Ó “Mọ Ọ̀nà” Náà
ARÁKÙNRIN Guy Hollis Pierce, tó sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ Tuesday, March 18, ọdún 2014. Ó kú ní ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi, ó sì ti jíǹde sí ọ̀run.—Héb. 2:10-12; 1 Pét. 3:18.
Ìlú Auburn, ní ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí Arákùnrin Guy Pierce sí ní November 6, ọdún 1934. Ó ṣèrìbọmi ní ọdún 1955. Ó fẹ́ aya rẹ̀ ọ̀wọ́n tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Penny lọ́dún 1977, wọ́n sì bímọ. Torí pé Arákùnrin Pierce ti tọ́ ọmọ rí, bíi bàbá ló máa ń ṣe sí ọ̀pọ̀ èèyàn. Lọ́dún 1982, òun àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ọdún 1986 ni Arákùnrin Pierce bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọdún mọ́kànlá ló sì fi ṣe é.
Lọ́dún 1997, Arákùnrin Pierce àti ìyàwó rẹ̀ di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ni Arákùnrin Pierce ti ṣiṣẹ́, nígbà tó sì di ọdún 1998, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àwọn Òṣìṣẹ́ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ibi ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania tí wọ́n ṣe ní October 2, 1999 ni wọ́n ti ṣèfilọ̀ pé Arákùnrin Pierce ti di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó sìn pẹ̀lú onírúurú ìgbìmọ̀ irú bí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àwọn Òṣìṣẹ́, Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé, Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde àti Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí.
Bí Arákùnrin Pierce ṣe máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́ tó sì máa ń pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín mú kí àwọn tí ipò àti àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Àmọ́, bó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tí kì í fi ìlànà òdodo báni ṣeré àti bó ṣe ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jèhófà ló dìídì mú kí àwọn èèyàn fà mọ́ ọn. Arákùnrin Guy Pierce gbà pé bó ṣe jẹ́ pé ojúmọ́ kan ò lè mọ́ kí ọ̀yẹ̀ má là, bẹ́ẹ̀ ni èyíkéyìí nínú àwọn ìlérí Jèhófà ò ní lọ láìṣẹ, ó sì fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ òtítọ́ yìí.
Akíkanjú èèyàn ni Arákùnrin Pierce, àárọ̀ kùtùkùtù ló ti máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, àṣedòru ló sì máa ń ṣe é nígbà míì. Bó ṣe ń rìnrìn àjò láti fún àwọn ará níṣìírí mú kó lọ káàkiri ayé. Kò sígbà tí kì í ráyè gbọ́ ti àwọn tí wọ́n jọ ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, yálà àwọn tó kàn fẹ́ wá bá a ṣeré tàbí àwọn mí ì tí wọ́n fẹ́ kó wá kí àwọn nílé. Àwọn míì lè wá bá a pé kó fún àwọn ní ìmọ̀ràn tàbí kó ran àwọn lọ́wọ́. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ṣì rántí ohun tó ti ṣe fún wọn lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, bó ṣe ní ẹ̀mí aájò àlejò, bó ṣe mú wọn bí ọ̀rẹ́ àti bó ṣe fún wọn ní ìmọ̀ràn tó dá lórí Ìwé Mímọ́.
Àwọn tó gbẹ̀yìn Arákùnrin wa àti ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n ni ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ mẹ́fà, àwọn ọmọ-ọmọ àtàwọn ọmọ-ọmọ-ọmọ. Ó sì tún ní àìmọye ọmọ nípa tẹ̀mí. Arákùnrin Mark Sanderson tóun náà jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé ìsìnkú Arákùnrin Pierce lọ́jọ́ Saturday, March 22, 2014, ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn. Lára ohun tó sọ nínú àsọyé rẹ̀ ni ìrètí tí Arákùnrin Pierce ní láti jíǹde sí ọ̀run, ó sì ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùjókòó ni ń bẹ. . . . Bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀. Ibi tí èmi sì ń lọ, ẹ mọ ọ̀nà ibẹ̀.”—Jòh. 14:2-4.
Lóòótọ́, a máa ṣàárò Arákùnrin Pierce gan-an. Àmọ́, inú wa dùn pé ó “mọ ọ̀nà” tó lọ sí “ibùjókòó” rẹ̀ tó máa wà pẹ́ títí.