ÌJÍRÒRÒ LÁÀÁRÍN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ÀTI ẸNÌ KAN
Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀?—Apá 1
Ìjíròrò tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Kọ́lá lọ sí ilé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tádé.
MÁA “BÁ A NÌṢÓ NÍ WÍWÁ” ÒYE
Kọ́lá: Tádé, mo máa ń gbádùn bá a ṣe jọ máa ń jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì.a Nígbà tá a jọ sọ̀rọ̀ gbẹ̀yìn, o bi mí ní ìbéèrè kan nípa Ìjọba Ọlọ́run. Rántí pé o béèrè ìdí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀.
Tádé: Bẹ́ẹ̀ ni. Inú ìwé yín kan ni mo ti kà á pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀. Ọ̀rọ̀ yẹn rú mi lójú torí pé ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí máa ń sọ pé gbogbo ohun tẹ́ ẹ gbà gbọ́ ló wà nínú Bíbélì.
Kọ́lá: Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí Bíbélì bá sọ la gbà gbọ́.
Tádé: Ó dáa, èmi fúnra mi ti ka Bíbélì látòkè délẹ̀, mi ò sì rò pé mo rí ohun tó jọ ọdún 1914 níbẹ̀. Mo tún lọ ṣí Bíbélì orí íńtánẹ́ẹ̀tì, mo sì ní kó wá ọdún 1914 jáde fún mi, ṣùgbọ́n èsì tó fún mi ni pé “kò sí ohun tó jọ ọ́.”
Kọ́lá: Ohun tó o ṣe yẹn wú mi lórí púpọ̀. Èyí tó kọ́kọ́ dùn mọ́ mi ni pé, o ka Bíbélì látòkè délẹ̀! Ìyẹn fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an.
Tádé: Bẹ́ẹ̀ ni, torí kò sí ìwé míì tó dà bíi rẹ̀.
Kọ́lá: Mo gbà bẹ́ẹ̀. Ohun kejì tó wú mi lórí ni pé, inú Bíbélì lo lọ tààràtà nígbà tí ò ń wá ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbà wá níyànjú ká ṣe gan-an nìyẹn, ó ní ká máa “bá a nìṣó ní wíwá” òye.b Ó dáa bó o ṣe ń sapá láti wá òye yìí.
Tádé: Ẹ ṣé gan-an. Ó wù mí kí n tún mọ̀ sí i. Kódà, ibi tí mo tún ti ń ṣèwádìí ni mo ti rí àwọn ìsọfúnni kan nípa ọdún 1914 nínú ìwé tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Ó sọ̀rọ̀ nípa ọba kan tó lálàá, ó rí igi ńlá kan tí wọ́n gé lulẹ̀, àmọ́ igi ọ̀hún tún hù pa dà, wọ́n ṣáà ṣe àlàyé yẹn bákan ṣá.
Kọ́lá: O ti gbìyànjú gan-an. Inú ìwé Dáníẹ́lì orí kẹrin ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn wà. Ó sọ nípa àlá tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lá.
Tádé: Ìyẹn gan-an ni mò ń sọ. Mo ka àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní àkàtúnkà, síbẹ̀, mi ò rí ohun tó jọ Ìjọba Ọlọ́run tàbí ọdún 1914 nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà.
Kọ́lá: Ká sòótọ́, wòlíì Dáníẹ́lì gan-an ò ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ohun tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ̀ láti kọ nígbà yẹn!
Tádé: Ṣé lóòótọ́?
Kọ́lá: Bẹ́ẹ̀ ni. Wòlíì yẹn sọ nínú ìwé Dáníẹ́lì 12:8 pé: “Wàyí o, ní tèmi, mo gbọ́, ṣùgbọ́n èmi kò lóye.”
Tádé: Àṣé a tiẹ̀ pọ̀ ńbẹ̀.
Kọ́lá: Òótọ́ ibẹ̀ ni pé wòlíì Dáníẹ́lì ò lóye àsọtẹ́lẹ̀ yẹn torí pé kò tíì tó àkókò lójú Ọlọ́run fún àwa èèyàn láti mọ ìtúmọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì. Àmọ́ a lè lóye wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lónìí.
Tádé: Kí nìdí tẹ́ ẹ fi sọ bẹ́ẹ̀?
Kọ́lá: Ó dáa, wo ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 12:9. Ó sọ pé: “A ṣe ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, a sì fi èdìdì dì í títí di àkókò òpin.” Èyí fi hàn pé, ó di “àkókò òpin” kí àwọn èèyàn tó lóye àsọtẹ́lẹ̀ náà. Bí a ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lọ, a ṣì máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àkókò òpin yẹn gan-an la wà yìí.c
Tádé: Ó dáa, ṣé ẹ lè ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì fún mi?
