Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Ń Rí Ìtura Lọ́dọ̀ Rẹ?
ÒKÈ Hámónì wà lápá gúúsù ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá tí wọ́n ń pè ní Òkè Anti-Lẹ́bánónì. Téńté Òkè Hámónì yìí, tó jẹ́ àgbàyanu, ga tó ẹgbẹ̀rìnlá ó lé mẹ́rìnlá [2,814] mítà láti ìtẹ́jú òkun. Lọ́pọ̀ ìgbà lọ́dún, ṣe ni yìnyín máa ń bo gbogbo orí ẹ̀. Èyí máa ń sọ atẹ́gùn olóoru tó ń fẹ́ gba orí òkè náà kọjá lóru di ìrì tó máa ń sẹ̀ sórí àwọn igi fir, àwọn igi eléso tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà, àtàwọn ọgbà àjàrà ìsàlẹ̀ òkè yẹn. Ìrì atura yìí ni olórí omi táwọn ewéko ń rí fà mu nígbà ẹ̀ẹ̀rùn tó máa ń gùn gan-an ní Ísírẹ́lì ayé àtijọ́.
Orin onísáàmù kan tí Jèhófà mí sí fi ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn tó ń sin Jèhófà wé “ìrì Hámónì tí ń sọ̀ kalẹ̀ sórí àwọn òkè ńlá Síónì.” (Sáàmù 133:1, 3) Bí ìrì atura ṣe ń sẹ̀ sórí àwọn ewéko láti orí Òkè Hámónì, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe lè máa mú ìtura bá àwọn èèyàn tá a bá jọ wà pọ̀. Báwo la ṣe lè ṣe èyí?
Ẹ Jẹ́ Ká Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
Ara máa ń tu àwọn èèyàn gan-an tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ Jésù Kristi. Kódà bó jẹ́ àkókò díẹ̀ léèyàn kàn lò lọ́dọ̀ rẹ̀ ara á tùùyàn ṣáá ni. Bí àpẹẹrẹ, Máàkù tó kọ ọ̀kan nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ pé: “[Jésù] gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.” (Máàkù 10:16) Inú àwọn ọmọ wọ̀nyẹn á mà dùn o!
Ní alẹ́ tí Jésù lò gbẹ̀yìn lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó dájú pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ á wú wọn lórí gan-an ni. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.” (Jòhánù 13:1-17) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó yẹ káwọn náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òye ohun tó ń wí kò yé àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tí wọ́n tún ń jiyàn lálẹ́ ọjọ́ yẹn nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn, Jésù kò bínú sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fi sùúrù la ohun tó ń wí yé wọn. (Lúùkù 22:24-27) Àní, “nígbà tí a ń kẹ́gàn [Jésù], kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà.” Kódà “nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” Ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa bó ṣe jẹ́ ẹni tó ń tuni lára.—1 Pétérù 2:21, 23.
Jésù ní: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” (Mátíù 11:29) Ẹ ò rí i pé ara máa tù wá gan-an tí Jésù bá fúnra rẹ̀ kọ́ wa. Nígbà táwọn ará ìlú rẹ̀ gbọ́ bó ṣe ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, ẹnu yà wọ́n gan-an débi pé wọ́n ní: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí ọgbọ́n yìí àti àwọn iṣẹ́ agbára wọ̀nyí?” (Mátíù 13:54) Tá a bá kà ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, a óò rí ẹ̀kọ́ kọ́ dáadáa nípa bá a ṣe lè jẹ́ ẹni tí ìwà rẹ̀ ń tuni lára. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ ní ti ká sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró àti ká ṣe tán láti ranni lọ́wọ́.
