ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/01 ojú ìwé 4
  • Ǹjẹ́ O Lè Sìn Níbi Tí Àìní Gbé Pọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Lè Sìn Níbi Tí Àìní Gbé Pọ̀?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ábúráhámù—Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Baba Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Ní Ìgbàgbọ́”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ní Irú Ìgbàgbọ́ Tí Ábúráhámù Ní!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Yí Orúkọ Ábúrámù àti Sáráì Pa Dà?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 7/01 ojú ìwé 4

Ǹjẹ́ O Lè Sìn Níbi Tí Àìní Gbé Pọ̀?

1 Ǹjẹ́ o tíì ronú rí nípa ṣíṣí lọ sí ibi tí wọ́n ti nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba púpọ̀ sí i? Bí a bá ké sí ọ láti ‘ré kọjá wá kí o sì ṣèrànwọ́,’ ṣé wàá dáhùn bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣe? (Ìṣe 16:9, 10) Ní ọ̀pọ̀ ìjọ, wọ́n nílò àwọn ìdílé tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, àwọn aṣáájú ọ̀nà láti ṣèrànwọ́ láti kárí ìpínlẹ̀ wọn tàbí àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun láti mú ipò iwájú. Ó ṣeé ṣe kí ìpínlẹ̀ náà jẹ́ àwọn ìlú kéékèèké tó wà ní àdádó káàkiri ìgbèríko ńlá kan. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ ibẹ̀ jù lọ jìnnà gan-an. Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lè má fi bẹ́ẹ̀ sí. Ojú ọjọ́ lè má fìgbà gbogbo bara dé. Ṣé o ṣe tán láti tẹ́wọ́ gba irú ìpèníjà yẹn? Báwo lo ṣe lè ṣàṣeyọrí níbẹ̀?

2 Ó Béèrè Ìgbàgbọ́ àti Ìgbẹ́kẹ̀lé: Ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ tí Ọlọ́run fún un, Ábúrámù kúrò ní Úrì ìlú rẹ̀, òun àti aya rẹ̀ àti ọmọkùnrin arákùnrin rẹ̀ àti Térà tó jẹ́ bàbá rẹ̀ arúgbó, wọ́n sì rìnrìn àjò ẹgbẹ̀rún kìlómítà lọ sí Háránì. (Jẹ́n. 11:31, 32; Neh. 9:7) Lẹ́yìn tí Térà kú, Jèhófà pàṣẹ fún Ábúrámù tó ti di ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin pé kó kúrò ní Háránì, òun àtàwọn ẹbí rẹ̀ kí ó sì rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí Ọlọ́run yóò fi hàn án. Ni Ábúrámù, Sáráì, àti Lọ́ọ̀tì bá “mú ọ̀nà wọn pọ̀n.” (Jẹ́n. 12:1, 4, 5) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe nítorí àtisìn níbi tí wọn ti nílò àwọn òjíṣẹ́ púpọ̀ sí i ni Ábúrámù ṣe ṣí lọ. Ṣùgbọ́n ṣíṣílọ rẹ̀ béèrè àwọn nǹkan kan. Kí ni àwọn nǹkan yẹn?

3 Ó gba ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé kí Ábúrámù tó lè dáwọ́ lé irú nǹkan yẹn. Ìrònú rẹ̀ àti ọ̀nà tó ń gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ ní láti yí padà. Ó ní láti yááfì àjọṣe òun àtàwọn ẹbí rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò bójú tó òun àti agboolé òun. Lónìí, ọ̀pọ̀ ti fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú Jèhófà hàn lọ́nà tó jọ èyí.

4 Iṣẹ́ Àyànfúnni Onígbà Kúkúrú: Ǹjẹ́ o tíì fìgbà kan rí gbádùn ìbùkún jìngbìnnì tó ń wá látinú ṣíṣe ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni? Lọ́dún tó kọjá, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún, ọgọ́rùn-ún méje, ó dín ẹyọ kan [5,699] àwọn akéde ṣiṣẹ́ kárí ẹ̀tàlélọ́gọ́jọ [163] lára ẹ̀rìnléláàádọ́sàn-án [174] àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni. Àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún, ọgọ́rùn-ún méje, ó dín mẹ́rìnlélógún [5,676] akéde mìíràn ṣèrànwọ́ fún okòó-dín-nírínwó [380] ìjọ láti kárí àwọn ìpínlẹ̀ tí wọn kì í sábàá ṣe. Èyí béèrè pé kí àwọn kan rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn réré. Ṣé gbogbo ìsapá yìí yẹ bẹ́ẹ̀?

