ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/01 ojú ìwé 6
  • Ṣe Rere Kí O sì Gba Ìyìn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣe Rere Kí O sì Gba Ìyìn!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Tọ́jú Ìwà Yín Kí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti 1995
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Fi Ìwà Rẹ Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 9/01 ojú ìwé 6

Ṣe Rere Kí O sì Gba Ìyìn!

1 “N kò tíì rí àwọn èèyàn mìíràn tó jẹ́ oníwàtútù bíi tiwọn rí.” “Níní irú àwọn èèyàn yìí ní sàkání ẹni máa ń gbádùn mọ́ni.” Ìwọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ rere táwọn tó ń wò wá sọ lẹ́yìn táa ṣe àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ọdún tó kọjá tán, tó ń tẹnu mọ́ orúkọ rere tí ètò àjọ wa ní. (Òwe 27:2; 1 Kọ́r. 4:9) Lékè gbogbo rẹ̀, irú ìyìn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti Jèhófà. (Mát. 5:16) Àǹfààní títayọ mìíràn láti yin Ọlọ́run tún ń bọ̀ fún wa báyìí ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti ọdún yìí.

2 Lọ́dọọdún, a máa ń rí àwọn ìránnilétí onínúure gbà nípa ìwà tó bójú mu ní àpéjọpọ̀. Nítorí kí ni? Ó jẹ́ nítorí pé a kò fẹ́ fara wé ayé yìí, nítorí ńṣe ni ẹ̀mí tó ń fi hàn, ìmúra rẹ̀, àti ìwà rẹ̀ túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i. A ò fẹ́ kí orúkọ rere táa ní bà jẹ́. (Éfé. 2:2; 4:17) Ẹ jẹ́ ká fi àwọn ibi tí a ti ní láti kíyè sára tí a sọ nísàlẹ̀ yìí sọ́kàn.

3 Ṣe Rere ní Ilé àti Òtẹ́ẹ̀lì Tí Ẹ Dé Sí: Àwọn èèyàn mọ̀ wá ní olóòótọ́. (Héb. 13:18) Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ se oúnjẹ nínú iyàrá bí wọn kò bá fàyè gbà á. Alábòójútó òtẹ́ẹ̀lì kan sọ pé òun dín owó ilé kù fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé òun mọ̀ pé wọ́n á tọ́jú ilé ọ̀hún dáadáa. Ó dájú pé a kò ní mú nǹkan tí kì í ṣe tiwa kúrò nínú ilé tàbí òtẹ́ẹ̀lì táa dé sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ká fi ìmọrírì hàn fún ohun tí wọ́n ṣe fún wa. Ká fara balẹ̀ kí a sì ní sùúrù nínú bí a ṣe ń bá àwọn tí a jọ dé síbì kan náà lò.

4 Orí àwọn tó ń wò wá máa ń wú nígbà tí wọ́n bá rí àwọn ọ̀dọ́ wa tí wọ́n ń hùwà lọ́nà ọ̀wọ̀ àti onígbọràn. (Éfé. 6:1, 2) Ẹ̀yin òbí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ máa bójú tó àwọn ọmọ yín nígbà gbogbo kí wọ́n má bàa di ìyọlẹ́nu fún àwọn ẹlòmíràn. Kí gbogbo wa yẹra fún títi ilẹ̀kùn gbàgà-gbàgà tàbí pípariwo gèè, pàápàá ní alẹ́.

5 Ṣe Rere ní Ibi Àpéjọpọ̀: A ti kíyè sí i pé àwọn kan tó lọ sí àpéjọpọ̀ kò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùṣàbójútó èrò, kódà wọ́n sọ̀rọ̀ sí wọn lọ́nà tí kò yẹ kí Kristẹni gbà sọ̀rọ̀. Nítorí pé àwọn kan kò tẹ̀ lé ìtọ́ni tí àwọn arákùnrin yìí fún wọn tí wọ́n sì lọ gbé ọkọ̀ síbi tí wọ́n sọ pé kí wọ́n máà gbé e sí, ó ti yọrí sí pé kí àwọn ọkọ̀ máà rí ibi gbà. Dájúdájú, ẹ̀mí tèmi làkọ́kọ́ kì í fini hàn lẹ́ni tí ń ṣe rere, bẹ́ẹ̀ ni kì í mú ìyìn wá fún Jèhófà Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ká ní sùúrù, ká sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀.—Gál. 5:22, 23, 25.

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti dámọ̀ràn pé a lè gbé oúnjẹ díẹ̀ wá láti jẹ ní ọ̀sán, kò yẹ láti jẹ oúnjẹ tó ń mára wúwo tó lè wá mú kí èèyàn máa tòògbé nígbà tí ìpàdé ọ̀sán bá ń lọ lọ́wọ́. Ìyẹn á fi hàn pé èèyàn ò mọrírì irú àkókò pàtàkì yẹn ni.

7 Ṣe Rere Nípa Ìwọṣọ àti Ìmúra: Nígbà tí àpéjọpọ̀ àgbègbè kan parí lọ́dún tó kọjá, olóòtú ìwé ìròyìn ìlú ńlá kan kọ̀wé pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn lọ, ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí ló fani mọ́ra jù. Ó mà tuni lára o, láti rí ọ̀pọ̀ èèyàn báyẹn tí wọ́n ń ṣe nǹkan tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lọ́nà iyì. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìdílé tí wọ́n wọṣọ tó dára gan-an, tí wọ́n jẹ́ [onírúurú] ẹ̀yà àti èdè ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ rọ́ lọ sí gbọ̀ngàn ọ̀hún. Ìwà wọn yàtọ̀ pátápátá sí ti ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ti máa ń rọ́ wá sí gbọ̀ngàn ọ̀hún. Ká sòótọ́, ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn tó ti máa ń wá síbẹ̀ kì í ṣe kékeré. Ó túbọ̀ ń wọ́pọ̀ pé àwọn èèyàn máa ń hùwà àìlọ́wọ̀ láwùjọ. . . . Ká sòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí gbayì.” Ǹjẹ́ ká má ṣe jẹ́ kí ìwọṣọ àti ìmúra wa tàbí ìwà wa tàbùkù ipò tẹ̀mí àpéjọpọ̀ wa lọ́nàkọnà.—Fílí. 1:10; 1 Tím. 2:9, 10.

8 Ṣe Rere Nígbà Ìrìbọmi: Ó yẹ kí àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi fi ọwọ́ iyì gidigidi mú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. Wíwọ aṣọ ìwẹ̀ tó bójú mú yóò fi hàn pé o mọrírì pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ọlọ́wọ̀. Yóò ṣàǹfààní gidigidi bí àwọn olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn ṣàyẹ̀wò “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1995, ṣáájú kí wọ́n tó lọ sí àpéjọpọ̀.

9 Ìwà ẹ̀yẹ wa àti olùṣèfẹ́ Ọlọ́run tí a jẹ́ ń jẹ́rìí sí àwọn ohun tí a gbà gbọ́ bí a ti jẹ́ Kristẹni, ó sì ń mú kó rọrùn fún àwọn olóòótọ́ ọkàn láti dá òtítọ́ mọ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká “máa ṣe rere” kí a sì gba ìyìn nígbà tí a bá lọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—Róòmù 13:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́