Kọ́lá: Màá gbìyànjú.
ÀLÁ TÍ NEBUKADINÉSÁRÌ ỌBA LÁ
Kọ́lá: Ká tó bẹ̀rẹ̀, jẹ́ kí n kọ́kọ́ mẹ́nu ba díẹ̀ lára ohun tí Nebukadinésárì Ọba rí nínú àlá rẹ̀, lẹ́yìn náà, àá wá sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àlá yẹn túmọ̀ sí.
Tádé: Ó dáa.
Kọ́lá: Nínú àlá yẹn, Nebukadinésárì rí igi ràgàjì kan tó ga dé ọ̀run. Ó gbọ́ tí ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n gé igi náà lulẹ̀, àmọ́ Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀ nínú ilẹ̀. Lẹ́yìn tí “ìgbà méje” bá ti kọjá, igi náà á hù pa dà.d Nebukadinésárì Ọba ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ sí lára. Ọba tó lókìkí ni Nebukadinésárì, a lè fi ipò ọba rẹ̀ wé igi tó ga dé ọ̀run, àmọ́, wọ́n ké e lulẹ̀ fún “ìgbà méje.” Ǹjẹ́ o rántí ohun tó ṣẹlẹ̀?
Tádé: Rárá, mi ò rántí.
Kọ́lá: Kò burú. Bíbélì jẹ́ ká lóye pé orí Nebukadinésárì dà rú fún ọdún méje. Láàárín àkókò yẹn, kò lè ṣàkóso gẹ́gẹ́ bi ọba. Àmọ́, lẹ́yìn ọdún méje yẹn, orí rẹ̀ pé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso pa dà.e
Tádé: Gbogbo ohun tẹ́ ẹ ti ń sọ bọ̀ ló yé mi. Ṣùgbọ́n, báwo ni gbogbo ẹ̀ ṣe tan mọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti ọdún 1914?
Kọ́lá: Ní kúkúrú, ìtumọ̀ méjì ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní. Àkọ́kọ́ ṣẹ sára Nebukadinésárì ọba nígbà tí orí rẹ̀ dà rú, tí kò sì lè ṣàkóso mọ́. Ìmúṣẹ kejì wáyé nígbà tí ìṣàkóso Ọlọ́run dáwọ́ dúró. Ìmúṣẹ kejì yìí gan-an ló tan mọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
Tádé: Báwo lẹ ṣe mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún ní ìtumọ̀ míì tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run?
Kọ́lá: Lákọ̀ọ́kọ́, ohun kan wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tó fi hàn pé ó ní ìtumọ̀ míì. Ohun tí ìwé Dáníẹ́lì 4:17 sọ ni pé àsọtẹ́lẹ̀ náà wà “fún ète pé kí àwọn ènìyàn tí ó wà láàyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́, ni ó ń fi í fún.” Ǹjẹ́ o kíyè sí gbólóhùn náà “ìjọba aráyé”?
Tádé: Bẹ́ẹ̀ ni, ibẹ̀ yẹn sọ pé, “Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé.”
Kọ́lá: O ṣeun. Ta wá ni “Ẹni Gíga Jù Lọ” yẹn?
Tádé: Ọlọ́run ló yẹ kó jẹ́, àbí?
Kọ́lá: O jánà. Ìyẹn fi hàn pé Nebukadinésárì nìkan kọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ náà kàn, ó tún kan “ìjọba aráyé,’ ìyẹn ìṣàkóso Ọlọ́run lórí aráyé. Tá a bá wo ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń bá bọ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn àtàwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e, wàá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu tá a bá ronú bẹ́ẹ̀.
Tádé: Kí lẹ ní lọ́kàn?
OHUN TÍ ÌWÉ NÁÀ DÁ LÉ
Kọ́lá: Ohun kan wà tí ìwé Dáníẹ́lì dá lé. Ìyẹn ni bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa bẹ̀rẹ̀, tí Ọlọ́run sì máa lo Jésù láti ṣàkóso. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká wo àwọn orí tó ṣáájú nínú ìwé Dáníẹ́lì yẹn. Jọ̀wọ́, ka ìwé Dáníẹ́lì 2:44.
Tádé: Mo ti débẹ̀. Ó kà pé: “Àti pé ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”
Kọ́lá: Mo gbádùn bó o ṣe ka ìwé yẹn. Ǹjẹ́ o rò pé Ìjọba Ọlọ́run ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń tọ́ka sí?
Tádé: Ẹn-ẹn, kò dá mi lójú.
Kọ́lá: Ó dáa. Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yẹn ní Ìjọba yẹn ‘yóò dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè dúró fún àkókò tí ó lọ kanrin, kò sí ìjọba èèyàn kankan tó lẹ́mìí ẹ̀. Àbí ó wà?
