, Ọlọ́run ń gbé ìjọsìn tòótọ́ ga ju gbogbo àwọn ìsìn èké lọ, àwọn èèyàn tó ń ṣègbọràn sì ń rọ́ wá sínú ìjọsìn tòótọ́. (Míkà 4:1; 2 Tímótì 3:1) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó máa “rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Míkà 4:5.
Ẹ ò rí i pé àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye ni ìwé Ọbadáyà, ìwé Jónà, àti ìwé Míkà kọ́ wa! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lẹ́gbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] ọdún tí wọ́n ti kọ wọ́n, síbẹ̀, ọ̀rọ̀ inú wọn “yè, ó sì ń sa agbára.”—Hébérù 4:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ọbadáyà sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “A ó ké [Édómù] kúrò fún àkókò tí ó lọ kánrin”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Míkà ‘fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Jèhófà,’ ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àǹfààní tó yẹ ká mọyì rẹ̀ ni iṣẹ́ ìwàásù jẹ́