ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 15-17
Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Yí Orúkọ Ábúrámù àti Sáráì Pa Dà?
Jèhófà ka Ábúrámù sí aláìlẹ́bi. Ó sì fún Ábúrámù àti Sáráì ní orúkọ tó máa jẹ́ kí ìlérí tó ṣe fún wọn túbọ̀ dá wọn lójú.
Orúkọ náà sì rò wọ́n lóòótọ́, torí pé Ábúráhámù di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, Sérà sì di ìyá àwọn ọba.
Ábúráhámù
Bàbá Ọ̀pọ̀ Èèyàn
Sérà
Ìyá Àwọn Ọba
A ò lè yan orúkọ tí wọ́n máa sọ wá nígbà tí wọ́n bí wa. Ṣùgbọ́n bíi ti Ábúráhámù àti Sérà, a lè ṣe orúkọ rere fún ara wa. Bi ara rẹ pé:
‘Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ aláìlẹ́bi lójú Jèhófà?’
‘Irú orúkọ wo ni mò ń ṣe fún ara mi lọ́dọ̀ Jèhófà?’