Máa Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
Ó rọrùn láti wólé ju kéèyàn kọ́lé lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rọrùn fọ́mọ èèyàn láti bani jẹ́ ju kí wọ́n gbéni ró lọ. Níwọ̀n bí àwa èèyàn ti jẹ́ aláìpé, gbogbo wa la ní kùdìẹ̀-kudiẹ. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (Oníwàásù 7:20) Kì í pẹ́ ká tó rí àṣìṣe ọmọnìkejì wa, tá a ó sì wá fẹnu ba onítọ̀hún jẹ́. (Sáàmù 64:2-4) Àmọ́ ó máa ń gba ìsapá gan-an ká tó lè jẹ́ni tó ń sọ̀rọ̀ tó gbéni ró.
Ńṣe ni Jésù máa ń fọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ gbéni ró. Ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn láti mú kí ara tù wọ́n. (Lúùkù 8:1) Jésù tún sọ irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ ọ̀run jẹ́ fáwọn tó di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti fi mú ìtura bá wọn. (Mátíù 11:25-27) Abájọ táwọn èèyàn ṣe máa ń fẹ́ wà lọ́dọ̀ Jésù ṣáá!
Ṣùgbọ́n ní tàwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí, àwọn ò tiẹ̀ fẹ́ mọ̀ bóyá nǹkan kan ń ṣe ẹnikẹ́ni. Jésù ní: “Wọ́n fẹ́ ibi yíyọrí ọlá jù lọ níbi oúnjẹ alẹ́ àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù.” (Mátíù 23:6) Ńṣe ni wọ́n ń fojú pa àwọn mẹ̀kúnnù rẹ́, wọ́n á ní: “Ogunlọ́gọ̀ yìí tí kò mọ Òfin jẹ́ ẹni ègún.” (Jòhánù 7:49) Ìwà wọn àti ìṣe wọn ò tuni lára rárá!
Ọ̀rọ̀ ẹnu wa sábà máa ń fi irú èèyàn tá a jẹ́, àtojú tá a fi ń wo àwọn ẹlòmíì hàn. Jésù ní: “Ẹni rere a máa mú ohun rere jáde wá láti inú ìṣúra rere ọkàn-àyà rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni burúkú a máa mú ohun tí í ṣe burúkú jáde wá láti inú ìṣúra burúkú rẹ̀; nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Lúùkù 6:45) Kí la wá lè ṣe kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè máa tu àwọn èèyàn lára?
Ọ̀kan nínú ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká máa ronú ká tó sọ̀rọ̀. Òwe 15:28 ní: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” Àṣàrò tíbí yìí ń sọ ò fi dandan jẹ́ èyí tó máa pẹ́ lọ títí o. Tá a bá ronú díẹ̀ ká tó sọ̀rọ̀, a lè mọ bọ́rọ̀ náà ṣe máa rí lára ẹni tá a fẹ́ sọ ọ́ sí. A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ ni ohun tí mo fẹ́ sọ yìí? Ṣóòótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, àbí àgbọ́sọ lásán? Ṣé “ọ̀rọ̀ tí ó sì bọ́ sí àkókò” ni? Ṣó máa tu àwọn tí mo fẹ́ sọ ọ́ fún lára, ṣó sì máa gbé wọn ró?’ (Òwe 15:23) Tá a bá rò ó lọ rò ó bọ̀ tá a rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn ò dáa tó, tàbí pé kò bójú mu lásìkò yẹn, ńṣe ni ká yáa mú un kúrò lọ́kàn wa pátápátá. Ohun tó tiẹ̀ wá dáa jù ni pé ká kúkú gbìyànjú láti fi èrò tó dáa tó sì gbéni ró rọ́pò èrò tí ò dáa yẹn. Nítorí pé ńṣe lọ̀rọ̀ téèyàn bá sọ láìronú máa ń dà bí “àwọn ìgúnni idà,” àmọ́ ohun “ìmúniláradá” lọ̀rọ̀ rere máa ń jẹ́.—Òwe 12:18.
Ohun tó tún máa ṣèrànlọ́wọ́ ni pé ká máa ronú nípa ohun tó mú káwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Jèhófà rí àwọn ànímọ́ tó dáa lára olúkúlùkù ìránṣẹ́ rẹ̀, àní títí kan àwọn táwa tiẹ̀ lè kà sí ẹni tó le lẹ́dàá. Tá a bá ń gbìyànjú láti mọ ibi tí wọ́n dáa sí, a ó máa rí nǹkan tó dáa sọ nípa wọn.
