Fiyè sí Bí O Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀
Fífetísílẹ̀ dáadáa ṣe kókó nígbà tí a bá lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ, àti àwọn àpéjọpọ̀. (Lúùkù 8:18) Báwo lo ṣe lè túbọ̀ máa fetí sílẹ̀ dáadáa?
◼ Má ṣe máa jẹ àwọn oúnjẹ tí ń mára wúwo ṣáájú ìpàdé.
◼ Má ṣe jẹ́ kí èrò inú rẹ máa ro tìhín ro tọ̀hún.
◼ Ṣàkọsílẹ̀ ṣókí nípa àwọn kókó pàtàkì.
◼ Ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a bá kà.
◼ Kópa nínú ìpàdé nígbà tí àǹfààní rẹ̀ bá wà.
◼ Ronú nípa àkójọ ọ̀rọ̀ tí a ń jíròrò.
◼ Ronú nípa bí o ṣe lè fi ohun tí o ń gbọ́ sílò.
◼ Lẹ́yìn náà, jíròrò ohun tí o kọ́.
Wo Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun, ìkẹ́kọ̀ọ́ 5.