ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/01 ojú ìwé 1
  • Máa Fògo fún Jèhófà Nípa Ṣíṣe Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fògo fún Jèhófà Nípa Ṣíṣe Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Tí Ń Yin Jehofa Lógo
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ǹjẹ́ O Ní Ìtara Fún “Iṣẹ́ Àtàtà”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ru Ẹnì Kìíní-Kejì Wa Sókè Ká Lè Jẹ́ Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Ọwọ Rẹ Dí Ninu Awọn Òkú Iṣẹ́ Tabi Ninu Iṣẹ-isin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 2/01 ojú ìwé 1

Máa Fògo fún Jèhófà Nípa Ṣíṣe Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà

1 Ká ní o rí ilé forí pa mọ́ sí nígbà tí ìjì ń jà burúkú-burúkú, ara á mà tù ọ́ pẹ̀sẹ̀ o! Bí inú ilé ọ̀hún bá lọ́ wọ́ọ́rọ́, tí kò sì séwu níbẹ̀, tí àwọn tó ń gbé níbẹ̀ bá sì láájò àlejò, inú ẹ á dùn láti dúró níbẹ̀. Irú ilé kan bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà máa ń darí àwọn èèyàn tí wọ́n ń jáde kúrò nínú ètò Sátánì sí. Ǹjẹ́ báa ṣe ń hùwà lójoojúmọ́ lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ibi ààbò táa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí fani mọ́ra gidigidi? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí Jésù sọ pé àwọn èèyàn á rí ‘àwọn iṣẹ́ àtàtà wa, wọ́n á sì fògo fún Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.’—Mát. 5:16.

2 Báwo la ṣe lè máa hùwà kí àwọn iṣẹ́ wa lè máa fa àwọn ẹlòmíràn wá sọ́dọ̀ Jèhófà àti sínú ètò àjọ rẹ̀? Nípa jíjẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó wà lákọsílẹ̀ ní Lúùkù 6:31 àti 10:27 máa darí ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́ ni. Èyí yóò mú kí a máa ṣàníyàn tìfẹ́tìfẹ́ nípa àwọn èèyàn bíi tiwa, ìyẹn yóò sì mú ká yàtọ̀ sí ayé aláìnífẹ̀ẹ́ àti aláìbìkítà yìí.

3 Arábìnrin kan tó ń rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ òkun bá ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan pàdé tí ara rẹ̀ kò yá débi pé kò tiẹ̀ lè tọ́jú ọmọ kékeré tó gbé dání. Arábìnrin náà yọ̀ǹda láti bójú tó ọmọ náà. Nígbà tí obìnrin náà béèrè bí òun ṣe lè fi ìmoore hàn fún ohun tí arábìnrin yìí ṣe, arábìnrin náà sọ pé: ‘Jọ̀wọ́, fetí sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbàkigbà tí wọ́n bá tún délé rẹ.’ Obìnrin náà ṣe bẹ́ẹ̀, òun àti ọkọ rẹ̀ sì ti di Ẹlẹ́rìí báyìí. Iṣẹ́ àtàtà ló mú kí bí wọ́n ṣe dáhùn sí ìhìn Ìjọba náà rí báyìí.

4 Ó Kan Gbogbo Ìgbésí Ayé Wa: Báa ṣe ń hùwà ládùúgbò wa, tàbí nígbà táa bá wà níbi iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́, àti nígbà eré ìtura máa ń mú kí àwọn ẹlòmíràn ní èrò kan nípa wa àti nípa ẹ̀sìn wa. Nítorí náà, ó yẹ ká bi ara wa léèrè pé: ‘Kí lèrò táwọn tó ń wo èmi àti ìdílé mi ní nípa mi àti nípa ìdílé mi? Ǹjẹ́ àwọn aládùúgbò ka ilé wa àti àyíká rẹ̀ sí èyí tó mọ́ táa sì ń tọ́jú dáadáa? Ǹjẹ́ àwọn táa jọ ń ṣiṣẹ́ àti àwọn táa jọ ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kà wá sí ẹni tó máa ń dé lákòókò tó sì ń ṣiṣẹ́ kára? Ǹjẹ́ àwọn ẹlòmíràn ń rí i pé ìrísí wa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó sì ń fi iyì hàn?’ Àwọn iṣẹ́ àtàtà táa ń ṣe lè mú kí ìjọsìn Jèhófà túbọ̀ fa àwọn ẹlòmíràn mọ́ra.

5 Pétérù kìlọ̀ pé wọ́n á fi àwọn Kristẹni ṣẹ̀sín. (1 Pét. 4:4) A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé kì í ṣe ìwà wa ló ń jẹ́ kí àwọn èèyàn máa sọ̀rọ̀ wa láìdáa. (1 Pét 2:12) Bí ìwà wa ojoojúmọ́ bá ń fògo fún Ọlọ́run táa ń jọ́sìn, nígbà náà, a ó dà bíi fìtílà táa gbé sókè, tó ń ṣamọ̀nà àwọn ẹlòmíràn lọ sí ibi ààbò tí Jèhófà pèsè.—Mát. 5:14-16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́