ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 12/1 ojú ìwé 8-9
  • Kò Ní Sí Àjálù Mọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kò Ní Sí Àjálù Mọ́!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni O Ní Láti Ṣe?
  • Àjálù—Kí Nìdí Tó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Fi Hàn Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Ọlọrun Ni Ó Ha Ń Fà Á Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 12/1 ojú ìwé 8-9

Kò Ní Sí Àjálù Mọ́!

BÁWO ló ṣe máa rí lára rẹ tí ẹnì kan bá sọ fún ẹ pé, “Láìpẹ́ kì yóò sí àjálù mọ́”? Ó ṣeé ṣe kí o sọ pé, “Àbí ò ń lálàá ni? Ìyẹn kò lè ṣẹlẹ̀ láéláé.” Tàbí kẹ̀, o lè rò ó lọ́kàn rẹ pé, ‘Ta ló rò pé òun ń tàn jẹ?’

Bó tilẹ̀ dà bíi pé àjálù kò lè dópin láyé yìí, ẹ̀rí tó dájú wà tó fi yẹ ká ní ìrètí pé ó máa dópin. Àmọ́ kì í ṣe àwọn èèyàn ló máa fòpin sí àjálù. Ìdí ni pé, kò sí bí àwọn èèyàn ṣe lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa bí àwọn àjálù ṣe ń wáyé àti ìdí tí wọ́n fi ń wáyé, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé wọ́n máa mọ bí wọ́n ṣe máa kápá rẹ̀. Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì àtijọ́ tí ó ní ọgbọ́n, tí ó sì ní àkíyèsí tó kàmàmà sọ pé: “Mo sì rí gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, bí aráyé kò ti lè rídìí iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn; bí ó ti wù kí aráyé máa bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ kárakára púpọ̀ tó láti wá a, síbẹ̀ wọn kò rídìí rẹ̀. Bí wọ́n sì tilẹ̀ sọ pé wọ́n gbọ́n tó láti mọ̀, wọn kò ní lè rídìí rẹ̀.”—Oníwàásù 8:17.

Bí aráyé kò bá lè kápá àjálù, ta ló lè kápá rẹ̀? Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá wa ni ẹni tó máa fòpin sí àjálù. Òun ló ṣètò àwọn nǹkan tó wà ní ayé, irú bí oòrùn ṣe máa ń fa omi lọ sókè, tí á sì tún wá rọ̀ sórí ilẹ̀ ayé. (Oníwàásù 1:7) Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín Ọlọ́run àti èèyàn, nítorí agbára Ọlọ́run kò ní ààlà. Wòlíì Jeremáyà jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Kíyè sí i, ìwọ fúnra rẹ ni ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé nípa agbára ńlá rẹ àti nípa apá rẹ nínà jáde. Gbogbo ọ̀ràn náà kò ṣe àgbàyanu jù fún ọ.” (Jeremáyà 32:17) Nítorí pé Ọlọ́run ló dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé ó mọ bí ó ṣe máa bójú tó àwọn nǹkan náà kí àwọn èèyàn lè máa gbé inú ayé ní àlàáfíà àti ààbò.—Sáàmù 37:11; 115:16.

Báwo wá ni Ọlọ́run ṣe máa mú àyípadà yìí wá? Wàá rántí pé àpilẹ̀kọ kejì nínú ọ̀wọ́ yìí, mẹ́nu bà á pé àwọn ohun abanilẹ́rù tó ń ṣẹlẹ̀ láyé lónìí jẹ́ “àmì” tó fi hàn pé a wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.” (Mátíù 24:3; Lúùkù 21:31) Ìjọba Ọlọ́run, tó jẹ́ ìjọba ti ọ̀run látọwọ́ Ọlọ́run, yóò mú àyípadà ńlá wá sórí ilẹ̀ ayé, àní ó máa kápá ẹ̀fúùfù àtàwọn nǹkan míì tó lè fa àjálù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ní agbára láti ṣe nǹkan yìí fúnra rẹ̀, síbẹ̀ ó ti gbé iṣẹ́ náà lé Ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Wòlíì Dáníẹ́lì sọ nípa Ọmọ náà pé: “A sì fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.”—Dáníẹ́lì 7:14.

