Orin 107
Wá sí Òkè Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Gbójú wòkè réré,
Kọjá òkè tó ga jù.
Ibẹ̀ ni òkè Jáà wà
Tí a gbé ga lónìí.
Àwọn èèyàn ń wá,
Àní látibi gbogbo,
Wọ́n ń ké síra wọn pé,
‘Wá jọ́sìn Ọlọ́run.’
Àkókò tó wàyí,
Kẹ́ni kékeré di ilẹ̀ ńlá.
Báa ṣe ń gbèrú síi,
A ńrọ́wọ́ Ọlọ́run lára wa.
Èrò ńya sọ́dọ̀ rẹ̀
Wọ́n gbàá l’Ọ́ba Aláṣẹ.
Wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ ìṣòtítọ́
Láìní yẹsẹ̀ láéláé.
2. Jésù ló paá láṣẹ
Pé ká wàásù ọ̀rọ̀ náà.
Ìhìn ’jọba Ọlọ́run
Ńdọ́dọ̀ gbogbo ayé.
Kristi ńjọba lọ́run,
Ó ń pe gbogbo èèyàn.
Ọlọ́kàn tútù tó ńgbọ́
Ń tẹ̀ lé Bíbélì.
Ayọ̀ gbọkàn wa pé
Ogunlọ́gọ̀ ńlá túbọ̀ ńbí síi!
Iṣẹ́ gbogbo wa ni,
Láti fọ̀nà Jèhófà hanni.
Jẹ́ ká gbóhùn sókè,
Ká ké tantan sáráyé,
‘Ẹ wá sókè Jèhófà,
Má sì kúrò níbẹ̀.’
(Tún wo Sm. 43:3; 99:9; Aísá. 60:22; Ìṣe 16:5.)