ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 9/1 ojú ìwé 3
  • Ṣé Ọlọ́run Ṣèlérí fún Ẹ Pé Wàá Dọlọ́rọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ọlọ́run Ṣèlérí fún Ẹ Pé Wàá Dọlọ́rọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojúlówó Aásìkí Ń Bọ̀ Nínú Ayé Tuntun ti Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ta Ni Ábúráhámù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ǹjẹ́ Jíjẹ́ Ọlọ́rọ̀ Ló Ń Fi Hàn Pé Èèyàn ní Ìbùkún Ọlọ́run?
    Jí!—2003
  • Jèhófà Pè É Ní “Ọ̀rẹ́ Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 9/1 ojú ìwé 3

Ṣé Ọlọ́run Ṣèlérí fún Ẹ Pé Wàá Dọlọ́rọ̀?

‘Ọlọ́run fẹ́ kó o lọ́rọ̀, kó o ní mọ́tò rẹpẹtẹ, kí iṣẹ́ ajé ẹ sì máa gbòòrò sí i. Ìwọ ṣáà ti gbẹ́kẹ̀ lé e, tọwọ́ bàpò, kó o sì fún un ní gbogbo owó tó o bá lè fún un.’

ÌWÉ ìròyìn kan tí wọ́n ń tẹ̀ lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé irú ìwàásù bí èyí làwọn ìsìn kan lórílẹ̀-èdè Brazil sábà máa ń ṣe. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì nirú ìwàásù yìí máa ń wọ̀ lọ́kàn. Nígbà tí ìwé ìròyìn Time ń sọ̀rọ̀ lórí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láàárín àwọn tó pera wọn ní Kristẹni, ó sọ pé: “Èèyàn tó lé ní mẹ́fà nínú mẹ́wàá ló gbà gbọ́ pé Ọlọ́run fẹ́ kéèyàn rí towó ṣe. Àwọn tó sì lé ní mẹ́ta nínú mẹ́wàá gbà pé téèyàn bá fún Ọlọ́run lówó, Ọlọ́run máa bù kún onítọ̀hún pẹ̀lú owó rẹpẹtẹ.”

Àwọn tó nírú èrò yìí ni wọ́n sábà máa ń pè ní àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tó gbà gbọ́ pé dandan ni kéèyàn dọlọ́rọ̀, wọ́n sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i káàkiri pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè Látìn Amẹ́ríkà, bí orílẹ̀-èdè Brazil. Àwọn èèyàn sì máa ń rọ́ lọ sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó máa ń kọ́ni pé Ọlọ́run ṣèlérí ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì fáwọn èèyàn. Àmọ́, ṣé òótọ́ ni pé Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn tó ń sin òun máa dọlọ́rọ̀? Ṣé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́ ló ní ọrọ̀?

Lóòótọ́, nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, a sábà máa ń rí i pé àwọn tí Ọlọ́run bá bù kún máa ń ní ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Bí àpẹẹrẹ, Diutarónómì 8:18 kà pé: “Ìwọ sì gbọ́dọ̀ rántí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nítorí òun ni ẹni tí ó fi agbára fún ọ láti ní ọlà.” Èyí fàwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kàn balẹ̀ pé tí wọ́n bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ó máa bù kún wọn.

Ẹnì kọ̀ọ̀kan ńkọ́? Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ lọ́rọ̀ gan-an, ìgbà tí Sátánì sì jẹ́ kó pàdánù gbogbo nǹkan tó ní, Jèhófà dá ọrọ̀ tí Jóòbù ní pa dà “ní ìlọ́po méjì.” (Jóòbù 1:3; 42:10) Ábúráhámù náà lọ́rọ̀. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 13:2 sọ pé ó “ní ọ̀pọ̀ wọ̀ǹtìwọnti ọ̀wọ́ ẹran àti fàdákà àti wúrà.” Nígbà táwọn ọmọ ogun àwọn ọba mẹ́rin láti Ìlà Oòrùn mú Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí Ábúráhámù, Ábúráhámù “pe àwọn ọkùnrin tí ó ti kọ́ jọ, ọ̀ọ́dúnrún lé méjìdínlógún ẹrú tí a bí ní agbo ilé rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:14) Àwọn ọ̀ọ́dúnrún lé méjìdínlógún [318] “ọkùnrin tí ó ti kọ́” tí wọ́n lè lo nǹkan ìjà ogun fi hàn pé àwọn èèyàn tó wà nílé Ábúráhámù máa pọ̀ gan-an. Bí Ábúráhámù ṣe ń gbọ́ bùkátà àwọn èèyàn tó pọ̀ tó báyìí fi hàn pé ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ débi pé ó tún ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran.

Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́ bí Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù, Dáfídì àti Sólómọ́nì jẹ́ ọlọ́rọ̀. Àmọ́, ṣé ìyẹn wá fi hàn pé Ọlọ́run máa sọ gbogbo ẹni tó bá ń sìn ín di ọlọ́rọ̀? Yàtọ̀ síyẹn, ṣé torí pé ẹnì kan jẹ́ òtòṣì wá túmọ̀ sí pé inú Ọlọ́run ò dùn sí onítọ̀hún? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́