ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp19 No. 2 ojú ìwé 8-9
  • Tí Ẹnì Kejì Rẹ Bá Ṣe Ìṣekúṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tí Ẹnì Kejì Rẹ Bá Ṣe Ìṣekúṣe
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌMỌ̀RÀN TÓ WÚLÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ
  • Kíkojú Ìfàsẹ́yìn Nípa Gbígbé Góńgó Kalẹ̀
    Jí!—2001
  • Bá A Ṣe Lè Rí Ìtùnú Lásìkò Wàhálà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Náà Ṣeé Yanjú?
    Jí!—1999
  • Mi Ò Ṣi Iṣẹ́ Tí Màá Ṣe Láyé Mi Yàn
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
wp19 No. 2 ojú ìwé 8-9
Obìnrin kan ń gbàdúrà

Tí Ẹnì Kejì Rẹ Bá Ṣe Ìṣekúṣe

“Nígbà tí ọkọ mi sọ pé òun fẹ́ lọ fẹ́ ọmọge kan, ayé sú mi, ó sì dà bíi pé kí n pa ara mi. Tí mo bá rántí gbogbo ìyà tí mo ti jẹ nítorí tiẹ̀, ńṣe ni ìbànújẹ́ máa ń bá mi.”​—Maria, Spain.

“Nígbà tí ìyàwó mi fi mí sílẹ̀ lójijì, ńṣe ló dà bíi pé àwọn ẹ̀yà ara mi bẹ̀rẹ̀ sí í daṣẹ́ sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Gbogbo àwọn àfojúsùn wa àtàwọn ipinnu wa pátá ló wọmi lọ́jọ́ yẹn. Àwọn ìgbà míì wà tó máa dà bíi pé ẹ̀dùn ọkàn mi ti lọ, àmọ́ ṣàdédé ni ìrẹ̀wẹ̀sì á tún bò mí mọ́lẹ̀.”​—Bill, Spain.

Ó MÁA ń bani nínú jẹ́ gan-an tẹ́nì kan bá mọ̀ pé ẹnì kejì òun ti ṣe ìṣekúṣe. Òótọ́ ni pé, a rí àwọn kan tó dárí ji ẹnì kejì wọn nígbà tí wọ́n rí i pé wọ́n ti ronú pìwà dà.a Àmọ́, bóyá irú àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ ṣì ń fẹ́ ara wọn àbí wọ́n tú ká, ìbànújẹ́ ńláǹlà tí ẹni tí wọ́n hùwà àìtọ́ sí máa ní máa ń kọjá àfẹnusọ. Báwo ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe lè borí ẹ̀dùn ọkàn wọn?

ÌMỌ̀RÀN TÓ WÚLÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ

Ọ̀pọ̀ àwọn tí ẹnì kejì wọn ṣe ìṣekúṣe ló ti rí ìtùnú nínú Bíbélì, láìka bí ẹ̀dùn ọkàn wọn ṣe lágbára sí. Wọ́n ti rí i pé Ọlọ́run ń rí omijé àwọn, ó sì mọ ẹ̀dùn ọkàn àwọn.​—Málákì 2:13-16.

“Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”​—Sáàmù 94:19.

Bill sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà ń wo ọgbẹ́ ọkàn mi sàn lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, gẹ́gẹ́ bíi bàbá onífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń ṣe.”

“Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin.”​—Sáàmù 18:25.

Carmen tí ọkọ rẹ̀ ti ń ṣe ìṣekúṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù sọ pé: “Ó ti pẹ́ tí ọkọ mi ti ń hùwà àìṣòótọ́ sí mi kí n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀. Àmọ́, ó dá mi lójú pé Jèhófà ò ní fi mí sílẹ̀. Kò sì ní já mi kulẹ̀ láé.”

“ Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ . . . ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín.”​—Fílípì 4:6, 7.

Sasha sọ pé: “Àkàtúnkà ni mo máa ń ka ẹsẹ Bíbélì yìí. Bí mo ṣe ń gbàdúrà lemọ́lemọ́, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fún mi ní àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀.”

Nígbà kan, àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí ti ro ara wọn pin. Àmọ́, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n sì rí okun gbà láti inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bill tiẹ̀ sọ pé: “Nígbà tó dà bíi pé gbogbo nǹkan ti dojú rú, ìgbàgbọ́ mi ló fún mi lókun. Bí mo tilẹ̀ ń rìn nígbà kan ‘nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri,’ Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.”​—Sáàmù 23:4.

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ bóyá ó yẹ kó o dárí ji ẹnì kejì rẹ tàbí kò yẹ kó o dárí jì í, ka àpilẹ̀kọ tó wà nínú Jí! May 8, 1999, “Bí Ẹnì Kejì Wa Nínú Ìgbéyàwó Bá Hùwà Àìṣòótọ́.”

Ohun Tó Ran Àwọn Kan Lọ́wọ́

Ronú nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù ẹ́ nínú.

Bill sọ pé: “Mo ka ìwé Jóòbù àti Sáàmù, mo sì fa ilà sí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó bá ohun tó ń ṣe mí mu. Mo wá rí i pé àwọn tó kọ ìwé méjèèjì yìí ló ti ní irú ìṣòro tí mo ní.”

Gbọ́ orin tó lè tù ẹ́ nínú.

Carmen sọ pé: “Láwọn ìgbà tí mi ò lè sùn ní òru, mo máa ń gbọ́ orin. Èyí sì máa ń tù mí lára gan-an.” Daniel sọ pé: “Mo kọ́ bí wọ́n ṣe ń ta jìtá, bí mo ṣe ń fi jìtá yẹn kọrin jẹ́ kí n láyọ̀, kí ara sì tù mí.”

Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fáwọn míì.

Daniel sọ pé: “Kò mọ́ mi lára láti máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fáwọn míì. Àmọ́, mo ní àwọn ọ̀rẹ́ rere, mo sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́. Mó máa ń sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn mi fún wọn, ó lè jẹ́ nínú lẹ́tà tàbí ní tààràtà. Èyí sì ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an.” Sasha náà sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ táwọn mọ̀lẹ́bí mi ṣe fún mi ò kéré rárá. Màmá mi dúró tì mí gan-an. Wọ́n máa ń tẹ́tí sí mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá fẹ́ sọ̀rọ̀. Bàbá mi náà ò sì gbẹ́yìn, wọ́n máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀ wọ́n sì máa ń ṣe sùúrù pẹ̀lú mi bí ara mi ṣe ń balẹ̀ díẹ̀díẹ̀.”

Má ṣe dákẹ́ àdúrà.

Carmen sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà. Mo sì máa ń rí i pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi, ó ń tẹ́tí sí mi, ó sì ń ràn mí lọ́wọ́. Òótọ́ ni pé àkókò yẹn ò rọrùn rárá, àmọ́ mo túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́