Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
December 15, 2014
© 2014 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
FEBRUARY 2-8, 2015
‘Ẹ Fetí sí Mi, Kí Ẹ sì Lóye Ìtúmọ̀ Rẹ̀’
FEBRUARY 9-15, 2015
Ǹjẹ́ O “Mòye Ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́”?
FEBRUARY 16-22, 2015
Bá A Ṣe Lè La Òpin Ayé Ògbólógbòó Yìí Já Pa Pọ̀
OJÚ ÌWÉ 22 • ORIN: 107, 29
FEBRUARY 23, 2015–MARCH 1, 2015
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ ‘Ẹ Fetí sí Mi, Kí Ẹ sì Lóye Ìtúmọ̀ Rẹ̀’
▪ Ǹjẹ́ O “Mòye Ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́”?
Báwo la ṣe lè rí i dájú pé a lóye àwọn àpèjúwe Jésù? Àwọn àpilẹ̀kọ méjì yìí máa jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè ṣàlàyé méje lára àwọn àpèjúwe tí Jésù lò. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí tún máa jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè lo àwọn ẹ̀kọ́ tí a kọ́ nínú àwọn àpèjúwe yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
▪ Bá A Ṣe Lè La Òpin Ayé Ògbólógbòó Yìí Já Pa Pọ̀
▪ Ǹjẹ́ O Mọyì Ohun Tí O Ti Rí Gbà?
Inú ayé tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ kò ti mọ̀ ju tara wọn lọ là ń gbé. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run? Nínú àpilẹ̀kọ yìí a máa ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ rere àti búburú tó máa jẹ́ kí tọmọdé tàgbà mọ ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ìpinnu tí ó tọ́.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
4 Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Ní Ẹ̀mí Ìmúratán
17 Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Yí Èrò Rẹ Pa Dà?
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Nígbà tí àwọn kan tó wá gbafẹ́ ní etíkun Tamarindo tó wà ní Etí Òkun Pàsífíìkì lórílẹ̀-èdè Costa Rica gbọ́ pé lọ́jọ́ iwájú gbogbo ilẹ̀ ayé máa di Párádísè, níbi tí a ó ti máa gbádùn, inú wọn dùn gan-an
COSTA RICA
IYE AKÉDE
29,185
IYE AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ DÉÉDÉÉ
2,858
Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run,
Jéoba
ni wọ́n ń pè é lédè Bribri
Jehová
ni wọ́n ń pè é lédè Cabecar
Ìjọ méjì àti àwùjọ méjì ló ń fi èdè Bribri ṣe ìpàdé, ìjọ mẹ́ta àti àwùjọ mẹ́rin sì ń fi èdè Cabecar ṣe ìpàdé. Èdè ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà ni èdè méjèèjì yìí