Rírí Ayọ̀ Látinú Fífúnni Lẹ́bùn
“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—ÌṢE 20:35.
Ìdí tí àwọn kan fi ń ṣe ọdún Kérésìmesì.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí fi hàn pé tẹ́nì kan bá fúnni lẹ́bùn, àtẹni tó fúnni lẹ́bùn àtẹni tó gbà á ló máa ń láyọ̀. Ọ̀pọ̀ tó mọ̀ pé ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń fúnni láyọ̀, tí wọ́n sì fẹ́ ní ayọ̀ yẹn, ka fífúnni ní ẹ̀bùn sí ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó yẹ kéèyàn ṣe nígbà Kérésìmesì. Kódà ìwádìí kan fi hàn pé ní ọdún tó kọjá nígbà tí ọrọ̀ ajé tiẹ̀ dẹnu kọlẹ̀, ìdílé kọ̀ọ̀kan nílẹ̀ Ireland ṣì fẹ́ ná iye tí ó tó ₦102,300 lórí ẹ̀bùn Kérésì tí wọ́n máa fúnni.
Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn?
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé wàhálà fífúnni ní ẹ̀bùn nígbà Kérésì pọ̀ ju ayọ̀ tó yẹ kó máa fúnni lọ. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Wọ́n rí i pé ó máa ń di dandan kí àwọn náwó kọjá bí àwọn ṣe rò lọ lórí ẹ̀bùn tí wọ́n fẹ́ fúnni. Àti pé, torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ ra ẹ̀bùn lásìkò kan náà, èrò tó máa ń wọ́ tìrítìrí àti ìlà gígùn tó máa ń wà láwọn ilé ìtajà máa ń mú kí ọjà rírà pin wọ́n lẹ́mìí.
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè tọ́ni sọ́nà?
Jésù sọ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà.”a (Lúùkù 6:38) Jésù kò sọ pé ìgbà kan pàtó láàárín ọdún ló yẹ ká máa fúnni lẹ́bùn, tí àwọn èèyàn á sì máa retí láti gba ẹ̀bùn. Ṣe ló rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ kó mọ́ wọn lára láti máa fúnni ní ẹ̀bùn nígbàkigbà tí ọkàn wọn bá sún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀.
“Kí olukuluku ṣe bí ó bá ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀; kì í ṣe pẹlu ìkanra, tàbí àfipáṣe, nitori onínúdídùn ọlọ́rẹ ni Ọlọ́run fẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 9:7, Ìròhìn Ayọ̀) Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé kókó inú ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù yìí ni pé “èèyàn kò gbọ́dọ̀ máa fúnni lẹ́bùn lábẹ́ ‘àfipáṣe’ tàbí kéèyàn máa rò pé wọ́n kàn án nípá fún òun láti fúnni lẹ́bùn.” Téèyàn bá jẹ́ “onínúdídùn ọlọ́rẹ” kò ní wò ó pé àwọn kan lòun gbọ́dọ̀ fún ní àwọn ẹ̀bùn kan pàtó ní àsìkò kan pàtó láàárín ọdún, bó ṣe sábà máa ń rí nígbà ọdún Kérésì.
“Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.” (2 Kọ́ríńtì 8:12) Ọlọ́run kò retí pé kí Kristẹni kankan jẹ gbèsè torí pé ó fẹ́ fúnni ní ẹ̀bùn olówó ńlá. Kàkà bẹ́ẹ̀ tí ẹnì kan bá fúnni lẹ́bùn ‘ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó ní,’ kò ní ka ẹ̀bùn tó ń fúnni sí ìnira, ṣe ni yóò jẹ́ ohun tó “ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì” lójú Ọlọ́run. Èyí tuni lára, ó sì yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí àwọn oníṣòwò máa ń fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe tí wọ́n fi máa ń ti ọjà síni lọ́rùn lásìkò ọdún. Wọ́n á ní kéèyàn rà á nísìnyí, kó wá sanwó tó bá yá!
a Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan kàn sọ pé “Ẹ fifun ni.” Ṣùgbọ́n nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ ìṣe tí wọ́n lò fi hàn pé ohun kan tó ń bá a lọ láìdáwọ́ dúró ni. Láti lè gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye ọ̀rọ̀ tí Jésù lò yọ, Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun túmọ̀ rẹ̀ báyìí pé, “Ẹ sọ fífúnni dàṣà.”