Máa Ṣe É Tayọ̀tayọ̀
1 Jésù sọ pé nígbà wíwàníhìn-ín òun, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn kò ní “fiyè sí i,” gan-an bó ṣe rí nígbà ayé Nóà. (Mát. 24:37-39) Nígbà náà, a retí pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní fetí sí ìhìn rere Ìjọba náà. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa láyọ̀ bí a ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?—Sm. 100:2.
2 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni iṣẹ́ tí a ń jẹ́ àti iṣẹ́ tí a gbé lé wa lọ́wọ́ láti wàásù ti wá. Bí àwọn èèyàn bá dágunlá sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, lẹ́yìn tí a ti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, a jẹ́ pé Jèhófà gan-an ni wọ́n kọ̀. Rírántí pé tayọ̀tayọ̀ ló fi ń tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìwàásù táa ń ṣe láìdáwọ́ dúró yóò máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìdùnnú àti ayọ̀ àtinúwá gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí.—Ják. 1:25.
3 Èkejì, àwọn kan ṣì wà tí yóò tẹ́wọ́ gba ọ̀nà ìgbàlà Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lè dágunlá, àwọn ẹni bí àgùntàn wà tí a ṣì gbọ́dọ̀ kó jọ, àní nísinsìnyí pàápàá, tí àkókò òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. A gbọ́dọ̀ máa wàásù nìṣó, kí a máa lọ sí “ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí” láti “wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.”—Mát. 10:11-13.
4 Ní Ẹ̀mí Pé Nǹkan Á Dára: Ìròyìn tó ń bani nínú jẹ́ nípa ìsìn èké ti já àwọn kan kulẹ̀. Àwọn míì wà tí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti “bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká.” (Mát. 9:36) Inú àwọn ẹlòmíràn lè bà jẹ́ nítorí pé wọn ò níṣẹ́ lọ́wọ́, tàbí pé wọn ò rí ìtọ́jú gbà fún àìlera wọn, tàbí pé ààbò kò sí fún wọn. Báa bá lóye èyí, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ wa nìṣó. Sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó sọ nípa àwọn ọ̀ràn tí àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa ń ṣàníyàn nípa wọn jù lọ. Ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ni ojútùú kan ṣoṣo tó wà. Lo Ìwé Mímọ́ àti àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa láti mú kí ìhìn rere wọ inú ọkàn-àyà wọn.—Héb. 4:12.
5 Àwọn tó ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí máa ń rántí nígbà gbogbo pé: “Ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára” wa. (Neh. 8:10) Kò sídìí tó fi yẹ ká pàdánù ìdùnnú wa. “Bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ yín padà sọ́dọ̀ yín.” (Mát. 10:13) Jèhófà ń sọ ìdùnnú àti okun wa dọ̀tun bí a ṣe ń fi sùúrù bá iṣẹ́ ìsìn mímọ́ rẹ̀ nìṣó, ó sì ń bù kún ìṣòtítọ́ wa.