Àpótí Ìbéèrè
◼ Kí ni ó yẹ kí a ṣe bí ẹni tí a yan àsọyé fún kò bá dé sí ìpàdé lákòókò?
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ipò tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ yóò dí arákùnrin kan lọ́wọ́ láti dé lákòókò láti sọ àsọyé tí a yàn fún un. Bí ìdí bá wà láti gbà gbọ́ pé yóò dé láìpẹ́, àwọn alàgbà lè pinnu láti máa bá Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ; a lè ṣe Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn tẹ̀ lé e. Bí ó bá hàn gbangba pé olùbánisọ̀rọ̀ náà kò ní dé ńkọ́? Ọ̀kan lára àwọn olùbánisọ̀rọ̀ àdúgbò lè sọ àsọyé èyíkéyìí tí òun ti múra rẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwéwèé tí a fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣe ṣáájú àkókò kì í jẹ́ kí ìṣòro yìí wáyé. Ó yẹ kí olùṣekòkáárí àsọyé fún gbogbo ènìyàn kàn sí olùbánisọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, ó kéré tán, ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú àkókò, láti rán an létí iṣẹ́ rẹ̀. Àkókò ìpàdé, àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba, àti ìtọ́sọ́nà tí ó ṣe kedere lórí bí a ṣe lè dé gbọ̀ngàn náà yẹ kí ó wà lára ìránnilétí náà. Olùbánisọ̀rọ̀ náà gbọ́dọ̀ ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí dáradára. Ó gbọ́dọ̀ fọwọ́ tí ó nípọn mú iṣẹ́ náà, ní ṣíṣe ìyípadà tí ó bá yẹ nínú àlámọ̀rí ara ẹni rẹ̀, kí ó baà lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Bí ohun kan tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ bá yọjú, tí yóò dí i lọ́wọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀, òún ní láti kàn sí olùṣekòkáárí àsọyé fún gbogbo ènìyàn lọ́gán, kí olùṣekòkáárí náà baà lè ṣètò fún ẹlòmíràn láti ṣe é. Ó yẹ kí ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé kò sí ṣíṣàyípadà nígbà tí ọ̀ràn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sórí tán. Bí ohun kan bá dá olùbánisọ̀rọ̀ náà dúró, tí yóò sì fi ìṣẹ́jú díẹ̀ pẹ́ dé, ó lè gbìyànjú láti ránṣẹ́ ní kíá mọ́sá sí àwọn alàgbà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí àwọn arákùnrin náà baà lè mọ ohun tí wọn yóò ṣe.
Ìmọrírì iṣẹ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, ìwéwèé àti ìránnilétí ṣáájú tí ó gún régé, àti àbójútó àfẹ̀sọ̀ṣe lè mú kí ó dájú pé yóò ṣeé ṣe fún ìjọ láti gbádùn àsọyé fún gbogbo ènìyàn, tí ó ṣàǹfààní, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.