ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/00 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Tí Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Ń Kojú Kò Níye
    Jí!—2002
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Àbójútó Ọmọ—Ìsìn Àti Òfin
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 5/00 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Báwo làwọn olùṣàbójútó èrò ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti mú kí àwọn ọmọ wọn fara balẹ̀ ní ìpàdé?

Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọmọdé, okun ń bẹ lára wọn, kò sì mọ́ wọn lára pé kí wọ́n jókòó fún àkókò pípẹ́. Lẹ́yìn ìpàdé, agbára máa ń gun àwọn ọmọdé, èyí sì lè mú kí wọ́n fẹ́ láti máa sáré kiri kí wọ́n sì máa lé àwọn ọmọdé míì káàkiri inú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ní àwọn ibòmíràn táa ti ń ṣèpàdé, ní àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, tàbí ní ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n, òótọ́ lòwe náà tó sọ pé: ‘Ọmọ tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fàlàlà yóò máa kó ìtìjú bá òbí rẹ̀.’—Òwe 29:15.

Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ará kan tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ti ṣèṣe gidigidi nítorí pé àwọn ọmọdé kọlù wọ́n, wọ́n sì gbé wọn ṣubú. Èyí ti fa ìrora tí kò yẹ, ó sì ti kó àwọn òbí àti ìjọ sí ìnáwó tí kò yẹ kó wáyé. Nítorí ààbò àwọn ọmọ àti ti àwọn ẹlòmíràn, a kò gbọ́dọ̀ gbà wọ́n láyè láti máa sáré nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí lóde rẹ̀, bẹ́ẹ̀ la ò sì gbọ́dọ̀ gbà wọ́n láyè láti máa ṣeré níbẹ̀.

Àwọn òbí ni Ìwé Mímọ́ fún lẹ́rù iṣẹ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n ní ọ̀wọ̀ tó yẹ fún àwọn ibi ìjọsìn wa. (Oníw. 5:1a) Ní àwọn ìpàdé tí àwa Kristẹni máa ń ṣe nínú ìjọ, ní àwọn ìpàdé àkànṣe, ti àyíká, àti ìpàdé àgbègbè, a yan àwọn olùṣàbójútó èrò láti máa rí i pé “ohun gbogbo . . . ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu,” àti pé àwọn nǹkan ‘wà létòletò.’ (1 Kọ́r. 14:40; Kól. 2:5) Wọ́n gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́, àti lẹ́yìn tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá parí, wọ́n á máa kíyè sóhun tó ń lọ nínú gbọ̀ngàn àti lóde rẹ̀. Bí ọmọ kan bá ń sáré kiri tàbí tó ń ṣèpátá, olùṣàbójútó èrò lè rọra dá ọmọ náà dúró, kí ó sì ṣàlàyé ìdí tí a kò fi fẹ́ kí ọmọ náà dá irú àṣà bẹ́ẹ̀. Kí ó tún fi pẹ̀lẹ́tù sọ fún àwọn òbí ọmọ náà nípa ohun tí ọmọ wọ́n ṣe àti pé kí wọ́n bójú tó ọmọ wọn. Kí irú òbí bẹ́ẹ̀ ṣe ohun tó bá yẹ o.

A mọ̀ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọ ọwọ́ àti ọmọ kéékèèké lè máa sunkún tàbí kí wọ́n máa ṣèdíwọ́ lákòókò ìpàdé. Àwọn olùṣàbójútó èrò, tí wọ́n ti dé ní nǹkan bí ogún ìṣẹ́jú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀, lè fi àwọn ìlà méjì tó wà lẹ́yìn nínú gbọ̀ngàn sílẹ̀ fún àwọn òbí tó bá fẹ́ jókòó síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kéékèèké. Kí àwa tó kù fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípa fífi ìjókòó wọ̀nyẹn sílẹ̀ fún wọn.

Bí ọmọ kan bá ń ṣèdíwọ́, kí àwọn òbí rẹ̀ ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Bí àwọn òbí rẹ̀ kò bá ṣe nǹkan, tí ohun tọ́mọ náà ń ṣe sì bẹ̀rẹ̀ sí da ìpàdé rú, kí olùṣàbójútó èrò kan fi pẹ̀lẹ́tù sọ pé kí àwọn òbí ọmọ náà gbé e jáde kúrò nínú gbọ̀ngàn. Nígbà tí a bá ké sí àwọn ẹni tuntun wá sí ìpàdé, tí wọ́n sì ní àwọn ọmọ kéékèèké, kí a jókòó tì wọ́n, ká sì yọ̀ǹda láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ọmọ wọn bí wọ́n bá ń sunkún tàbí bí wọ́n bá ń ṣèdíwọ́ ní àwọn ọ̀nà mìíràn.

Inú wa máa ń dùn láti rí onírúurú àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọ́n yàtọ̀ síra nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí a sì rí ìwà rere tí wọ́n ń hù nínú agbo ilé Ọlọ́run. (1 Tím. 3:15) Nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀wọ̀ fún ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn, wọ́n ń bọlá fún un, gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ sì mọrírì wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́