Ìtara Tó Máa Ń Ru Ọ̀pọ̀ Jù Lọ Sókè
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún àwọn ará Kọ́ríńtì nítorí pé ìtara wọn fún iṣẹ́ rere ti “ru ọ̀pọ̀ jù lọ” nínú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn sókè. (2 Kọ́r. 9:2) Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìdílé, àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, tàbí odindi ìjọ lè ní ipa kan náà yìí ní ti bí wọ́n ṣe ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere. Àwọn ọ̀nà kan rèé tí o lè gbà fi ìtara hàn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.
◼ Ya ọjọ́ Sátidé sọ́tọ̀ fún ìgbòkègbodò Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn.
◼ Kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́jọ́ Sunday.
◼ Kópa nínú àwọn ọjọ́ ìjẹ́rìí àkànṣe èyíkéyìí tí a bá ṣètò.
◼ Lo ìsinmi tí o bá gbà lẹ́nu iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́ láti lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn.
◼ Kọ́wọ́ ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká.
◼ Ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dún.
◼ Yí ipò rẹ padà láti ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé bó bá ṣeé ṣe.
Wo ìwé 2000 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 17 sí 19.