Tádé: Rára. Mi ò rò bẹ́ẹ̀.
Kọ́lá: Àsọtẹ́lẹ̀ míì tún wà nínú ìwé Dáníẹ́lì tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Inú ìwé Dáníẹ́lì 7:13, 14 ló wà. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ̀rọ̀ nípa alákòóso kan tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó ní: ‘A ò fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sìn ín. Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.’ Kí lo rí nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó jọra pẹ̀lú ohun tá a ti ń sọ bọ̀?
Tádé: Ẹsẹ Bíbélì yìí náà mẹ́nu kan ìjọba kan.
Kọ́lá: Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé o kíyè sí i pé kì í kàn-án ṣe ìjọba kan ṣá. Bíbélì yẹn sọ pé Ìjọba yẹn máa ní ọlá àṣẹ lórí “àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè.” Lẹ́nu kan, Ìjọba náà máa ṣàkóso kárí ayé.
Tádé: Mí ò ronú débẹ̀ yẹn, àmọ́ òótọ́ lẹ sọ. Ohun tó sọ náà nìyẹn.
Kọ́lá: Ṣé o rántí pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún sọ pé: “Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.” Tó o bá wò ó dáadáa, wàá rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí jọ èyí tá a kà nínú ìwé Dáníẹ́lì 2:44. Àbí?
Tádé: Ó jọra lóòótọ́.
Kọ́lá: Ní báyìí, jẹ́ ká ṣàkópọ̀ ohun tá a ti ń sọ bọ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì orí kẹrin fẹ́ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé “Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé.” Ìyẹn nìkan ti jẹ́ ká rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún ní ìtumọ̀ míì tó gadabú yàtọ̀ sí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinésárì. Àti pé, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì látòkè délẹ̀ ń tọ́ka sí Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù máa jẹ́ alákòóso rẹ̀. Ṣé o wá rò pé ó bọ́gbọ́n mu tá a bá sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì orí kẹrin yìí ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run?
Tádé: Hun-un, ó fẹ́ẹ́ jọ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ èmi ò tíì rí bó ṣe kan ọdún 1914 tí mo bi yín.
“KÍ ÌGBÀ MÉJE SÌ KỌJÁ”
Kọ́lá: Ó dáa. Jẹ́ ká pa dà sórí ọ̀rọ̀ Nebukadinésárì Ọba. Ṣé o rántí pé òun ló dúró fún igi ńlá nínú ìmúṣẹ àkọ́kọ́ tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní? Wọ́n gé igi náà, wọ́n sì fi í sílẹ̀ fún ìgbà méje ní ti pé ìṣàkóso Ọba yẹn dáwọ́ dúró nígbà tí orí rẹ̀ dà rú. Ìgbà méje yẹn sì dópin nígbà tí orí Nebukadinésárì pé, tí ó sì pa dà sí orí ìtẹ́ rẹ̀. Nínú ìmúṣẹ kejì tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní, ìṣàkóso Ọlọ́run máa dáwọ́ dúró fúngbà díẹ̀, àmọ́ kì í ṣe nítorí pé Ọlọ́run ṣe ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó o.
Tádé: Kí lẹ ní lọ́kàn?
Kọ́lá: Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ńṣe ni àwọn ọba Ísírẹ́lì tó ń ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù jókòó sórí “ìtẹ́ Jèhófà.”f A lè sọ pé wọ́n ń ṣojú fún Ọlọ́run láti ṣàkóso àwọn èèyàn rẹ̀. Ìyẹn já sí pé Jèhófà ló ń tipasẹ̀ àwọn ọba yẹn ṣàkóso àwọn èèyàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ọ̀pọ̀ àwọn ọba yẹn ṣàìgbọràn sí Jèhófà, àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fara wé ìwà àìgbọràn wọn. Èyí ló bí Jèhófà nínú tó fi fàyè gba àwọn ará Bábílónì láti ṣẹ́gun wọn ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Látìgbà yẹn ni kò ti sí ọba tó ń ṣojú fún Jèhófà mọ́ ní Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe di pé ìṣàkóso Ọlọ́run dáwọ́ dúró fúngbà díẹ̀ nìyẹn. Ǹjẹ́ àlàyé mi ń yé ẹ?
Tádé: Ó dà bíi pé ó ń yé mi díẹ̀díẹ̀.
Kọ́lá: Torí náà, ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ìgbà méje yẹn bẹ̀rẹ̀ tàbí lédè míì, ìgbà yẹn ni ìṣàkóso Ọlọ́run dáwọ́ dúró. Nígbà tí ìgbà méje yẹn bá dópin, Ọlọ́run á gbé ọba tuntun gorí ìtẹ́ kó lè máa ṣojú fún un. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ọ̀run ni ọba náà máa wà. Ìgbà yẹn gan-an wá ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tá a kà nínú ìwé Dáníẹ́lì máa ní ìmúṣẹ. Ìbéèrè náà wá ni pé: Ìgbà wo ni ìgbà méje náà dópin? Tí a bá lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, àá mọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso.