5 Arákùnrin kan tó ṣí lọ síbòmíràn lọ́nà yẹn kọ̀wé pé: “Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ sọ fún mi pé bóyá màá lè mú àwùjọ kan lọ sí ìpínlẹ̀ tí a kì í sábàá ṣe, mo lọ́ tìkọ̀. Ṣùgbọ́n mo pinnu láti gba iṣẹ́ àyànfúnni náà. Kì í ṣe pé n kò kábàámọ̀ rárá nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún yí ìgbésí ayé mi padà. Ojoojúmọ́ ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo láǹfààní láti wà lára àwọn tó rìnrìn àjò yìí.” Arákùnrin mìíràn sọ pé ìrírí mánigbàgbé jù lọ tí òun tíì ní nìyẹn láti ogún ọdún tóun ti wà nínú òtítọ́! Ọ̀dọ́langba kan tó lọ síbi tí wọ́n ti nílò ìrànwọ́ sọ pé: “Ìrírí tó tíì dára jù lọ ní ìgbésí ayé mi nìyí!” Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn akéde gbà pé kódà sísìn fún àkókò kúkúrú níbi tí àìní gbé pọ̀ ti mú kí ìmọrírì tí wọ́n ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ jinlẹ̀ sí i. Bá àwọn to ti ṣe é sọ̀rọ̀. Wàá rí i pé wọ́n túbọ̀ sunwọ̀n sí i nípa tẹ̀mí, bí a bá sì tún fún wọn láǹfààní yẹn, àfàìmọ̀ ni wọn kò ní tẹ́wọ́ gbà á.

6 Títẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àyànfúnni onígbà díẹ̀ láti sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ lè wúlò lọ́nà mìíràn. Àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ lè rí ìsọfúnni tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti “gbéṣirò lé ìnáwó” ṣíṣílọ sí apá ibòmíràn lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé.—Lúùkù 14:28.

7 Jèhófà ti pinnu láti rí i pé a polongo ìhìn rere náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” kí òpin tó dé. (Mát. 24:14) Bí o ti wá mọ èyí, ǹjẹ́ o múra tán láti ṣí lọ sí ibi tí àìní gbé pọ̀ bí o bá lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀pọ̀ ibi ni àìní gbé pọ̀.

8 Ṣíṣílọ sí Ibi Tí Àìní Gbé Pọ̀: Ṣé o ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ni? Ṣé owó ń wọlé fún ọ déédéé? Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé o lè wá iṣẹ́ ti ara rẹ ṣe? Ṣé ó ṣeé ṣe fún ọ láti gbọ́ bùkátà ara rẹ lápá ibi yòówù kí o wà lórílẹ̀-èdè yìí? Bí o kò bá lè ṣí lọ síbòmíràn, ṣé o lè ṣètìlẹ́yìn fún ẹlòmíràn nínú ìdílé rẹ láti lọ sìn níbòmíràn?

9 Bó bá jẹ́ pé lẹ́yìn tóo ronú tàdúràtàdúrà, o rí i pé apá rẹ yóò ká ìpèníjà ṣíṣílọ sí ibi tí àìní gbé pọ̀, bá ìdílé rẹ àti àwọn alàgbà inú ìjọ rẹ jíròrò nípa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, kọ lẹ́tà kan kí o sì fún àwọn alàgbà kí wọ́n lè kọ àkíyèsí àti àbá tiwọn pẹ̀lú rẹ̀ kí wọ́n tó fi ránṣẹ́ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka.

10 Kí ló yẹ kí o kọ sínú lẹ́tà rẹ? Kọ ọjọ́ orí rẹ, ọjọ́ tóo ṣèrìbọmi, ẹrù iṣẹ́ rẹ nínú ìjọ, bóyá o ti ṣègbéyàwó tàbí o kò tíì ṣe, àti bóyá o ní àwọn ọmọ tí kò tíì tójúúbọ́. Kọ orúkọ àwọn ìpínlẹ̀ tàbí ibi tí o ti fẹ́ láti lọ sìn ní ìbámu pẹ̀lú ipò rẹ.

11 Ǹjẹ́ o ní ìtara, tí o sì máa ń lo ìdánúṣe? Ǹjẹ́ ipò rẹ gbà ọ́ láyè láti sìn níbi tí àìní gbé pọ̀? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ máa kíyè si bí Jèhófà yóò ṣe máa rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e bí wọ́n ṣe ń fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn!—Sm. 34:8; Mál. 3:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́