Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ Tọ̀sán Tòru
1 A ti nawọ́ àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ sí wa. Ìyẹn ni jíjẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jehofa. A jẹ́ apá kan ètò àjọ kárí ayé ti àwọn ajíhìnrere tí Jehofa ń lò láti ṣàṣeparí iṣẹ́ ìpolongo Ìjọba lọ́nà tí ó tóbi jù lọ tí a tí ì ṣe rí! (Marku 13:10) Lójú ìwòye ìjẹ́kánjúkánjú àkókò wa, àwá ha ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ yìí títí dé ìwọ̀n àyè tí ó bá ṣeé ṣe ní kíkún bí?
2 A kò mọ iye àwọn tí yóò dáhùn padà sí ìwàásù wa lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Jehofa fún wa ní ìdánilójú pé yóò jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan,” gbogbo àwọn tí a óò dá mọ̀ nípa pé wọ́n “ń ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán tòru.” (Ìṣí. 7:9, 15) Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó ju mílíọ̀nù márùn-ún tí ọwọ́ wọ́n dí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọrun kì í ṣe olùgbọ́ tí ń fìfẹ́ hàn lásán, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣe olùpésẹ̀ sí ìpàdé lásán. Wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ tí ń polongo ìhìn rere kárí ayé!
3 Lójoojúmọ́, àǹfààní máa ń ṣí sílẹ̀ láti yin Jehofa, yálà nínú iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí láìjẹ́-bí-àṣà. Ronú nípa ìjẹ́rìí kíkọ yọyọ tí a lè ṣe bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wá bá lè lo ìdánúṣe láti ṣàjọpín òtítọ́ pẹ̀lú ẹnì kan péré lóòjọ́. Ìmọrírì wa fún Jehofa yẹ kí ó sún wa láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pẹ̀lú ìtara ọkàn.—Orin Da. 92:1, 2.
4 Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ láti Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Ọlọ́wọ̀: Jehofa ń bá a nìṣó láti bù kún wa pẹ̀lú ìbísí. (Hag. 2:7) Ní Nàìjíríà, ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tí ó kọjá, a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé tí ìpíndọ́gba rẹ̀ jẹ́ 272,954 lóṣù. Góńgó wa ní ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jesu. (Matt. 28:19, 20) Ọ̀pọ̀ nínú wọn ti tẹ̀ síwájú dáradára nípa pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé déédéé. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ojúlùmọ̀ wọn sọ̀rọ̀ “nipa awọn ohun ọlá-ńlá Ọlọrun” tí wọ́n ti kọ́. (Ìṣe 2:11) A ha lè ké sí wọn nísinsìnyí láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba bí?
5 Ní April, ó yẹ kí á ṣe àkànṣe ìsapá láti ké sí àwọn ẹni tuntun tí wọ́n tóótun, pé kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ha ti sọ ìfẹ́ rẹ̀ láti ṣe èyí jáde? Bí ó bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó ha kúnjú ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún bí? (Wo ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 97 sí 99.) Nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá nífẹ̀ẹ́ láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, jíròrò ìfojúsọ́nà rẹ̀ pẹ̀lú alábòójútó olùṣalága, tí yóò ṣètò fún àwọn alàgbà méjì láti yẹ ọ̀ràn náà wò. Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá tóótun láti di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi, ké sí i láti dara pọ̀ mọ́ ọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Kí àwọn alábòójútó iṣẹ́ ìsìn àti olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ní pàtàkì wà lójúfò sí ríran àwọn tí ó lè tóótun lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í kéde ní April.
6 Àwọn òbí lè ronú jinlẹ̀ bóyá àwọn ọmọ wọ́n tóótun láti di akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi. (Orin Da. 148:12, 13) Bí ọmọ rẹ bá fẹ́ láti sọ tẹnu rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba, tí òún sì ní ìwà rere, o lè tọ ọ̀kan nínú àwọn alàgbà tí ó wà nínú ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn lọ láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bá ti bá ìwọ àti ọmọ náà pàdé pọ̀, àwọn alàgbà méjì yóò pinnu bóyá ó tóótun láti di ẹni tí a kà sí akéde kan. A ní ìdí pàtàkì láti dunnú nígbà tí àwọn ọmọ wá bá dara pọ̀ mọ́ wa nínú yíyin Ọlọrun!
7 Jehofa nìkan ni ó lẹ́tọ̀ọ́ sí iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wa. (Luku 4:8) Ǹjẹ́ kí olúkúlùkù wa lo àǹfààní àgbàyanu tí a ní láti fi yìn ín “gidigidi.”—Orin Da. 109:30; 113:3.