Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ru Ẹnì Kìíní-Kejì Wa Sókè Ká Lè Jẹ́ Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà
Hébérù 10:24 rọ̀ wá pé “kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” A lè fi àpẹẹrẹ àti ọ̀rọ̀ ẹnu wa tó fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ru àwọn ará wa sókè. Máa sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tó o ní fún àwọn ará nínú ìjọ. Jẹ́ kí wọ́n rí bí ayọ̀ rẹ ṣe pọ̀ tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́, má ṣe máa fi ohun tó o ṣe wé tiwọn tàbí kó o máa fi ara rẹ wé àwọn ẹlòmíì. (Gál. 6:4) Máa wá bí wàá ṣe fi àwọn ìrírí tó o ní ru àwọn ẹlòmíì sókè sí “ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà,” kì í ṣe pé kó o ru wọ́n sókè sí ẹ̀bi àti àwọn iṣẹ́ àtàtà. (Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 158, ìpínrọ̀ 4.) Tí a bá ń ru àwọn ẹlòmíì sókè sí ìfẹ́, a ó tún mú kí wọ́n máa ṣe àwọn iṣẹ́ àtàtà bíi ṣíṣe ohun rere fún àwọn míì nípa tara tàbí kí wọ́n máa wàásù.—2 Kọ́r. 1:24.