Ọlọ́run ti fún Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ní agbára tí ó nílò láti yí àwọn nǹkan pa dà kí ayé yìí lè di ibi tó dára láti gbé. Ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn ní ráńpẹ́ pé òun ní agbára láti kápá àwọn ìṣẹ̀dá. Nígbà kan, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà nínú ọkọ̀ lórí Òkun Gálílì, “ìjì ẹlẹ́fùúùfù ńlá lílenípá kan bẹ́ sílẹ̀, ìgbì sì ń rọ́ wọnú ọkọ̀ ojú omi ṣáá, tó bẹ́ẹ̀ tí omi fi fẹ́rẹ̀ẹ́ bo ọkọ̀ ojú omi náà mọ́lẹ̀.” Àyà àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ já. Wọ́n lọ bá Jésù, nítorí ẹ̀rù ń bà wọ́n pé àwọ́n lè ṣègbé. Kí ni Jésù ṣe? Ó “bá ẹ̀fúùfù náà wí lọ́nà mímúná, ó sì wí fún òkun náà pé: ‘Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!’ Ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.” Ẹnu ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gan-an, wọ́n sì béèrè pé: “Ta nìyí ní ti gidi, nítorí ẹ̀fúùfù àti òkun pàápàá ń ṣègbọràn sí i?”—Máàkù 4:37-41.

Àmọ́ lẹ́yìn ìgbà tí Ọlọ́run gbé Jésù ga sí òkè ọ̀run, ó fún un ní agbára àti àṣẹ tó pọ̀ sí i. Nítorí pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, òun ló máa ṣe gbogbo àyípadà tó yẹ láti mú káwọn èèyàn ní àlááfíà àti ààbò lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ní agbára láti ṣe é.

Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i, ọ̀pọ̀ ìṣòro àtàwọn àjálù yìí ló jẹ́ àfọwọ́fà ẹ̀dá èèyàn, ìgbà míì sì rèé, ìmọtara ẹni nìkan àti ìwọra àwọn èèyàn ló túbọ̀ ń mú kó burú. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún àwọn tí kò jáwọ́ nínú irú ìwà búburú yìí? Bíbélì sọ nípa ìgbà tí Jésù Olúwa ń bọ̀ “láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” Ó dájú pé ó máa “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—2 Tẹsalóníkà 1:7, 8; Ìṣípayá 11:18.

Jésù Kristi tó jẹ́ “Ọba àwọn ọba,” yóò lo agbára rẹ̀ láti kápá àwọn ìṣẹ̀dá tó lè fa àjálù. (Ìṣípayá 19:16) Yóò rí i dájú pé àjálù kò ní bá àwọn tó wà lábẹ́ Ìjọba náà. Yóò lo agbára rẹ̀ láti ṣàkóso àwọn ohun tó jẹ mọ́ ojú ọjọ́ àti àwọn àyípoyípo ìgbà kí àwọn nǹkan yìí lè máa ṣe aráyé láǹfààní. Èyí á jẹ́ àbájáde ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Dájúdájú, èmi yóò fún yín ní ọ̀wààrà òjò ní àkókò rẹ̀ tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu, ilẹ̀ yóò sì mú èso rẹ̀ wá ní ti gidi, igi pápá yóò sì fi èso rẹ̀ fúnni.” (Léfítíkù 26:4) Àwọn èèyàn á lè kọ́lé láìní máa bẹ̀rù pé àjálù kan lè bà á jẹ́, Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.”—Aísáyà 65:21.

Kí Ni O Ní Láti Ṣe?

Kò sí àní-àní pé bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn, á wù ọ́ láti gbé nínú ayé kan tí kò ní sí àjálù mọ́. Àmọ́, kí lo ní láti ṣe kí o lè wà níbẹ̀? Nígbà tó jẹ́ pé “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run” àti “àwọn tí kò ṣe ìgbọ́ràn sí ìhìn rere” kò ní gbé nínú ayé tó ń bọ̀, nínú èyí tí àjálù kò ní sí mọ́, ó ṣe kedere pé, ní báyìí èèyàn ní láti mọ̀ nípa Ọlọ́run, kí èèyàn sì ṣe àtìlẹ́yìn fún ètò tó ṣe láti ṣàkóso ayé. Ọlọ́run ń fẹ́ kí á mọ òun kí á sì ṣègbọràn sí ìhìn rere Ìjọba tó ti gbé kalẹ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀.

Ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà ṣe èyí ni pé, kí èèyàn máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bíbélì ní àwọn ẹ̀kọ́ tó máa mú kí èèyàn di ẹni tó lè gbé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ní àyíká tí kò ní sí ewu. O ò ṣe ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè mọ ohun tí Bíbélì kọ́ni? Wọ́n ti múra tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ohun kan tó dájú ni pé, tó o bá sapá láti mọ Ọlọ́run àti láti ṣègbọràn sí ìhìn rere, nígbà náà ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe 1:33 yóò ṣẹ sí ẹ lára, ó ní: “Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́