Máa Ṣàjọpín Nǹkan Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn Gẹ́gẹ́ Bí Wọ́n Ṣe Nílò Rẹ̀
1 Jèhófà ṣètò láti máa pèsè àwọn ohun tí a ṣaláìní nípa tẹ̀mí fún wa nípasẹ̀ “ẹrú” olóòótọ́ náà. (Mát. 24:45-47) Ọ̀pọ̀ nínú ìpèsè wọ̀nyí ló ń wá gẹ́gẹ́ bí ìwé, Bíbélì, àwọn ìdìpọ̀ ìwé, fídíò, àwọn ọ̀rọ̀ tí a gbà sórí kásẹ́ẹ̀tì, àti àwọn àwo kọ̀ǹpútà tí a fi ń ṣèwádìí nínú Bíbélì. Ìgbà gbogbo ni ohun tí Jèhófà pèsè máa ń tó láìsí fífi nǹkan ṣòfò. Ó retí pé kí a máa bá ara wa ṣàjọpín, kí a rí i dájú pé gbogbo wa ló ń jàǹfààní lọ́gbọọgba.
2 Owó tabua la fi ń pèsè àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé ló ń gbé bùkátà ìnáwó wọ̀nyí. Èyí sì túbọ̀ wá rí bẹ́ẹ̀ gan-an látìgbà tí ètò àjọ náà ti bẹ̀rẹ̀ ètò pípín ìwé láìbéèrè fún iye owó kan pàtó, tí ó gbára lé ọrẹ àtinúwá pátápátá láti gbé ẹrù ìnáwó náà.
3 Bí A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́: A lè kọbi ara sí ìṣílétí Pọ́ọ̀lù pé kí a máa ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn “ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní wọn.” (Róòmù 12:13) Nígbà tí a bá fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé náà, ṣe la ń ṣàjọpín ohun tí a ní pẹ̀lú àwọn ará jákèjádò ayé. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, àwọn kan ti pinnu láti ya iye kan sọ́tọ̀ láti máa fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé lóṣooṣù, bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nínú ọ̀ràn ti ìnáwó Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe ìwé títẹ̀ nìkan ni a ń lo owó yìí fún, ṣùgbọ́n a ń lò ó fún gbogbo ẹ̀ka iṣẹ́ náà. Fojú inú wo àǹfààní ńláǹlà tí ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé yóò jẹ, bí púpọ̀ sí i nínú wa yóò bá máa ṣàjọpín lọ́nà yìí, kí a sì máa ṣe é déédéé.
4 Síwájú sí i, a lè bá wọn ṣàjọpín nípa wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nígbà tí a bá ń béèrè àwọn ìwé tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa. Bíbéèrè fún kìkì ohun tí a nílò ní ti gidi máa ń jẹ́ kí àwọn ará wa níbòmíràn lè rí àwọn ìpèsè tẹ̀mí gbà èyí tí àwọn pẹ̀lú nílò láti máa bá a nìṣó láti jẹ́ alágbára, kí wọ́n sì mú kí wíwàásù ìhìn rere náà máa bá a nìṣó lápá ibi tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé.—Héb. 13:16.
5 Ní pàtàkì, a gbọ́dọ̀ fi èyí sọ́kàn nígbà tí a bá ń béèrè àwọn èyí tó jẹ́ pé owó tabua ni Society fi ń pèsè wọn. Lára wọn ni fídíò, CD-ROM, àwọn ìwé atọ́ka ńlá, ìwé àdìpọ̀, àti àwọn kásẹ́ẹ̀tì. Dípò bíbéèrè ọ̀kọ̀ọ̀kan fún mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé, ǹjẹ́ gbogbo ìdílé kan lè ní ẹyọ kan ṣoṣo péré? Bí a bá jẹ́ kí ohun tí a ń gbà mọ níwọ̀n, yóò jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn náà lè gba àwọn nǹkan rere tí àwa náà ń gbádùn.—Fílí. 2:4.
6 A lè rí apá kan iye owó tí a ń ná lórí àwọn ìwé tí a ń fi sóde gbà nípa ọrẹ fún iṣẹ́ Society kárí ayé tí àwa fúnra wa bá fi ṣètìlẹ́yìn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti èyí tí àwọn olùfìfẹ́hàn tó bá gba àwọn ìwé náà bá fi ṣètìlẹ́yìn. Ṣùgbọ́n, nígbà tó bá dórí àwọn ìwé tí a béèrè tí àwa fúnra wa yóò máa lò, irú bí ìwé orin, ìwé Yearbook, Bíbélì olómi góòlù, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, a kò lè retí pé àwọn ará ìta ni yóò wá kúnjú àìní wa. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti ṣèyàsímímọ́ ni wọ́n ń fi owó ṣe ìtìlẹ́yìn lọ́nà yìí ní pàtàkì. Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, ọ̀pọ̀ akéde ló ń fojú díwọ̀n iye tí àwọn ìwé yẹn lè tó bó bá jẹ́ pé àwọn oníṣòwò ló ṣe é, wọ́n á sì wá fi owó ṣètìlẹ́yìn ní ìbámu pẹ̀lú ìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì olómi góòlù lè tó ₦900 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwé atọ́ka lè tó ₦1,300 tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ, kàlẹ́ńdà aláwọ̀ mèremère tí a ń gbé kọ́ sí ara ògiri lè tó ₦50 ó kéré tán, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tó bá wà lórí CD-ROM lè náni tó ₦1,000 sí ₦2,300 tàbí kó tilẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn àwo orin compact disc máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ₦300, àwọn fídíò kan sì wà tó sábà máa ń gbówó lórí jù bẹ́ẹ̀. Bí a bá kùnà láti ṣe ìdáwó tí ó tó láti kájú iye tí a fi ń ṣe wọ́n, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ìyẹn kò ní jẹ́ kí ètò àjọ náà lè ṣe ohun tí ì bá ṣe láti mú kí iṣẹ́ kárí ayé náà máa tẹ̀ síwájú.
7 Jésù polongo pé, wọ́n á dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun mọ̀ ní kedere nípasẹ̀ ìfẹ́ tí wọ́n á ní sí ara wọn. (Jòh. 13:34, 35) Ó dájú pé ìwà ọ̀làwọ́ wa nínú fífi ohun ìní wa ṣètìlẹ́yìn, àti ṣíṣàìjẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan nínú ṣíṣàjọpín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe nílò rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tó dára láti fi hàn pé ojúlówó Kristẹni la jẹ́.