Padà Sọ́dọ̀ Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Fi Ìfẹ́ Hàn Láti Ṣe Àwọn Ẹlòmíràn Láǹfààní
1 Kí ni kókó pàtàkì tí ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa? Ọkan-ìfẹ́! Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nígbà tí ó bá kan ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò. Nígbàkugbà tí ẹnì kan bá fi ìfẹ́ hàn nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ bín-íntín, a fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ṣe ẹni náà láǹfààní. Nítorí náà, a ń ṣe ìpadàbẹ̀wò pẹ̀lú ète mímú ọkàn-ìfẹ́ ẹni náà dàgbà, àti bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. Góńgó wa nìyí, àní bí kò bá tilẹ̀ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ pàápàá. Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí?
2 Bí ìjíròrò rẹ ìṣáájú bá dá lórí àwọn ìṣòro ìgbeyàwó tí ó gbòde kan lónìí, tí o sì fi ìwé “Walaaye Titilae” sílẹ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò rẹ lọ́nà yìí:
◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó kọjá, a sọ̀rọ̀ lórí ìgbeyàwó àti ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ inú Bibeli tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ tí ó pọ̀ sí i. Kò ha jẹ́ òtítọ́ pé, nínú àwọn ìdílé tí ó dára jù lọ pàápàá, àwọn ìṣòro máa ń jẹyọ láti ìgbà dé ìgbà? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bibeli fún wa ní ìmọ̀ràn tí ó tayọ lọ́lá tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro nínú ipò ìbátan ìdílé. Ìdílé kan lè di èyí tí a bùkún nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli papọ̀.” Ṣí i sí ojú ìwé 246, kí o sì jíròrò ìpínrọ̀ 23. Ka Johannu 17:3, kí o sì yọ̀ǹda láti ran ìdílé náà lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé.
3 Bí o bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ àti àìní tí wọ́n ní fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́, o lè máa bá ìjíròrò náà lọ ní ọ̀nà yìí:
◼ “Ní ìṣáájú, a sọ̀rọ̀ nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí tí àwọn ọmọ nílò àti bí àwọn òbí ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn òbí tí mo ti bá sọ̀rọ̀ ni ẹnu ń yà sí ìwà burúkú tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń hù lónìí. Kí ni èrò rẹ nípa . . . ? [Mẹ́nu kan àpẹẹrẹ ìwàkíwà àwọn èwe tí ẹ sábà máa ń kíyèsí ní àdúgbò yín. Jẹ́ kí ó fèsì.] Jẹ́ kí n fi díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn tí ó gbéṣẹ́ tí a fi fúnni nínú Bibeli hàn ọ́.” Ṣí ìwé Walaaye Titilae sí ojú ìwé 246, ìpínrọ̀ 22, jíròrò àwọn kókó tí ó wà níbẹ̀, kí o sì ka Efesu 6:4. Ṣàlàyé pé èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọdé ní ń fẹ́ ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà ní ti gidi. Nígbà tí àwọn òbí bá jẹ́ aláápọn ní pípèsè rẹ̀, inú àwọn ọmọ máa ń dùn, wọ́n sì máa ń túbọ̀ fi ọ̀wọ̀ hàn sí i nínú ìwà wọn. Ṣàlàyé bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn ọmọ wa.
4 Bí ó bá jẹ́ Paradise orí ilẹ̀ ayé ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìjíròrò rẹ, nígbà náà, o lè sọ èyí láti mú ọ̀kan-ìfẹ́ náà sọjí:
◼ “A fi díẹ̀ lára àwọn àwòrán inú ìwé yìí, tí ó fi bí ilẹ̀ ayé yóò ṣe rí, nígbà tí Ọlọrun bá sọ ọ́ di paradise, hàn wá. Kò ní já sí nǹkankan fún wa bí a kò bá lè gbádùn rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wa. Ìwọ kò ha gbà bẹ́ẹ̀ bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé Walaaye Titilae sí ojú ìwé 162. Ka Ìṣípayá 21:3, 4, kí o sì ṣàlàyé bí ó ti ṣeé ṣe kí àwọn olólùfẹ́ wa wà pẹ̀lú wa. Bí ìdáhùnpadà tí ó dára bá wà, ka Johannu 5:28, 29 láti fi hàn pé àwọn òkú yóò padà wá sí ìyè. Tọ́ka sí èpo ìwé náà, kí o sì sọ pé: “Òtítọ́ ni—a lè wà láàyè títí láé nínú Paradise lórí ilẹ̀ ayé!” Ṣètò fún ìbẹ̀wò mìíràn láti jíròrò ìdí tí a fi mọ̀ pé ó sún mọ́lé.
5 Ète pàtàkì tí a fi ń ṣe ìpadàbẹ̀wò ní láti ran àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní láti inú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn nílò ohun kan láti ru ìfẹ́ wọn sókè fún àwọn ohun tẹ̀mí. Darí àfiyèsí wọn sórí àwọn kókó ṣiṣe gúnmọ́, tí ó ní ìníyelórí gbígbéṣẹ́ nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ní títẹnu mọ́ bí ó ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Bibeli sí i. Ìpadàbẹ̀wò tí ó bá ṣàṣeparí àwọn góńgó wọ̀nyí yóò ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe ara wọn láǹfààní ní ọ̀nà ṣíṣeé ṣe tí ó dára jù lọ.