ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/96 ojú ìwé 1
  • Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Ṣiṣẹ́ Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Ṣiṣẹ́ Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Gbàgbé Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ẹ Ṣèrànwọ́ fún Wọn Kí Wọ́n Lè Tètè Pa Dà Láìjáfara!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • “Ẹ Pa Dà Sọ́dọ̀ Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 6/96 ojú ìwé 1

Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Ṣiṣẹ́ Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I

1 Ní mímọ ewu tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Wákàtí náà ti tó nísinsìnyí fún yín láti jí lójú oorun, nítorí ìgbàlà wa sún mọ́lé nísinsìnyí ju ìgbà tí a di onígbàgbọ́ lọ.” (Rom. 13:11) Pọ́ọ̀lù ṣàníyàn nípa àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n ń tòògbé nípa tẹ̀mí; ó hára gàgà láti ta wọ́n jí sí ìgbòkègbodò tí a sọ dọ̀tun.

2 A lè sọ ní tòótọ́ pé òru ayé ògbólógbòó yìí ti lọ jìnnà. ojúmọ́ ayé tuntun sì kù fẹ́fẹ́. (Rom. 13:12) A ní ìdí rere láti ṣàníyàn nípa àwọn arákùnrin wa, tí wọ́n ti ṣíwọ́ láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú wa gẹ́gẹ́ bí oníwàásù ìhìn rere náà. Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tí ó kọjá, ní Nàìjíríà nìkan, a mú èyí tí ó ju 1,500 akéde sọjí. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn aláìṣiṣẹ́ mọ́ yòókù lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà lẹ́ẹ̀kan sí i?

3 Ohun Tí Àwọn Alàgbà Lè Ṣe: Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ kò tí ì fi òtítọ́ sílẹ̀; wọ́n kàn wulẹ̀ ṣíwọ́ wíwàásù nìkan ni, nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì, àwọn ìṣòro ara ẹni, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tàbí àwọn àníyàn ìgbésí ayé mìíràn. (Luk. 21:34-36) Bí ó bá ṣeé ṣe, ó sàn jù lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n tó di aláìṣiṣẹ́ mọ́. Akọ̀wé ìjọ ní láti ta olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lólobó nígbà tí akéde kan kò bá ń ròyìn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ déédéé. Wọ́n lè ṣètò fún ìbẹ̀wò olùṣọ́-àgùntàn. Wọ́n ní láti gbìyànjú láti pinnu ohun tí ó fa ìṣòro náà àti bí wọ́n ṣe lè pèsè ìrànwọ́.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1993, ojú ìwé 20 sí 23.

4 Bí Àwọn Mìíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́: Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa mọ ẹnì kan tí ó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́. Ó lè jẹ́ ẹnì kan tí ó sún mọ́ wa tẹ́lẹ̀. Kí ni a lè ṣe láti ṣèrànwọ́? Èé ṣe tí o kò fi ṣe ìbẹ̀wò ṣókí. Sọ fún un pé o ṣàárò rẹ̀. Jẹ́ ọlọ́yàyà, kí o sì fojú sọ́nà fún rere. Sọ àníyàn rẹ jáde láìdọ́gbọ́n sọ fún un pé ó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. Sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tàbí àwọn ohun rere mìíràn tí ìjọ ti ṣàṣeparí rẹ̀. Fi ìtara sọ fún un nípa Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run,” sì fún un níṣìírí láti wà níbẹ̀. Kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọ lẹ́ẹ̀kan sí i lè ràn án lọ́wọ́ ju ohunkóhun mìíràn lọ. Yọ̀ǹda láti lọ sí ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀. Jẹ́ kí àwọn alàgbà mọ irú ìdáhùnpadà tí o rí gbà.

5 Nígbà tí ẹnì kan tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ bá padà wá sí ìpàdé, ó ṣeé ṣe kí ó lọ́ tìkọ̀ nígbà tí ó bá ṣalábàápàdé àwọn tí ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Má ṣe béèrè pé, “Níbo ni o ti wà tẹ́lẹ̀?” Kàkà bẹ́ẹ̀, mú kí ó nímọ̀lára pé a tẹ́wọ́ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Fà á wọnú ìjíròrò. Fi í mọ àwọn tí kò mọ̀. Jókòó tì í nígbà ìpàdé, ní rírí i dájú pé ó ní ìwé orin àti ìwé tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́. Fún un níṣìírí láti padà wá, kí o sì pèsè ìrànwọ́ bí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀.

6 Ní níní ìfẹ́ni ọlọ́yàyà fún àwọn tí wọ́n ti ṣako lọ, Jèhófà àti Jésù máa ń láyọ̀ nígbà tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá jí pépé lẹ́ẹ̀kan sí i nípa tẹ̀mí. (Mal. 3:7; Mat. 18:12-14) A lè rí ayọ̀ kan náà bí a bá ṣàṣeyọrí nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà lẹ́ẹ̀kan sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́