Máa Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́
Jésù mọ bí ìnira àwọn èèyàn tí wọ́n tẹ̀ lórí ba ṣe tó. Àní, “nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Kì í ṣe pé Jésù kàn mọ ìnira wọn lára nìkan, ó ṣe nǹkan kan láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó pè wọ́n, ó ní: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.” Ó sì tún fi dá wọn lójú pé: “Àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28, 30.
“Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé lóde òní. (2 Tímótì 3:1) “Àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí” ti di òkè ìṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn. (Mátíù 13:22) Ìṣòro táwọn ẹlòmíì ní ti wọ̀ wọ́n lọ́rùn gan-an. (1 Tẹsalóníkà 5:14) Báwo la ṣe lè mú kí ara tu àwọn tó níṣòro? A lè ṣe bíi ti Kristi, ká mú ẹrù wọn fúyẹ́.
Àwọn kan máa ń fẹ́ láti sọ ìṣòro wọn fáwọn ẹlòmíì kí ara lè tù wọ́n. Báwọn tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá wá sọ́dọ̀ wa fún ìrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ a máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí gbọ́ wọn? Ó gba ìkóra-ẹni-níjàánu kéèyàn tó lè fẹ̀mí ìgbatẹnirò tẹ́tí gbọ́ni. Ó gba pé ká máa fọkàn bá ohun tónítọ̀hún ń sọ lọ dípò ká máa ronú nípa bá a ṣe máa fèsì tàbí bá a ṣe máa yanjú ìṣòro rẹ̀. Tá a bá tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, tá à ń wojú ẹni tó ń sọ̀rọ̀, torí pé ojú lọ́rọ̀ wá, tá a sì ń dáhùn bó ṣe yẹ, ìyẹn á fi hàn pé a ń ṣaájò wọn.
Nínú ìjọ, a ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti gba àwọn ará wa níyànjú. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wá sípàdé, ká lọ kí àwọn tára wọn ò le. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tá a máa ṣe láti fi gbé wọn ró kò ju pé ká lo ìṣẹ́jú mélòó kan ṣáájú tàbí lẹ́yìn ìpàdé láti fi fún wọn níṣìírí. A tún lè ṣàkíyèsí àwọn tá a jọ wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan náà tí wọn ò wá. A lè pè wọ́n lórí tẹlifóònù láti béèrè àlàáfíà wọn, ká sì ṣèrànlọ́wọ́ tó bá yẹ fún wọn.—Fílípì 2:4.
Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn alàgbà ń ṣe nínú ìjọ. A lè mú kí iṣẹ́ wọn dín kù gan-an tá a bá bá wọn fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tá a sì ń ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” (Hébérù 13:17) Tá a bá lẹ́mìí ìfọwọ́sowọ́pọ̀, a lè mú kí ara tu àwọn “tí ń ṣe àbójútó lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”—1 Tímótì 5:17.
Máa Sọ̀rọ̀ Tó Tuni Lára Kó O sì Máa Ranni Lọ́wọ́
Ọ̀kẹ́ àìmọye omi tíntìntín tó ń sẹ̀ látojú ọ̀run, tá a fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máà ríbi tó ti ń wá, ló ń di ìrì atura. Bákan náà, híhùwà bíi Kristi nígbà gbogbo máa ń fún àwọn èèyàn nítura ju pé ká kàn wá nǹkan ńlá ṣe fún wọn lọ.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Ẹ jẹ́ ká fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò, ká rí i dájú pé à ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣe wa mú kí ara tu ọmọnìkejì wa.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìrì láti Òkè Hámónì jẹ́ omi atura fáwọn ewéko
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹni tó ń fẹ̀mí ìgbatẹnirò tẹ́tí gbọ́ni ń mú kí ara tu ọmọnìkejì rẹ̀