Tádé: Ó dáa. Ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tó wà lọ́kàn mi. Ó dà bíi pé ọdún 1914 ni ìgbà méje yẹn dópin. Àbí?
Kọ́lá: Bó ṣe rí gan-an nìyẹn!
Tádé: Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Kọ́lá: Màá ṣàlàyé. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà méje yẹn ò tíì dópin.g A jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ọjọ́ méje kọ́ ni ohun tá à ń sọ yìí. Ìgbà méje yẹn ti bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí Jésù tó wá sáyé, ó sì tún ń bá a lọ́ fún àwọn àkókò kan lẹ́yìn tí Jésù pa dà sí ọ̀run. Má gbàgbé pé ó di “àkókò òpin”h kí ìtumọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì tó ṣe kedere. Àmọ́ a láyọ̀ pé ní ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti fi òótọ́ inú ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ yìí àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì, kínníkínní. Wọ́n sì ti fòye mọ̀ pé ìgbà méje yẹn máa dópin ní ọdún 1914. Àwọn ohun mánigbàgbé tó sì ṣẹlẹ̀ láyé ti jẹ́ ká rí i pé ọdún 1914 gan-an ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ lókè ọ̀run. Ọdún yẹn gan-an ni àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ tàbí lédè míì, ni àkókò òpin bẹ̀rẹ̀. Ó dà bíi pé ohun tá a ti sọ lónìí ti pọ̀ gan-an o!
Tádé: Bẹ́ẹ̀ ni. Màá rí i pé mo gbé gbogbo ohun tá a jíròrò yìí yẹ̀ wò, kó lè túbọ̀ yé mi dáadáa.
Kọ́lá: Kò rọrùn. Ó pẹ́ díẹ̀ kí èmi náà tó lóye gbogbo àlàyé yẹn. Àmọ́, mo mọ̀ pé gbogbo ohun tá a jíròrò yìí ti jẹ́ kó o rí i pé inú Bíbélì ni gbogbo ohun tá a gbà gbọ́ nípa Ìjọba náà ti wá.
Tádé: Mo gbà bẹ́ẹ̀. Gbogbo ìgbà ló tiẹ̀ máa ń wú mi lórí bó ṣe jẹ́ pé gbogbo ohun tẹ́ ẹ gbà gbọ́ ló wà nínú Bíbélì.
Kọ́lá: Mo sì mọ̀ pé ó wù ẹ́ kó jẹ́ pé gbogbo ohun tó o bá gbà gbọ́ ló máa wà nínú Bíbélì. Bí mo ṣe sọ tẹ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ohun tá a lé mójú tó ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan. Ó ṣeé ṣe kó o ṣì ní àwọn ìbéèrè míì. Bí àpẹẹrẹ, a ti rí i pé ìgbà méje yẹn ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run àti pé ìgbà méje yẹn bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, báwo gan-an la ṣe mọ̀ pé ìgbà méje yẹn dópin ní ọdún 1914?i
Tádé: Apá ibẹ̀ yẹn ṣì ń ya èmi náà lẹ́nu.
Kọ́lá: Bíbélì jẹ́ ká mọ bí ìgbà méje yẹn ṣe gùn tó. Ṣé wàá fẹ́ ká gbé kókó yẹn yẹ̀ wò nígbà míì tí mo bá wá?j
Tádé: Bẹ́ẹ̀ ni, màá fẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ṣé àwọn ẹ̀kọ Bíbélì kan máa ń ṣe ìwọ náà ní kàyéfì? Ǹjẹ́ ó fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ àti bí ìjọsìn wa ṣe rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́tìkọ̀ láti bi ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa rẹ̀. Inú onítọ̀hùn á dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń jíròrò Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn lọ́fẹ̀ẹ́.
c Wo orí 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo.
g Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn, ó sọ pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè yóò tẹ Jerúsálẹ́mù [èyí tó dúró fún ìṣàkóso Ọlọ́run] mọ́lẹ̀, títí àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi pé.” (Lúùkù 21:24) Nípa bẹ́ẹ̀, ìṣàkóso Ọlọ́run ò tíì gbérí pa dà ní àkókò tí Jésù wà láyé, ipò yìí sì máa bá a lọ títí di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.
i Wo the àfikún “Ọdún 1914—Ọdún Pàtàkì Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
j Àpilẹ̀kọ tó máa tẹ̀ lé èyí nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bí ìgbà méje náà ṣe gùn tó.