ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/95 ojú ìwé 8
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ṣe Ara Wọn Láǹfààní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ṣe Ara Wọn Láǹfààní
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Padà Sọ́dọ̀ Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Fi Ìfẹ́ Hàn Láti Ṣe Àwọn Ẹlòmíràn Láǹfààní
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Fi Òye Inú Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ẹ Jẹ́ Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọrun—Ní Lílo Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 9/95 ojú ìwé 8

Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ṣe Ara Wọn Láǹfààní

1 Jehofa ṣèlérí láti kọ́ wa ní ohun tí ó yẹ kí a mọ̀. Ó mú un dá wa lójú ní Orin Dafidi 32:8 pé: “Èmi óò fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà, èmi óò sì kọ́ ọ ní ọ̀nà tí ìwọ óò rìn: Èmi óò máa fi ojú mi tọ́ ọ.” Àǹfààní ńlá ni ìmúdánilójú yìí jẹ́ fún wa. Láìfẹ́ jẹ́ olùmọtara-ẹni-nìkan, a fẹ́ fi bí àwọn ẹlòmíràn ṣe lè ṣe ara wọn láǹfààní, nípa kíkọbiara sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n láti inú Bibeli, hàn wọ́n. (Isa. 48:17) Ní September, a lè ṣe èyí nípa fífi ìwé Walaaye Titilae lọni. Ní gbígbé àwọn ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀, onírúurú ọ̀nà ni ó wà tí a lè gbà fi ìníyelórí ìgbéṣẹ́ Bibeli hàn.

2 Nítorí àwọn ìṣòro ìgbéyàwó tí ó gbòde kan lónìí, o lè yàn láti gbé èrò yìí jáde láti inú ìwé “Walaaye Titilae”:

◼ “Èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn tí mo ti bá sọ̀rọ̀ ń ṣàníyàn gidigidi nípa bí àìláyọ̀ àti ìkọ̀sílẹ̀ nínú ìgbeyàwó ti ń peléke sí i. Kí ni èrò rẹ nípa ìṣòro yìí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ọ̀pọ̀ ti kùnà láti rí àwọn okùnfà abẹ́nú. Bí wọ́n bá fi òtítọ́ inú sapá, kì í ṣe kìkì pé àwọn tọkọtaya lè dáàbò bo ìgbeyàwó wọn nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n lè rí ojúlówó ayọ̀ pẹ̀lú. Àṣírí ṣíṣàṣeyọrí sinmi lórí fífi ìmọ̀ràn tí ó wà nínú Bibeli sílò.” Ka Efesu 5:28, 29, 33. Ṣí i sí ojú ìwé 243, jíròrò ìpínrọ̀ 16 àti 17, lẹ́yìn náà, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́.

3 Àwọn ọmọdé nílò ojúlówó àkókò àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Ní gbígbé ìwé “Walaaye Titilae” jáde lákànṣe, o lè sọ pé:

◼ “Gbogbo wa ni ire ọjọ́ ọ̀la àwọn ọ̀dọ́ wa ń jẹ lọ́kàn. Ní èrò tìrẹ, ọ̀nà wo ni ó dára jù lọ tí àwọn òbí lè gbà ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti rí ọjọ́ ọ̀la aláàbò kan? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Fetí sí ìmọ̀ràn yìí láti inú òwe Bibeli kan, tí a kọ ní nǹkan bí 3,000 ọdún sẹ́yìn. [Ka Owe 22:6.] Bí àwọn ọmọ wa tilẹ̀ lè jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ láti inú ìtọ́ni tí wọ́n ń rí gbà ní ilé ẹ̀kọ́, àwọn òbí wọn ní ilé ni ó ń pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó ṣeyebíye jù lọ fún wọn. Ó ń béèrè fún àkókò, àfiyèsí, àti ìfẹ́, ṣùgbọ́n ìsapá náà yẹ fún un ní ti gidi.” Ṣí i sí ojú ìwé 245, jíròrò ìpínrọ̀ 20 àti 21, kí o sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè lo ìwé náà gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé.

4 O lè fẹ́ láti fi ìwé “Walaaye Titilae” lọni nípa fífi bí ilẹ́ ayé yóò ṣe di paradise hàn:

◼ “Ó dá mi lójú pé o ń ṣàníyàn nípa bí ìgbésí ayé rẹ yóò ṣe rí ní ọjọ́ iwájú. Nínú Àdúrà Oluwa, Jesu kọ́ wa láti gbàdúrà fún ìfẹ́ Ọlọrun láti di ṣíṣe ní orí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run. Báwo ni ilẹ̀ ayé yóò ṣe rí nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bí ayàwòrán kan ṣe ṣàpèjúwe paradise àgbáyé kan nìyí. [Fi àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 12 àti 13 hàn án. Lẹ́yìn náà, ka Isaiah 11:6-9, tí ó wà ní ìpínrọ̀ 12.] Kò ha ní jẹ́ ohun àgbàyanu láti gbé nínú irú ayé bẹ́ẹ̀? Ìwé yìí yóò fi bí ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe lè gbé nínú paradise bí èyí hàn ọ́.”

5 Mímúra àwọn ìgbékalẹ̀ rẹ sílẹ̀ ṣáájú àkókò ṣe kókó nínú pípinnu àṣeyọrí rẹ ní ẹnu ilẹ̀kùn. Kí o tó kan ilẹ̀kùn, rí i dájú pé o ní ohun kan pàtó láti sọ nípa èròngbà inú Ìwé Mímọ́. Bákan náà, ní àlàyé kúkúrú kan lọ́kàn nípa ẹ̀ka fífanimọ́ra kan nínú ìwé ìròyìn tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú tí o wéwèé láti fi lọni, bí wọn kò bá gba ìwé náà. Lo gbogbo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ láti fún irúgbìn òtítọ́ Ìjọba ní September. (Oniwasu 11:6) Ìwọ yóò máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ká àwọn àǹfààní tí yóò wà pẹ́ títí láé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́